ORIN DAFIDI 139

139
Ọlọrun Olùmọ̀ràn Ọkàn
1OLUWA, o ti yẹ̀ mí wò, o sì mọ̀ mí.
2O mọ ìgbà tí mo jókòó, ati ìgbà tí mo dìde;
o mọ èrò ọkàn mi láti òkèèrè réré.
3O yẹ ìrìn ẹsẹ̀ mi ati àbọ̀sinmi mi wò;
gbogbo ọ̀nà mi ni o sì mọ̀.
4Kódà kí n tó sọ ọ̀rọ̀ jáde lẹ́nu,
OLUWA, o ti mọ gbogbo nǹkan tí mo fẹ́ sọ patapata.
5O pa mí mọ́, níwájú ati lẹ́yìn;
o gbé ọwọ́ ààbò rẹ lé mi.
6Irú ìmọ̀ yìí jẹ́ ohun ìyanu fún mi,
ó ga jù, ojú mi kò tó o.
7Níbo ni mo lè sá lọ, tí ẹ̀mí rẹ kò ní sí níbẹ̀?
Níbo ni mo lè sá gbà tí ojú rẹ kò ní tó mi?
8Ǹ báà gòkè re ọ̀run, o wà níbẹ̀!
Bí mo sì tẹ́ ibùsùn mi sí isà òkú, n óo bá ọ níbẹ̀.
9Ǹ báà hu ìyẹ́, kí n fò lọ sí ibi ojúmọ́ ti ń mọ́ wá,
kí n lọ pàgọ́ sí ibi tí òkun pin sí,
10níbẹ̀ gan-an, ọwọ́ rẹ ni yóo máa tọ́ mi,
tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóo sì dì mí mú.
11Bí mo bá wí pé kí kìkì òkùnkùn bò mí mọ́lẹ̀,
kí ọ̀sán di òru fún mi,
12òkùnkùn gan-an kò ṣú jù fún ọ;
òru mọ́lẹ̀ bí ọ̀sán;
lójú rẹ, ìmọ́lẹ̀ kò yàtọ̀ sí òkùnkùn.
13Nítorí ìwọ ni o dá inú mi,
ìwọ ni o sọ mí di odidi ní inú ìyá mi.
14Mo yìn ọ́, nítorí pé ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ ati ẹni ìyanu ni ọ́;
ìyanu ni iṣẹ́ ọwọ́ rẹ!
O mọ̀ mí dájú.
15Nígbà tí à ń ṣẹ̀dá egungun mi lọ́wọ́ ní ìkọ̀kọ̀,
tí ẹlẹ́dàá ṣẹ̀ṣẹ̀ ń ṣọnà sí mi lára ní àṣírí,
kò sí èyí tí ó pamọ́ fún ọ.
16Kí á tó dá mi tán ni o ti rí mi,
o ti kọ iye ọjọ́ tí a pín fún mi
sinu ìwé rẹ,
kí ọjọ́ ayé mi tilẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ rárá.
17Ọlọrun, iyebíye ni èrò rẹ lójú mi!
Wọ́n pọ̀ pupọ ní iye.
18Bí mo bá ní kí n kà wọ́n,
wọ́n pọ̀ ju iyanrìn lọ;
nígbà tí mo bá sì jí,
ọ̀dọ̀ rẹ náà ni n óo wà.#Sir 18:5-7
19Ọlọrun, ò bá jẹ́ pa àwọn eniyan burúkú,
kí àwọn apànìyàn sì kúrò lọ́dọ̀ mi.
20Wọ́n ń sọ ọ̀rọ̀ ọ̀tẹ̀ nípa rẹ,
àwọn ọ̀tá rẹ ń ba orúkọ rẹ jẹ́.
21OLUWA, mo kórìíra àwọn tí ó kórìíra rẹ;
mo sì kẹ́gàn àwọn tí ń dìtẹ̀ sí ọ?
22Mo kórìíra wọn dé òpin;
ọ̀tá ni mo kà wọ́n kún.
23Wádìí mi, Ọlọrun, kí o mọ ọkàn mi;
yẹ̀ mí wò, kí o sì mọ èrò ọkàn mi.
24Wò ó bí ọ̀nà ibi kan bá wà tí mò ń tọ̀,
kí o sì tọ́ mi sí ọ̀nà ayérayé.#139:24b tabi “ọ̀nà àwọn aṣaaju mi,” tabi “ọ̀nà títọ́.”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 139: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀