ORIN DAFIDI 140

140
Adura Ààbò
1OLUWA, gbà mí lọ́wọ́ àwọn ẹni ibi;
dáàbò bò mí lọ́wọ́ àwọn oníwà ipá;
2àwọn tí ó ń pète ibi lọ́kàn wọn,
tí wọ́n sì ń dá ogun sílẹ̀ nígbàkúùgbà,
3Wọ́n pọ́n ahọ́n wọn, ó mú bí ahọ́n ejò;
oró paramọ́lẹ̀ sì ń bẹ ninu eyín wọn.#Rom 3:13
4OLUWA, ṣọ́ mi lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú;
dáàbò bò mí lọ́wọ́ àwọn oníwà ipá,
tí ó ń gbìmọ̀ láti ré mi lẹ́pa.
5Àwọn agbéraga ti dẹ tàkúté sílẹ̀ dè mí,
wọ́n dẹ àwọ̀n sílẹ̀ fún mi;
wọ́n sì dẹ okùn sílẹ̀ fún mi lẹ́bàá ọ̀nà.
6Mo wí fún OLUWA pé, “Ìwọ ni Ọlọrun mi.”
OLUWA, tẹ́tí sí ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.
7OLUWA, OLUWA mi, alágbára tíí gbani là,
ìwọ ni o dáàbò bò mí ní ọjọ́ ogun.
8OLUWA, má jẹ́ kí ọwọ́ àwọn eniyan burúkú tẹ ohun tí wọn ń wá;
má jẹ́ kí èrò ọkàn wọn ṣẹ.
9Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ibi ẹnu àwọn tí ó yí mi ká
dà lé wọn lórí.
10Jẹ́ kí ẹ̀yinná dà lé wọn lórí;
jẹ́ kí wọn já sí kòtò, kí wọn má lè yọ.
11Má jẹ́ kí abanijẹ́ fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ lórí ilẹ̀ náà;
jẹ́ kí oníwà ipá ko àgbákò kíákíá.
12Mo mọ̀ pé OLUWA yóo gba ọ̀ràn olùpọ́njú rò,
yóo sì ṣe ìdájọ́ òdodo fún àwọn aláìní.
13Dájúdájú, àwọn olódodo yóo máa fi ọpẹ́ fún ọ;
àwọn olóòótọ́ yóo sì máa gbé níwájú rẹ.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 140: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀