ORIN DAFIDI 48

48
OLUWA Tóbi
1OLUWA tóbi, ó sì yẹ kí á máa yìn ín lọpọlọpọ
ní ìlú Ọlọrun wa.
2Òkè mímọ́ rẹ̀, tí ó ga, tí ó sì lẹ́wà,
ni ayọ̀ gbogbo ayé.
Òkè Sioni, ní àríwá, lọ́nà jíjìn réré,
ìlú ọba ńlá.
3Ninu ilé ìṣọ́ ìlú náà, Ọlọrun ti fi ara rẹ̀ hàn bí ibi ìsádi.#Mat 5:35
4Wò ó! Àwọn ọba kó ara wọn jọ;
wọ́n jùmọ̀ gbógun tì í.
5Nígbà tí wọ́n fojú kàn án, ẹnu yà wọ́n,
ìpayà mú wọn, wọ́n sì sá;
6ìwárìrì mú wọn níbẹ̀;
ìrora sì bá wọn bí obinrin tí ń rọbí.
7Ó fọ́ wọn bí afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn tií fọ́ ọkọ̀ Taṣiṣi.
8Bí a ti gbọ́, bẹ́ẹ̀ gan-an ni ó rí,
ní ìlú OLUWA àwọn ọmọ ogun,
ní ìlú Ọlọrun wa:
Ọlọrun fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ títí lae.
9Ninu tẹmpili rẹ, Ọlọrun,
à ń ṣe àṣàrò lórí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀.
10Ọlọrun, ìyìn rẹ tàn ká,
bí orúkọ rẹ ṣe tàn dé òpin ayé,
iṣẹ́ rere kún ọwọ́ rẹ.
11Jẹ́ kí inú òkè Sioni kí ó dùn,
kí gbogbo Juda sì máa yọ̀
nítorí ìdájọ́ rẹ.
12Ẹ rìn yí Sioni po; ẹ yí i ká;
ẹ ka àwọn ilé ìṣọ́ rẹ̀;
13ẹ ṣàkíyèsí odi rẹ̀;
ẹ wọ inú gbogbo ilé ìṣọ́ rẹ̀ lọ,
kí ẹ lè ròyìn fún ìran tí ń bọ̀
14pe: “Ọlọrun yìí ni Ọlọrun wa,
lae ati laelae.
Òun ni yóo máa ṣe amọ̀nà wa títí lae.”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 48: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀