ORIN DAFIDI 49

49
Ìwà Òmùgọ̀ ni Igbẹkẹle Ọrọ̀
1Ẹ gbọ́, gbogbo orílẹ̀-èdè!
Ẹ dẹtí sílẹ̀, gbogbo aráyé,
2ati mẹ̀kúnnù àtọlọ́lá,
àtolówó ati talaka!
3Ẹnu mi yóo sọ̀rọ̀ ọgbọ́n;
àṣàrò ọkàn mi yóo sì jẹ́ ti òye.
4N óo tẹ́tí sílẹ̀ sí òwe;
n óo sì fi hapu túmọ̀ rẹ̀.
5Kí ló dé tí n óo fi bẹ̀rù ní àkókò ìyọnu,
nígbà tí iṣẹ́ ibi àwọn tí ń ṣe inúnibíni mi bá yí mi ká,
6àwọn tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ wọn,
tí wọ́n sì ń yangàn nítorí wọ́n ní ọrọ̀ pupọ?
7Dájúdájú, kò sí ẹni tí ó le ra ara rẹ̀ pada,
tabi tí ó lè san owó ìràpadà ẹ̀mí rẹ̀ fún Ọlọrun;
8nítorí pé ẹ̀mí eniyan níye lórí pupọ.
Kò sí iye tí eniyan ní tí ó le kájú rẹ̀,
9tí eniyan lè máa fi wà láàyè títí lae,
kí ó má fojú ba ikú.
10Yóo rí i pé ikú a máa pa ọlọ́gbọ́n,
òmùgọ̀ ati òpè a sì máa rọ̀run;
wọn a sì fi ọrọ̀ wọn sílẹ̀ fún ẹlòmíràn.
11Ibojì wọn ni ilé wọn títí lae,
ibẹ̀ ni ibùgbé wọn títí ayérayé,
wọn ìbáà tilẹ̀ ní ilẹ̀ ti ara wọn.
12Eniyan kò lè máa gbé ninu ọlá rẹ̀ títí ayé,
bí ẹranko tíí kú, ni òun náà óo kú.#Sir 11:19
13Ìpín àwọn tí ó ní igbẹkẹle asán nìyí,
òun sì ni èrè àwọn tí ọrọ̀ wọn tẹ́ lọ́rùn.
14Ikú ni ìpín wọn bí àgùntàn lásánlàsàn,
ikú ni yóo máa ṣe olùṣọ́ wọn;
ibojì ni wọ́n sì ń lọ tààrà.
Wọn yóo jẹrà, ìrísí wọn óo sì parẹ́,
Àwọn olódodo yóo jọba lórí wọn ní òwúrọ̀,
ibojì ni yóo sì máa jẹ́ ilé wọn.
15Ṣugbọn Ọlọrun yóo ra ẹ̀mí mi pada lọ́wọ́ ikú
nítorí pé yóo gbà mí.
16Má ba ara jẹ́ bí ẹnìkan bá di olówó,
tí ọrọ̀ rẹ̀ ń pọ̀ sí i.
17Nítorí pé ní ọjọ́ tí ó bá kú,
kò ní mú ohunkohun lọ́wọ́ lọ;
dúkìá rẹ̀ kò sì ní bá a wọ ibojì.
18Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé nígbà tí ó wà láàyè,
ó rò pé Ọlọrun bukun òun,
bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ayé a máa yin eniyan
nígbà tí nǹkan bá ń dára fún un,
19yóo kú bí àwọn baba ńlá rẹ̀ ti kú,
kò sì ní fojú kan ìmọ́lẹ̀ mọ́.
20Eniyan kò lè máa gbé inú ọlá rẹ̀ títí ayé;
bí ẹranko tíí kú, ni òun náà óo ku.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 49: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀