ORIN DAFIDI 82

82
Ọlọrun, Ọba Àwọn Ọba
1Ọlọrun ti jókòó ní ààyè rẹ̀ ninu ìgbìmọ̀ ọ̀run;
ó sì ń ṣe ìdájọ́ láàrin àwọn ẹ̀dá ọ̀run:
2“Yóo ti pẹ́ tó tí ẹ̀yin óo máa fi aiṣododo ṣe ìdájọ́,
tí ẹ óo sì máa ṣe ojuṣaaju fún àwọn eniyan burúkú?
3Ẹ ṣe ìdájọ́ òdodo fún àwọn mẹ̀kúnnù ati àwọn ọmọ aláìníbaba;
ẹ sì máa ṣe ẹ̀tọ́ fún àwọn tí ojú ń pọ́n ati àwọn talaka.
4Ẹ gba talaka ati aláìní sílẹ̀,
ẹ gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú.”
5Wọn kò ní ìmọ̀ tabi òye,
wọ́n ń rìn kiri ninu òkùnkùn,
títí gbogbo ìpìlẹ̀ ayé fi mì tìtì.
6Mo ní, “oriṣa ni yín,
gbogbo yín ni ọmọ Ọ̀gá Ògo.
7Ṣugbọn sibẹsibẹ, ẹ óo kú bí eniyan,
ẹ ó sùn bí èyíkéyìí ninu àwọn ìjòyè.”
8Dìde, Ọlọrun, ṣe ìdájọ́ ayé,
nítorí tìrẹ ni gbogbo orílẹ̀-èdè!#Joh 10:34

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 82: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀