ORIN DAFIDI 90

90
Ibi tí Agbára Ẹ̀dá Mọ
1OLUWA, ìwọ ni o ti jẹ́ ibi ààbò wa láti ìrandíran.
2Kí o tó dá àwọn òkè,
ati kí o tó dá ilẹ̀ ati ayé,
láti ayérayé, ìwọ ni Ọlọrun.
3O sọ eniyan di erùpẹ̀ pada,
o sì wí pé, “Ẹ yipada, ẹ̀yin ọmọ eniyan.”
4Nítorí pé lójú rẹ, ẹgbẹrun ọdún dàbí àná,
tabi bí ìṣọ́ kan ní òru.
5Ìwọ a máa gbá ọmọ eniyan dànù; wọ́n dàbí àlá,
bíi koríko tí ó tutù ní òwúrọ̀;
6ní òwúrọ̀ á máa gbilẹ̀, á sì máa jí pérépéré;
ní ìrọ̀lẹ́ á sá, á sì rọ.#2 Pet 3:8
7Ibinu rẹ pa wá run;
ìrúnú rẹ sì bò wá mọ́lẹ̀.
8O ti gbé ẹ̀ṣẹ̀ wa kalẹ̀ ní iwájú rẹ;
àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ìkọ̀kọ̀ wa sì hàn kedere ninu ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ.
9Nítorí ọjọ́ ayé wa ń kọjá lọ ninu ibinu rẹ;
ayé wa sì ń dópin bí ẹni mí kanlẹ̀.
10Aadọrin ọdún ni ọjọ́ ayé wa;
pẹlu ipá a lè tó ọgọrin;
sibẹ gbogbo rẹ̀ jẹ́ kìkì làálàá ati ìyọnu;
kíá, ayé wa á ti dópin, ẹ̀mí wa á sì fò lọ.#Sir 18:8-9
11Ta ló mọ agbára ibinu rẹ?
Ta ló sì mọ̀ pé bí ẹ̀rù rẹ ti tó bẹ́ẹ̀ ni ibinu rẹ rí?
12Nítorí náà kọ́ wa láti máa ka iye ọjọ́ orí wa,
kí á lè kọ́gbọ́n.
13Yipada sí wa, OLUWA; yóo ti pẹ́ tó tí o óo máa bínú sí wa?
Ṣàánú àwa iranṣẹ rẹ.
14Fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ tẹ́ wa lọ́rùn ní òwúrọ̀,
kí á lè máa yọ̀, kí inú wa sì máa dùn
ní gbogbo ọjọ́ ayé wa.
15Mú inú wa dùn fún iye ọjọ́ tí o
ti fi pọ́n wa lójú,
ati fún iye ọdún tí ojú wa ti fi rí ibi.
16Jẹ́ kí iṣẹ́ rẹ hàn sí àwọn iranṣẹ rẹ,
kí agbára rẹ tí ó lógo sì hàn sí àwọn ọmọ wọn.
17Jẹ́ kí ojurere OLUWA Ọlọrun wa wà lára wa,
fi ìdí iṣẹ́ ọwọ́ wa múlẹ̀,
jẹ́ kí iṣẹ́ ọwọ́ wa fi ìdí múlẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 90: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀