I. Kor 1

1
Ìkíni
1PAULU, ẹniti a pè lati jẹ Aposteli Jesu Kristi nipa ifẹ Ọlọrun, ati Sostene arakunrin,
2Si ijọ enia Ọlọrun ti o wà ni Korinti, awọn ti a sọ di mimọ́ ninu Kristi Jesu, awọn ẹniti a npè li enia mimọ́, pẹlu gbogbo awọn ti npè orukọ Jesu Kristi Oluwa wa nibigbogbo, ẹniti iṣe tiwọn ati tiwa:
3Ore-ọfẹ si nyin, ati alafia, lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Oluwa wa Jesu Kristi.
Ìdúpẹ́
4Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun mi nigbagbogbo nitori nyin, nitori ore-ọfẹ Ọlọrun ti a fifun nyin ninu Jesu Kristi;
5Nitoripe nipasẹ rẹ̀ li a ti sọ nyin di ọlọrọ̀ li ohun gbogbo, ninu ọ̀rọ-isọ gbogbo, ati ninu ìmọ gbogbo;
6Ani gẹgẹ bi a ti fi idi ẹrí Kristi kalẹ ninu nyin:
7Tobẹ ti ẹnyin kò fi rẹ̀hin ninu ẹ̀bunkẹbun; ti ẹ si nreti ifarahàn Oluwa wa Jesu Kristi:
8Ẹniti yio si fi idi nyin kalẹ titi de opin, ki ẹnyin ki o le jẹ alailẹgàn li ọjọ Oluwa wa Jesu Kristi.
9Olododo li Ọlọrun, nipasẹ ẹniti a pè nyin sinu ìdapọ Ọmọ rẹ̀ Jesu Kristi Oluwa wa.
Ìyapa ninu Ìjọ
10Mo si bẹ̀ nyin, ará, li orukọ Oluwa wa Jesu Kristi, ki gbogbo nyin mã sọ̀rọ ohun kanna, ati ki ìyapa ki o máṣe si ninu nyin; ṣugbọn ki a le ṣe nyin pé ni inu kanna, ati ni ìmọ kanna.
11Nitori a ti fihàn mi nipa tinyin, ará mi, lati ọdọ awọn ara ile Kloe, pe ìja mbẹ larin nyin.
12Njẹ eyi ni mo wipe, olukuluku nyin nwipe, Emi ni ti Paulu; ati emi ni ti Apollo; ati emi ni ti Kefa; ati emi ni ti Kristi.
13A ha pin Kristi bi? iṣe Paulu li a kàn mọ agbelebu fun nyin bi? tabi li orukọ Paulu li a baptisi nyin si?
14Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun pe emi kò baptisi ẹnikẹni ninu nyin, bikoṣe Krispu ati Gaiu;
15Ki ẹnikẹni ki o máṣe wipe mo ti mbaptisi li orukọ emi tikarami.
16Mo si baptisi awọn ara ile Stefana pẹlu: lẹhin eyi emi kò mọ̀ bi mo ba baptisi ẹlomiran pẹlu.
17Nitori Kristi kò rán mi lọ ibaptisi, bikoṣe lati wãsu ihinrere: kì iṣe nipa ọgbọ́n ọ̀rọ, ki a máṣe sọ agbelebu Kristi di alailagbara.
Kristi Ni Agbára ati Ọgbọ́n Ọlọrun
18Nitoripe wère li ọ̀rọ agbelebu si awọn ti o nṣegbé; ṣugbọn si awa ti a ngbalà, agbara Ọlọrun ni.
19Nitoriti a kọ ọ pe, Emi ó pa ọgbọ́n awọn ọlọ́gbọn run, emi ó si sọ òye awọn olóye di asan.
20Ọlọ́gbọn na ha da? akọwe na ha da? ojiyan aiye yi na ha da? Ọlọrun kò ha ti sọ ọgbọ́n aiye yi di wère?
21Nitoripe ninu ọgbọ́n Ọlọrun niwọnbi aiye kò ti mọ̀ nitori ọgbọ́n, o wù Ọlọrun nipa wère iwasu lati gbà awọn ti o gbagbọ́ là.
22Nitoripe awọn Ju mbère àmi, awọn Hellene si nṣafẹri ọgbọ́n:
23Ṣugbọn awa nwasu Kristi ti a kàn mọ agbelebu, ikọsẹ̀ fun awọn Ju, ati wère fun awọn Hellene,
24Ṣugbọn fun awọn ti a pè, ati Ju ati Hellene, Kristi li agbara Ọlọrun, ati ọgbọ́n Ọlọrun.
25Nitoripe wère Ọlọrun gbọ́n jù enia lọ; ati ailera Ọlọrun li agbara jù enia lọ.
26Ẹ sa wo ìpè nyin, ará, bi o ti ṣepe kì iṣe ọ̀pọ awọn ọlọ́gbọn enia nipa ti ara, kì iṣe ọ̀pọ awọn alagbara, kì iṣe ọ̀pọ awọn ọlọlá li a pè:
27Ṣugbọn Ọlọrun ti yàn awọn ohun wère aiye lati fi dãmu awọn ọlọgbọ́n; Ọlọrun si ti yàn awọn ohun ailera aiye lati fi dãmu awọn ohun ti o li agbara;
28Ati awọn ohun aiye ti kò niyìn, ati awọn ohun ti a nkẹgàn, li Ọlọrun si ti yàn, ani, awọn ohun ti kò si, lati sọ awọn ohun ti o wà di asan:
29Ki o máṣe si ẹlẹran-ara ti yio ṣogo niwaju rẹ̀.
30Ṣugbọn nipasẹ rẹ̀ li ẹnyin wà ninu Kristi Jesu, ẹniti Ọlọrun fi ṣe ọgbọ́n, ati ododo, ati isọdimimọ́, ati idande fun wa:
31Pe, gẹgẹ bi a ti kọ ọ, Ẹniti o ba nṣogo, ki o mã ṣogo ninu Oluwa.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

I. Kor 1: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀