I. Kor 6

6
Onigbagbọ Ń Pe Ara Wọn Lẹ́jọ́ Níwájú Àwọn Alaigbagbọ
1ẸNIKẸNI ninu nyin, ti o ni ọ̀ran kan si ẹnikeji rẹ̀, ha gbọdọ lọ pè e li ẹjọ niwaju awọn alaiṣõtọ, ki o má si jẹ niwaju awọn enia mimọ́?
2Ẹnyin kò ha mọ̀ pe awọn enia mimọ́ ni yio ṣe idajọ aiye? Njẹ bi o ba ṣepe a ó tipasẹ nyin ṣe idajọ aiye, ẹnyin ha ṣe alaiyẹ lati ṣe idajọ awọn ọ̀ran ti o kere julọ?
3E kò mọ̀ pe awa ni yio ṣe idajọ awọn angẹli? melomelo li ohun ti iṣe ti aiye yi?
4Njẹ bi ẹnyin ni yio ba ṣe idajọ ohun ti iṣe ti aiye yi, ẹnyin ha nyan awọn ti a kò kà si rara ninu ijọ ṣe onidajọ?
5Mo sọ eyi fun itiju nyin. O ha le jẹ bẹ̃ pe kò si ọlọgbọn kan ninu nyin ti yio le ṣe idajọ larin awọn arakunrin rẹ̀?
6Ṣugbọn arakunrin npè arakunrin li ẹjọ, ati eyini niwaju awọn alaigbagbọ́.
7Njẹ nisisiyi, abuku ni fun nyin patapata pe ẹnyin mba ara nyin ṣe ẹjọ. Ẽṣe ti ẹnyin kò kuku gbà ìya? ẽṣe ti ẹnyin kò kuku jẹ ki a rẹ́ nyin jẹ?
8Ṣugbọn ẹnyin njẹni ni ìya, ẹ sì nrẹ́ ni jẹ, ati eyini awọn arakunrin nyin.
9Ẹnyin kò mọ̀ pe awọn alaiṣõtọ kì yio jogún ijọba Ọlọrun? Ki a má tàn nyin jẹ: kì iṣe awọn àgbere, tabi awọn abọriṣa, tabi awọn panṣaga, tabi awọn alailera, tabi awọn ti nfi ọkunrin bà ara wọn jẹ́,
10Tabi awọn olè, tabi awọn olojukòkoro, tabi awọn ọmuti, tabi awọn ẹlẹgàn, tabi awọn alọnilọwọgbà ni yio jogún ijọba Ọlọrun.
11Bẹ̃ li awọn ẹlomiran ninu nyin si ti jẹ rí: ṣugbọn a ti wẹ̀ nyin nù, ṣugbọn a ti sọ nyin di mimọ́, ṣugbọn a ti da nyin lare li orukọ Jesu Kristi Oluwa, ati nipa Ẹmí Ọlọrun wa.
Ẹ Fi Ara Yín Yin Ọlọrun
12Ohun gbogbo li o yẹ fun mi, ṣugbọn ki iṣe ohun gbogbo li o li ère: ohun gbogbo li o yẹ fun mi, ṣugbọn emi kì yio jẹ ki a fi mi sabẹ agbara ohunkohun.
13Onjẹ fun inu, ati inu fun onjẹ: ṣugbọn Ọlọrun yio fi opin si ati inu ati onjẹ. Ṣugbọn ara kì iṣe ti àgbere, bikoṣe fun Oluwa; ati Oluwa fun ara.
14Ṣugbọn Ọlọrun ti jí Oluwa dide, yio si jí awa dide pẹlu nipa agbara rẹ̀.
15Ẹnyin kò mọ̀ pe ẹ̀ya-ara Kristi li ara nyin iṣe? njẹ emi o ha mu ẹ̀ya-ara Kristi, ki emi ki o si fi ṣe ẹ̀ya-ara àgbere bi? ki a má ri.
16Tabi, ẹnyin kò mọ̀ pe ẹniti o ba dàpọ mọ́ àgbere di ara kan? nitoriti o wipe, Awọn mejeji ni yio di ara kan.
17Ṣugbọn ẹniti o dàpọ mọ́ Oluwa di ẹmí kan.
18Ẹ mã sá fun àgbere. Gbogbo ẹ̀ṣẹ ti enia ndá o wà lode ara; ṣugbọn ẹniti o nṣe àgbere nṣẹ̀ si ara on tikararẹ̀.
19Tabi, ẹnyin kò mọ̀ pe ara nyin ni tẹmpili Ẹmí Mimọ́, ti mbẹ ninu nyin, ti ẹnyin ti gbà lọwọ Ọlọrun? ẹnyin kì si iṣe ti ara nyin,
20Nitori a ti rà nyin ni iye kan: nitorina ẹ yìn Ọlọrun logo ninu ara nyin, ati ninu ẹmí nyin, ti iṣe ti Ọlọrun.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

I. Kor 6: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀