I. Tes 5
5
Ẹ Múra Sílẹ̀ De Ìpadàbọ̀ Oluwa
1ṢUGBỌN niti akokò ati ìgba wọnni, ará, ẹnyin kò tun fẹ ki a kọ ohunkohun si nyin,
2Nitoripe ẹnyin tikaranyin mọ̀ dajudaju pe, ọjọ Oluwa mbọ̀wá gẹgẹ bi olè li oru.
3Nigbati nwọn ba nwipe, alafia ati ailewu; nigbana ni iparun ojijì yio de sori wọn gẹgẹ bi irọbi lori obinrin ti o lóyun; nwọn kì yio si le sálà.
4Ṣugbọn ẹnyin, ará, kò si ninu òkunkun, ti ọjọ na yio fi de bá nyin bi olè.
5Nitori gbogbo nyin ni ọmọ imọlẹ, ati ọmọ ọsán: awa kì iṣe ti oru, tabi ti òkunkun.
6Nitorina ẹ máṣe jẹ ki a sùn, bi awọn iyoku ti nṣe; ṣugbọn ẹ jẹ ki a mã ṣọna ki a si mã wa ni airekọja.
7Nitori awọn ti nsùn, ama sùn li oru; ati awọn ti nmutipara, ama mutipara li oru.
8Ṣugbọn ẹ jẹ ki awa, bi a ti jẹ ti ọsán, mã wà li airekọja, ki a mã gbé igbaiya igbagbọ́ ati ifẹ wọ̀; ati ireti igbala fun aṣibori.
9Nitori Ọlọrun yàn wa ki iṣe si ibinu, ṣugbọn si ati ni igbala nipasẹ Jesu Kristi Oluwa wa,
10Ẹniti o kú fun wa, pe bi a ba jí, tabi bi a ba sùn, ki a le jùmọ wà lãye pẹlu rẹ̀.
11Nitorina ẹ mã gbà ara nyin niyanju, ki ẹ si mã fi ẹsẹ ara nyin mulẹ, ani gẹgẹ bi ẹnyin ti nṣe.
Gbolohun Ìparí
12Ṣugbọn awa mbẹ̀ nyin, ará, lati mã mọ awọn ti nṣe lãla larin nyin, ti nwọn si nṣe olori nyin ninu Oluwa, ti nwọn si nkìlọ fun nyin;
13Ki ẹ si mã bu ọla fun wọn gidigidi ninu ifẹ nitori iṣẹ wọn. Ẹ si mã wà li alafia lãrin ara nyin.
14Ṣugbọn awa mbẹ̀ nyin, ará, ki ẹ mã kìlọ fun awọn ti iṣe alaigbọran, ẹ mã tù awọn alailọkàn ninu, ẹ mã ràn awọn alailera lọwọ, ẹ mã mu sũru fun gbogbo enia.
15Ẹ kiyesi i, ki ẹnikẹni ki o máṣe fi buburu san buburu fun ẹnikẹni; ṣugbọn ẹ mã lepa eyi ti iṣe rere nigbagbogbo, lãrin ara nyin, ati larin gbogbo enia.
16Ẹ mã yọ̀ nigbagbogbo.
17Ẹ mã gbadura li aisimi.
18Ẹ mã dupẹ ninu ohun gbogbo: nitori eyi ni ifẹ Ọlọrun ninu Kristi Jesu fun nyin.
19Ẹ máṣe pa iná Ẹmí.
20Ẹ máṣe kẹgan isọtẹlẹ.
21Ẹ mã wadi ohun gbogbo daju; ẹ dì eyiti o dara mu ṣinṣin.
22Ẹ mã takéte si ohun gbogbo ti o jọ ibi.
23Ki Ọlọrun alafia tikararẹ̀ ki o sọ nyin di mimọ́ patapata; ki a si pa ẹmí ati ọkàn ati ara nyin mọ́ patapata li ailabukù ni ìgba wíwa Oluwa wa Jesu Kristi.
24Olododo li ẹniti o pè nyin, ti yio si ṣe e.
25Ará, ẹ mã gbadura fun wa.
26Ẹ fi ifẹnukonu mimọ́ kí gbogbo awọn ará.
27Mo fi Oluwa mu nyin bura pe, ki a ka iwe yi fun gbogbo awọn ará.
28Ki ore-ọfẹ Oluwa wa Jesu Kristi ki o wà pẹlu nyin. Amin.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
I. Tes 5: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.