Oni 7
7
1ORUKỌ rere dara jù ororo ikunra; ati ọjọ ikú jù ọjọ ibi enia lọ.
2O dara lati lọ si ile ọ̀fọ jù ati lọ si ile àse: nitoripe eyi li opin gbogbo enia; alãye yio si pa a mọ́ li aiya rẹ̀.
3Ibinujẹ san jù ẹrín: nitoripe nipa ifaro oju a si mu aiya san.
4Aiya ọlọgbọ́n mbẹ ni ile ọ̀fọ; ṣugbọn aiya aṣiwère ni ile iré.
5O san lati gbọ́ ibawi ọlọgbọ́n jù ki enia ki o fetisi orin aṣiwère.
6Nitoripe bi itapàpa ẹgún labẹ ìkoko, bẹ̃li ẹrín aṣiwère: asan li eyi pẹlu.
7Nitõtọ inilara mu ọlọgbọ́n enia sinwin; ọrẹ a si ba aiya jẹ.
8Opin nkan san jù ipilẹṣẹ rẹ̀ lọ: ati onisuru ọkàn jù ọlọkàn igberaga.
9Máṣe yara li ọkàn rẹ lati binu, nitoripe ibinu simi li aiya aṣiwère.
10Iwọ máṣe wipe, nitori kili ọjọ iṣaju ṣe san jù wọnyi lọ? nitoripe iwọ kò fi ọgbọ́n bere niti eyi.
11Ọgbọ́n dara gẹgẹ bi iní, ati nipasẹ rẹ̀ ère wà fun awọn ti nri õrùn.
12Nitoripe ãbò li ọgbọ́n, ani bi owo ti jẹ́ abò: ṣugbọn ère ìmọ ni pe, ọgbọ́n fi ìye fun awọn ti o ni i.
13Wò iṣẹ Ọlọrun: nitoripe, tali o le mu eyini tọ́ ti on ṣe ni wiwọ?
14Li ọjọ alafia, mã yọ̀, ṣugbọn li ọjọ ipọnju, ronu pe, bi Ọlọrun ti da ekini bẹ̃li o da ekeji, niti idi eyi pe ki enia ki o máṣe ri nkan ti mbọ̀ lẹhin rẹ̀.
15Ohun gbogbo ni mo ri li ọjọ asan mi: olõtọ enia wà ti o ṣegbé ninu ododo rẹ̀, ati enia buburu wà ti ọjọ rẹ̀ pẹ ninu ìwa buburu rẹ̀.
16Iwọ máṣe ododo aṣeleke; bẹ̃ni ki iwọ ki o máṣe fi ara rẹ ṣe ọlọgbọ́n aṣeleke: nitori kini iwọ o ṣe run ara rẹ?
17Iwọ máṣe buburu aṣeleke, bẹ̃ni ki iwọ ki o má ṣiwère; nitori kini iwọ o ṣe kú ki ọjọ rẹ ki o to pe?
18O dara ki iwọ ki o dì eyi mu; pẹlupẹlu iwọ máṣe yọ ọwọ rẹ kuro ninu eyi: nitori ẹniti o bẹ̀ru Ọlọrun ni yio yọ kuro ninu rẹ̀ gbogbo.
19Ọgbọ́n mu ọlọgbọ́n lara le jù enia alagbara mẹwa lọ ti o wà ni ilu.
20Nitoriti kò si olõtọ enia lori ilẹ, ti nṣe rere ti kò si dẹṣẹ.
21Pẹlupẹlu máṣe fiyesi gbogbo ọ̀rọ ti a nsọ; ki iwọ ki o má ba gbọ́ ki iranṣẹ rẹ ki o bu ọ.
22Nitoripe nigba pupọ pẹlu li aiya rẹ mọ̀ pe iwọ tikalarẹ pẹlu ti bu awọn ẹlomiran.
23Idi gbogbo wọnyi ni mo fi ọgbọ́n wá; mo ni, emi o gbọ́n: ṣugbọn ọ̀na rẹ̀ jin si mi.
24Eyi ti o jinna, ti o si jinlẹ gidigidi, tali o le wá a ri?
25Mo fi aiya mi si i lati mọ̀, on ati wadi, on ati ṣe afẹri ọgbọ́n ati oye, on ati mọ̀ ìwa buburu wère, ani ti wère ati ti isinwin:
26Mo si ri ohun ti o korò jù ikú lọ, ani obinrin ti aiya rẹ̀ iṣe idẹkun ati àwọn, ati ọwọ rẹ̀ bi ọbára: ẹnikẹni ti inu Ọlọrun dùn si yio bọ lọwọ rẹ̀; ṣugbọn ẹlẹṣẹ li a o ti ọwọ rẹ̀ mu.
27Kiyesi i, eyi ni mo ri, bẹ̃li oniwasu wi, ni wiwadi rẹ̀ li ọkọkan lati ri oye.
28Ti ọkàn mi nwakiri sibẹ, ṣugbọn emi kò ri: ọkunrin kanṣoṣo ninu ẹgbẹrun ni mo ri; ṣugbọn obinrin kan ninu gbogbo awọn wọnni, emi kò ri.
29Kiyesi i, eyi nikanṣoṣo ni mo ri, pe, Ọlọrun ti da enia ni iduroṣinṣin; ṣugbọn nwọn ti ṣe afẹri ihumọkihumọ.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Oni 7: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: