Joṣ Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ìwé Joṣua ni ó sọ ìtàn bí àwọn ọmọ Israẹli ṣe jagun gba ilẹ̀ Kenaani, lábẹ́ àkóso Joṣua, ẹni tí ó gba ipò Mose gẹ́gẹ́ bí olùdarí àwọn ọmọ Israẹli. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pataki tí a sọ nípa rẹ̀ ninu ìwé yìí ni: bí àwọn ọmọ Israẹli ṣe rékọjá odò Jordani; bí odi Jẹriko ṣe wó lulẹ̀; ogun tí wọ́n jà ní Ai, ati bí wọ́n ṣe tún majẹmu dá pẹlu Ọlọrun. Ẹsẹ tí ọpọlọpọ eniyan mọ̀ jù ninu ìwé yìí ni orí 24 ẹsẹ 15 tí ó kà báyìí pé, “Ẹ yan ẹni tí ẹ̀yin ó máa sin ni oni ... ṣùgbọ́n bi o ṣe ti emi ati ile mi ni, OLUWA ni awa o máa sin.”
Àwọn Ohun tí ó wà ninú Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Ṣiṣẹgun àwọn ará Kenaani 1:1—12:24
Pínpín ilẹ̀ náà 13:1—21:45
a. Ilẹ̀ apá ìlà oòrùn Jọdani 13:1-33
b. Ilẹ̀ apá ìwọ̀ oòrùn Jọdani 14:1—19:51
d. Àwọn ìlú ààbò 20:1-9
e. Àwọn ìlú àwọn ọmọ Lefi 21:1-45
Àwọn ẹ̀yà ìlà oòrùn pada sí agbègbè wọn 22:1-34
Ọ̀rọ̀ ìdágbére Joṣua 23:1-16
Àtúnṣe majẹmu ní Ṣekemu 24:1-33
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Joṣ Ọ̀rọ̀ Iṣaaju: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.