O. Daf 32

32
Ìjẹ́wọ́ Ẹ̀ṣẹ̀
1IBUKÚN ni fun awọn ti a dari irekọja wọn jì, ti a bò ẹ̀ṣẹ wọn mọlẹ.
2Ibukún ni fun ọkunrin na ẹniti Oluwa kò kà ẹ̀ṣẹ si lọrun, ati ninu ẹmi ẹniti ẹ̀tan kò si.
3Nigbati mo dakẹ, egungun mi di gbigbo nitori igbe mi ni gbogbo ọjọ.
4Nitori li ọsan ati li oru, ọwọ rẹ wuwo si mi lara: omi ara mi si dabi ọdá-ẹ̀run.
5Emi jẹwọ ẹ̀ṣẹ mi fun ọ, ati ẹ̀ṣẹ mi li emi kò si fi pamọ́. Emi wipe, emi o jẹwọ ìrekọja mi fun Oluwa: iwọ si dari ẹbi ẹ̀ṣẹ mi jì.
6Nitori eyi li olukulùku ẹni ìwa-bi-ọlọrun yio ma gbadura si ọ ni igba ti a le ri ọ: nitõtọ ninu iṣan-omi nla, nwọn kì yio sunmọ ọdọ rẹ̀.
7Iwọ ni ibi ipamọ́ mi: iwọ o pa mi mọ́ kuro ninu iṣẹ́; iwọ o fi orin igbala yi mi ka kiri.
8Emi o fi ẹsẹ̀ rẹ le ọ̀na, emi o si kọ́ ọ li ọ̀na ti iwọ o rìn: emi o ma fi oju mi tọ́ ọ.
9Ki ẹnyin ki o máṣe dabi ẹṣin tabi ibaka, ti kò ni iyè ninu: ẹnu ẹniti a kò le ṣe aifi ijanu bọ̀, ki nwọn ki o má ba sunmọ ọ.
10Ọ̀pọ ikãnu ni yio wà fun enia buburu: ṣugbọn ẹniti o ba gbẹkẹle Oluwa, ãnu ni yio yi i ka kiri.
11Ki inu nyin ki o dùn niti Oluwa, ẹ si ma yọ̀, ẹnyin olododo; ẹ si ma kọrin fun ayọ̀, gbogbo ẹnyin ti aiya nyin duro ṣinṣin.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

O. Daf 32: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀