Tit Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Titu kì í ṣe Juu, ṣugbọn ó di onigbagbọ. Ó sì di alábàáṣiṣẹ́ ati olùrànlọ́wọ́ Paulu ninu ìrìn àjò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ajíyìnrere. Paulu kọ ìwé tí à ń pè ní Ìwé Paulu sí Titu sí ọdọmọkunrin olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ yìí ní Kirete. Paulu ni ó fi Titu sí Kirete pé kí ó máa mójú tó iṣẹ́ ìjọ níbẹ̀. Àwọn nǹǹkan àfiyèsí mẹta ni ìwé yìí mẹ́nu bà.
Lákọ̀ọ́kọ́, Paulu rán Titu létí irú ìwà tí ó yẹ kí àwọn aṣaaju ninu ìjọ máa hù, pataki jù lọ, nítorí ìwà burúkú ọ̀pọ̀ ninu àwọn ará Kirete. Lẹ́yìn èyíi, Paulu gba Titu ní ìmọ̀ràn lórí bí ó ṣe yẹ kí ó máa kọ́ oríṣìíríṣìí ìṣọ̀wọ́ àwọn eniyan ninu ìjọ: àwọn bíi àgbà ọkunrin ati àwọn àgbà obinrin (àwọn àgbà obinrin ni Paulu ní kí ó máa kọ́ àwọn ọdọmọbinrin), lẹ́yìn náà àwọn ọdọmọkunrin ati àwọn ẹrú. Ní ìparí, Paulu gba Titu ní ìmọ̀ràn nípa ìhùwàsí onigbagbọ, pataki jù lọ bí onigbagbọ ti níláti máa wá alaafia ati ìrẹ́pọ̀, tí yóo sì máa yẹra fún ìkórìíra, iyàn jíjà, ati ìyapa ninu ìjọ.
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Ọ̀rọ̀ iṣaaju 1:1-4
Àwọn olóyè ìjọ 1:5-16
Iṣẹ́ oríṣìíríṣìí ìṣọ̀wọ́ àwọn ọmọ ìjọ 2:1-15
Ìgbani-níyànjú ati ìkìlọ̀ 3:1-11
Ọ̀rọ̀ ìparí 3:12-15
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Tit Ọ̀rọ̀ Iṣaaju: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.