1 Kọrinti Ìfáàrà

Ìfáàrà
Paulu ti fi ẹsẹ̀ ilé Ọlọ́run múlẹ̀ ní ìlú ńlá Giriki ti ṣe Kọrinti ní ìrìnàjò iṣẹ́ rẹ̀ kejì (Ìṣe àwọn Aposteli 18.18). Ṣùgbọ́n nǹkan kò fi ara rọ lẹ́yìn ìgbà tó fi ibẹ̀ sílẹ̀. Ó wòye pé ó yẹ kí òun kọ̀wé lórí àwọn oríṣìíríṣìí wàhálà tó ń farahàn níbẹ̀. Wọ́n ń gbógun ti iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aposteli, wọ́n ń gba oúnjẹ alẹ́ Olúwa sódì, wọ́n ń rin ìrìn alẹ́ kiri láti jẹ ẹran tí wọ́n fi rú ẹbọ sí òrìṣà, wọ́n gbé ara wọn lọ ilé ìdájọ́, wọ́n fi ààyè gba ìṣekúṣe, wọ́n ń ṣe àìṣòótọ́ sí àjíǹde, wọ́n sì ń ṣe àríyànjiyàn nípa ìgbéyàwó àti ọ̀pọ̀ nǹkan mìíràn. Paulu wòye pé ó yẹ kí òun ṣe ẹ̀tọ́ òun lórí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ni Kọrinti, kí gbogbo ohun tí ó ń tẹ̀síwájú má ba à túká yángá. Bí Paulu ti ń sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìṣòro wọ̀nyí lẹ́sẹẹsẹ ni ó sì ń hú gbòǹgbò ohun tó jẹ́ ẹ̀kọ́ nípa ìgbàgbọ́ jáde.
Olúborí ète Paulu láti kọ ìwé yìí sí ìjọ Ọlọ́run ni ìlú Kọrinti ní láti ṣe àtúnṣe lórí àwọn ìṣekúṣe tó ń gbilẹ̀, àti láti ṣàlàyé ìgbé ayé àlàáfíà. Kò tọ́ láti kan sọ pé onígbàgbọ́ ni wá, ìṣe onígbàgbọ́ gbọdọ̀ jẹ jáde nínú ìgbé ayé wa. Tí kò bá rí bẹ́ẹ̀, a ó ta èpò sí àlà iṣẹ́ rere Kristi. Paulu fi Kristi hàn bí olùṣe ohun gbogbo. Nínú Kristi, a di aláìlábàwọ́n, mímọ́ àti ẹni ìtẹ́wọ́gbà ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́run (1.30).
Kókó-ọ̀rọ̀
i. Àwọn Ìkíni 1.1-9.
ii. Ìyapa nínú ìjọ Ọlọ́run 1.10–4.21.
iii. Èdè-àìyedè nínú ìjọ Ọlọ́run 5–6.
iv. Ọ̀rọ̀ nípa Ìgbéyàwó 7.1-40.
v. Ọ̀rọ̀ nípa àìṣedéédéé 8.1–11.1.
vi. Ọ̀rọ̀ nípa Ìsìn 11.2–14.40.
vii. Ọ̀rọ̀ nípa àjíǹde 15.1-58.
viii. Ọ̀rọ̀ nípa ara ẹni 16.1-24.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

1 Kọrinti Ìfáàrà: YCB

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀