1 Timotiu Ìfáàrà

Ìfáàrà
Paulu kọ lẹ́tà yìí nígbà tí ìgbé ayé rẹ̀ súnmọ́ òpin, ó sí kọ́ sí alábáṣiṣẹ́ rẹ̀, Timotiu, ẹni tí ó fi sílẹ̀ ní Efesu láti ṣe àtúnṣe lórí àwọn ìṣòro ìjọ Ọlọ́run níbẹ̀. Ní àsìkò yìí, èdè-àìyedè ti bẹ̀rẹ̀ sí gbilẹ̀ lórí ẹ̀kọ́ ìjọ, ohun tí wọ́n ń ṣe nínú ilé Ọlọ́run, ìṣàkóso ìjọ Ọlọ́run tí ó fi dé orí ohun tó jẹ mọ́ ìgbé ayé Kristiani pátápátá. Paulu kọ̀wé láti fi sọ fún Timotiu lórí àwọn nǹkan wọ̀nyí kí ìjọ Ọlọ́run bá a le máa tẹ̀síwájú bí ó ti yẹ. Ó kọ̀wé láti fi mú Timotiu ní ọkàn le, kí ìrẹ̀wẹ̀sì má bá ìgbé ayé rẹ̀ níwọ̀n ìgbà tí ó ti jẹ́ Kristiani, ṣùgbọ́n kí ó lè máa gbé nínú oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, èyí ni àwọn òfin nípa fífi àwọn olùdarí sórí ìjọ Ọlọ́run pẹ̀lú.
Ṣíṣe ìgbàgbọ́ lọ́nà tó tọ̀nà pẹ̀lú híhu ìwà tí ó dára ni ó jẹ́ kókó inú ìwé náà. Paulu tẹnumọ́ ọn pé a gbọdọ̀ mọ òtítọ́, a sì gbọdọ̀ dáàbò bò ó lọ́wọ́ àwọn ẹ̀kọ́ òdì tó ń gbórí. A gbọdọ̀ gbé ìgbé ayé tó bá ẹ̀kọ́ ìjọ Ọlọ́run mú ní ọ̀nà ti èṣù kò ní fi rí ààyè gba ìgbé ayé àwọn ènìyàn Ọlọ́run, Ó tẹnumọ́ ọn bí ó ṣe ṣe pàtàkì kí àwọn tó fi ara wọn fún Ọlọ́run àti àwọn tí ọkàn wọn mọ́ jẹ́ aṣíwájú ìjọ Ọlọ́run.
Kókó-ọ̀rọ̀
i. Ìkìlọ̀ nípa ẹ̀kọ́ ẹ̀tàn 1.1-20.
ii. Ẹ̀kọ́ tó jẹ mọ́ gbígba àdúrà 2.1-15.
iii. Fífi àwọn alábojútó àti díákónì jẹ 3.1-16.
iv. Ìwàásù àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ 4.1–5.25.
v. Iṣẹ́ ìránṣẹ́ Kristiani àti pípe Timotiu níjà 6.1-21.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

1 Timotiu Ìfáàrà: YCB

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀