I. Kor 12:17-19
I. Kor 12:17-19 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bi gbogbo ara ba jẹ oju, nibo ni igbọràn iba gbé wà? Bi gbogbo rẹ̀ ba si jẹ igbọràn, nibo ni igbõrùn iba gbé wà? Ṣugbọn nisisiyi Ọlọrun ti fi awọn ẹ̀ya sinu ara, olukuluku wọn gẹgẹ bi o ti wù u. Bi gbogbo wọn ba si jẹ ẹ̀ya kan, nibo li ara iba gbé wà?
I. Kor 12:17-19 Yoruba Bible (YCE)
Bí gbogbo ara bá jẹ́ ojú, báwo ni yóo ti ṣe gbọ́ràn? Bí gbogbo ara bá jẹ́ etí, báwo ni yóo ti ṣe gbóòórùn? Ṣugbọn lóòótọ́ ni, Ọlọrun fi àwọn ẹ̀yà ara kọ̀ọ̀kan sí ipò wọn bí ó ti wù ú. Bí ó bá jẹ́ pé ẹ̀yà kan ṣoṣo ni gbogbo ara ní, níbo ni ara ìbá wà?
I. Kor 12:17-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bí gbogbo ara bá jẹ́ ojú, níbo ni ìgbọ́ran ìbá gbé wà? Bí gbogbo ara bá jẹ́ etí, níbo ni ìgbóórùn ìbá gbé wà? Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti fi àwọn ẹ̀yà ara si ara wa, ó sí fi ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan sí ibi tí ó fẹ́ kí ó wà. Bí gbogbo wọn bá sì jẹ́ ọ̀kan ṣoṣo nínú ẹ̀yà ara, níbo ni ara yóò gbé wà.