I. Joh 4:1-2
I. Joh 4:1-2 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUFẸ, ẹ máṣe gbà gbogbo ẹmí gbọ́, ṣugbọn ẹ dán awọn ẹmí wò bi nwọn ba ṣe ti Ọlọrun: nitori awọn woli eke pupọ̀ ti jade lọ sinu aiye. Eyi li ẹ o fi mọ̀ Ẹmí Ọlọrun: gbogbo ẹmí ti o ba jẹwọ pe, Jesu Kristi wá ninu ara, ti Ọlọrun ni
I. Joh 4:1-2 Yoruba Bible (YCE)
Olùfẹ́, ẹ má ṣe gba gbogbo ẹni tí ó bá wí pé òun ní Ẹ̀mí Ọlọrun gbọ́. Ẹ kọ́kọ́ wádìí wọn láti mọ ẹni tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun, nítorí ọpọlọpọ àwọn èké wolii ti wọ inú ayé. Ọ̀nà tí a óo fi mọ Ẹ̀mí Ọlọrun nìyí: gbogbo ẹni tí ó bá jẹ́wọ́ pé Jesu Kristi wá sáyé gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́ran-ara jẹ́ ẹni tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun.
I. Joh 4:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Olùfẹ́, ẹ má ṣe gba gbogbo ẹ̀mí gbọ́, ṣùgbọ́n ẹ dán àwọn ẹ̀mí wò bí wọn ba ń ṣe tí Ọlọ́run: nítorí àwọn wòlíì èké púpọ̀ tí jáde lọ sínú ayé. Èyí ni ẹ ó fi mọ Ẹ̀mí Ọlọ́run: gbogbo ẹ̀mí tí ó ba jẹ́wọ́ pé, Jesu Kristi wá nínú ara, ti Ọlọ́run ni