Efe 3:14-21
Efe 3:14-21 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori idi eyi ni mo ṣe nfi ẽkun mi kunlẹ fun Baba Oluwa wa Jesu Kristi, Orukọ ẹniti a fi npè gbogbo idile ti mbẹ li ọrun ati li aiye, Ki on ki o le fifun nyin, gẹgẹ bi ọrọ̀ ogo rẹ̀, ki a le fi agbara rẹ̀ mú nyin li okun nipa Ẹmí rẹ̀ niti ẹni inu; Ki Kristi ki o le mã gbé inu ọkàn nyin nipa igbagbọ; pe bi ẹ ti nfi gbongbo mulẹ, ti ẹ si nfi ẹsẹ mulẹ ninu ifẹ, Ki ẹnyin ki o le li agbara lati mọ̀ pẹlu gbogbo awọn enia mimọ́, kini ìbú, ati gigùn, ati jijìn, ati giga na jẹ, Ati lati mọ ifẹ Kristi ti o ta ìmọ yọ, ki a le fi gbogbo ẹ̀kún Ọlọrun kun nyin. Njẹ ẹniti o le ṣe lọpọlọpọ jù gbogbo eyiti a mbère tabi ti a nrò lọ, gẹgẹ bi agbara ti nṣiṣẹ ninu wa, On ni ki a mã fi ogo fun ninu ijọ ati ninu Kristi Jesu titi irandiran gbogbo, aiye ainipẹkun. Amin.
Efe 3:14-21 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí èyí ni mo ṣe ń fi ìkúnlẹ̀ gbadura sí Baba, tí à ń fi orúkọ rẹ̀ pe gbogbo ìdílé lọ́run ati láyé. Mò ń gbadura pé, gẹ́gẹ́ bíi títóbi ògo rẹ̀, kí ó fun yín ní agbára Ẹ̀mí rẹ̀ tí yóo fún ọkàn yín ní okun; kí Kristi fi ọkàn yín ṣe ilé nípa igbagbọ kí ẹ fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ ninu ìfẹ́, kí ìpìlẹ̀ ìgbé-ayé yín jẹ́ ti ìfẹ́, kí ẹ lè ní agbára, pẹlu gbogbo àwọn eniyan Ọlọrun, láti mọ bí ìfẹ́ Kristi ti gbòòrò tó, bí ó ti gùn tó, bí ó ti ga tó, ati bí ó ti jìn tó; kí ẹ lè mọ bí ìfẹ́ Kristi ti tayọ ìmọ̀ ẹ̀dá tó, kí ẹ sì lè kún fún gbogbo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ọlọrun. Ògo ni fún ẹni tí ó lè ṣe ju gbogbo nǹkan tí à ń bèèrè, ati ohun gbogbo tí a ní lọ́kàn lọ, gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀ tí ń ṣiṣẹ́ ninu wa. Kí ògo yìí wà fún un ninu ìjọ ati ninu Kristi Jesu láti ìrandíran títí laelae. Amin.
Efe 3:14-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí ìdí èyí ni mo ṣe ń fi eékún mi kúnlẹ̀ fún Baba Olúwa wa Jesu Kristi. Orúkọ ẹni tí a fi ń pe gbogbo ìdílé tí ń bẹ ni ọ̀run àti ní ayé. Kí òun kí ó lè fi agbára rẹ̀ fún ẹni inú yín ní okun, nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́. Kí Kristi lè máa gbé inú ọkàn yín nípa ìgbàgbọ́; pé bí ẹ ti ń fi gbòǹgbò múlẹ̀ tí ẹ sì ń fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìfẹ́; kí ẹ̀yin lè ní agbára láti mọ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́, ohun tí ìbú, àti gígùn, àti jíjìn, àti gíga ìfẹ́ Kristi jẹ́. Àti láti mọ̀ ìfẹ́ Kristi yìí tí ó ta ìmọ̀ yọ, kí a lè fi gbogbo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ọlọ́run kún yín. Ǹjẹ́ ẹni tí o lè ṣe lọ́pọ̀lọpọ̀ ju gbogbo èyí tí a ń béèrè tàbí tí a ń rò lọ, gẹ́gẹ́ bí agbára tí ń ṣiṣẹ́ nínú wa. Òun ni kí a máa fi ògo fún nínú ìjọ àti nínú Kristi Jesu láti ìrandíran gbogbo àní, ayé àìnípẹ̀kun, Àmín.