1
KỌRINTI KINNI 9:25-26
Yoruba Bible
Nítorí gbogbo àwọn tí ń sáré ìje a máa kó ara wọn ní ìjánu. Wọ́n ń ṣe èyí kí wọ́n lè gba adé tí yóo bàjẹ́. Ṣugbọn adé tí kò lè bàjẹ́ ni tiwa. Nítorí náà, aré tí èmi ń sá kì í ṣe ìsákúsàá láìní ète. Èmi kì í máa kan ẹ̀ṣẹ́ tèmi ní ìkànkukàn, bí ẹni tí ń kan afẹ́fẹ́ lásán lẹ́ṣẹ̀ẹ́.
Compare
Explore KỌRINTI KINNI 9:25-26
2
KỌRINTI KINNI 9:27
Ṣugbọn mò ń fi ìyà jẹ ara mi, mò ń kó ara mi ní ìjánu. Ìdí ni pé nígbà tí mo bá ti waasu fún àwọn ẹlòmíràn tán, kí èmi alára má baà di ẹni tí kò ní yege ninu iré-ìje náà.
Explore KỌRINTI KINNI 9:27
3
KỌRINTI KINNI 9:24
Ṣebí ẹ mọ̀ pé gbogbo àwọn tí ń sáré ìje ni ó ń sáré, ṣugbọn ẹnìkan ṣoṣo níí gba ẹ̀bùn. Ẹ sáré ní ọ̀nà tí ẹ óo fi rí ẹ̀bùn gbà.
Explore KỌRINTI KINNI 9:24
4
KỌRINTI KINNI 9:22
Nígbà tí mo bá wà láàrin àwọn aláìlera, èmi a di aláìlera, kí n lè jèrè àwọn aláìlera. Èmi a máa sọ ara mi di gbogbo nǹkan fún gbogbo eniyan, kí n lè gba àwọn kan ninu wọn là lọ́nà kan tabi lọ́nà mìíràn.
Explore KỌRINTI KINNI 9:22
Home
Bible
Plans
Videos