KỌRINTI KINNI 9
9
Iṣẹ́ ati Ẹ̀tọ́ Aposteli
1Ṣebí mo ní òmìnira? Ṣebí aposteli ni mí? Ṣebí mo ti rí Jesu Oluwa wa sójú? Ṣebí àyọrísí iṣẹ́ mi ninu Oluwa ni yín? 2Bí àwọn ẹlòmíràn kò bá tilẹ̀ gbà mí bí aposteli, ẹ̀yin gbọdọ̀ gbà mí ni, nítorí èdìdì iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi ninu Kristi ni ẹ jẹ́.
3Ìdáhùn mi nìyí fún àwọn tí wọn ń rí wí sí mi. 4Ṣé a kò ní ẹ̀tọ́ láti jẹ ati láti mu ni? 5Ṣé a kò ní ẹ̀tọ́ láti máa mú aya lọ́wọ́ ninu ìrìn àjò wa gẹ́gẹ́ bí àwọn aposteli yòókù ati àwọn arakunrin Oluwa ati Peteru? 6Àbí èmi ati Banaba nìkan ni a níláti máa ṣiṣẹ́ bọ́ ara wa? 7Ta ló jẹ́ ṣe iṣẹ́ ọmọ-ogun tí yóo tún máa bọ́ ara rẹ̀? Ta ló jẹ́ dá oko láì má jẹ ninu èso rẹ̀? Ta ló jẹ́ máa tọ́jú aguntan láìmu ninu wàrà aguntan tí ó ń tọ́jú?
8Kì í ṣe àpẹẹrẹ ti eniyan nìkan ni mo fi ń sọ nǹkan wọnyi. Ṣebí òfin náà sọ nípa nǹkan wọnyi. 9Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ ninu Òfin Mose pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ di ẹnu mààlúù tí o fi ń ṣiṣẹ́ lóko ọkà.” Ǹjẹ́ nítorí mààlúù ni Ọlọrun ṣe sọ èyí?#Diut 25:4; 1 Tim 5:18 10Tabi kò dájú pé nítorí tiwa ni ó ṣe sọ ọ́? Dájúdájú nítorí tiwa ni. Nítorí ó yẹ kí ẹni tí ń roko kí ó máa roko pẹlu ìrètí láti pín ninu ìkórè oko, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹni tí ó ń pa ọkà ní ìrètí láti pín ninu ọkà náà. 11Nígbà tí a fúnrúgbìn nǹkan ẹ̀mí fun yín, ṣé ó pọ̀jù pé kí á kórè nǹkan ti ara lọ́dọ̀ yín?#Rom 15:27 12Bí àwọn ẹlòmíràn bá ní ẹ̀tọ́ láti jẹ lára yín, ṣé ẹ̀tọ́ tiwa kò ju tiwọn lọ?
Ṣugbọn a kò lo anfaani tí a ní yìí. Kàkà bẹ́ẹ̀ à ń fara da ohun gbogbo kí á má baà fa ìdínà fún ìyìn rere Kristi. 13Ẹ kò mọ̀ pé àwọn tí ń ṣiṣẹ́ ninu Tẹmpili a máa jẹ lára ẹbọ, ati pé àwọn tí ń ṣiṣẹ́ níbi pẹpẹ ìrúbọ a máa pín ninu nǹkan ìrúbọ tí ó wà lórí pẹpẹ?#Diut 18:1 14Bẹ́ẹ̀ gan-an ni Oluwa pàṣẹ pé kí àwọn tí ó ń waasu ìyìn rere máa jẹ láti inú iṣẹ́ ìyìn rere.#Mat 10:10; Luk 10:7
15Ṣugbọn n kò lo anfaani yìí rí. Kì í ṣe pé kí n lè lo anfaani yìí ni mo ṣe ń sọ ohun tí mò ń sọ yìí. Nítorí ó yá mi lára kí ń kúkú kú jù pé kí ẹnikẹ́ni wá sọ ọ̀nà ìṣògo mi di asán lọ. 16Nítorí bí mo bá ń waasu ìyìn rere, kì í ṣe ohun tí mo lè máa fi ṣògo. Nítorí dandan ni ó jẹ́ fún mi. Bí n kò bá waasu ìyìn rere, mo gbé! 17Nítorí bí ó bá jẹ́ pé èmi fúnra mi ni mo yàn láti máa ṣe iṣẹ́ yìí, mo ní ẹ̀tọ́ láti retí èrè níbẹ̀. Ṣugbọn tí ó bá jẹ́ dandan ni mo fi ń ṣe é, iṣẹ́ ìríjú tí a fi sí ìtọ́jú mi ni. 18Kí wá ni èrè mi? Mo ní ìtẹ́lọ́rùn pé mò ń waasu ìyìn rere lọ́fẹ̀ẹ́, n kò lo anfaani tí ó tọ́ sí mi ninu iṣẹ́ ìyìn rere.
19Nítorí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òmìnira ni mo wà, tí n kò sì sí lábẹ́ ẹnìkan, sibẹ mo sọ ara mi di ẹrú gbogbo eniyan kí n lè mú ọpọlọpọ wọn wá sọ́dọ̀ Jesu. 20Nígbà tí mo bá wà láàrin àwọn Juu, èmi a máa di Juu kí n lè jèrè wọn. Nígbà tí mo bá wà láàrin àwọn tí ó gba ètò ti Òfin Mose, èmi a máa fi ara mi sábẹ́ Òfin Mose, kí n lè jèrè àwọn tí ó gba ètò ti Òfin, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò gba ètò ti Òfin Mose fúnra mi. 21Nígbà tí mo bá wà láàrin àwọn tí kò gba ètò ti Òfin Mose, èmi a máa fi ara mi sí ipò wọn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ka òfin Ọlọrun sí, pàápàá jùlọ òfin Kristi. Èmi a máa ṣe bẹ́ẹ̀ kí n lè jèrè àwọn tí kò gba ètò ti Òfin Mose. 22Nígbà tí mo bá wà láàrin àwọn aláìlera, èmi a di aláìlera, kí n lè jèrè àwọn aláìlera. Èmi a máa sọ ara mi di gbogbo nǹkan fún gbogbo eniyan, kí n lè gba àwọn kan ninu wọn là lọ́nà kan tabi lọ́nà mìíràn.
23Èmi a máa ṣe gbogbo nǹkan wọnyi nítorí ti ìyìn rere, kí n lè ní ìpín ninu ibukun rẹ̀. 24Ṣebí ẹ mọ̀ pé gbogbo àwọn tí ń sáré ìje ni ó ń sáré, ṣugbọn ẹnìkan ṣoṣo níí gba ẹ̀bùn. Ẹ sáré ní ọ̀nà tí ẹ óo fi rí ẹ̀bùn gbà. 25Nítorí gbogbo àwọn tí ń sáré ìje a máa kó ara wọn ní ìjánu. Wọ́n ń ṣe èyí kí wọ́n lè gba adé tí yóo bàjẹ́. Ṣugbọn adé tí kò lè bàjẹ́ ni tiwa.#Ọgb 4:2; 5:16 26Nítorí náà, aré tí èmi ń sá kì í ṣe ìsákúsàá láìní ète. Èmi kì í máa kan ẹ̀ṣẹ́ tèmi ní ìkànkukàn, bí ẹni tí ń kan afẹ́fẹ́ lásán lẹ́ṣẹ̀ẹ́. 27Ṣugbọn mò ń fi ìyà jẹ ara mi, mò ń kó ara mi ní ìjánu. Ìdí ni pé nígbà tí mo bá ti waasu fún àwọn ẹlòmíràn tán, kí èmi alára má baà di ẹni tí kò ní yege ninu iré-ìje náà.
Currently Selected:
KỌRINTI KINNI 9: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010