KỌRINTI KINNI 10
10
Ìkìlọ̀ Nípa Ìbọ̀rìṣà
1Ẹ̀yin ará, ẹ má gbàgbé pé gbogbo àwọn baba wa ni wọ́n wà lábẹ́ ìkùukùu. Gbogbo wọn ni wọ́n la òkun kọjá.#a Eks 13:21-22; b Eks 14:22-29 2Gbogbo wọn ni wọ́n ṣe ìrìbọmi ninu ìkùukùu ati ninu òkun, kí wọ́n lè di ọmọ ẹ̀yìn Mose. 3Gbogbo wọn ni wọ́n jẹ oúnjẹ ẹ̀mí kan náà.#Eks 16:35 4Gbogbo wọn ni wọ́n mu omi ẹ̀mí kan náà, nítorí wọ́n mu omi tí ó jáde láti inú òkúta ẹ̀mí tí ó ń tẹ̀lé wọn. Òkúta náà ni Kristi.#Eks 17:6; Nọm 20:11 5Ṣugbọn sibẹ inú Ọlọrun kò dùn sí ọpọlọpọ ninu wọn, nítorí ọpọlọpọ wọn ni wọ́n kú dànù káàkiri ninu aṣálẹ̀.#Nọm 14:29-30
6Àwọn nǹkan wọnyi jẹ́ àpẹẹrẹ fún wa, pé kí á má ṣe kó nǹkan burúkú lé ọkàn, gẹ́gẹ́ bí àwọn ti kó o lé ọkàn.#Nọm 11:4 7Kí ẹ má sì di abọ̀rìṣà bí àwọn mìíràn ninu wọn. Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Àwọn eniyan náà jókòó láti jẹ ati láti mu, wọ́n sì dìde láti ṣe àríyá.”#Eks 32:6 8Bẹ́ẹ̀ ni a kò gbọdọ̀ ṣe àgbèrè bí àwọn mìíràn ninu wọn ti ṣe àgbèrè, tí ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbẹẹdogun (23,000) eniyan fi kú ní ọjọ́ kan.#Nọm 25:1-18 9Bẹ́ẹ̀ ni kí á má ṣe dán Oluwa wò, bí àwọn mìíràn ninu wọn ti dán an wò, tí ejò fi ṣán wọn pa.#Nọm 21:5-6 10Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe kùn bí àwọn mìíràn ninu wọn ṣe kùn, tí Apani sì pa wọ́n.#Nọm 16:41-49
11Gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wọn yìí jẹ́ àpẹẹrẹ fún wa. A kọ wọ́n sílẹ̀ kí ó lè jẹ́ ìkìlọ̀ fún wa, àwa tí a wà ní ìgbà ìkẹyìn.
12Nítorí náà, ẹni tí ó bá rò pé òun dúró kí ó ṣọ́ra kí ó má baà ṣubú. 13Kò sí ìdánwò kan tí ó dé ba yín bíkòṣe irú èyí tí ó wọ́pọ̀ láàrin eniyan. Ṣugbọn Ọlọrun tó gbẹ́kẹ̀lé, kò ní jẹ́ kí ẹ rí ìdánwò tí ó ju èyí tí ẹ lè fara dà lọ. Ṣugbọn ní àkókò ìdánwò, yóo pèsè ọ̀nà àbáyọ, yóo sì mú kí ẹ lè fara dà á.#Judt 8:25-27; Sir 15:11-20
14Nítorí náà, ẹ̀yin àyànfẹ́ mi, ẹ sá fún ìbọ̀rìṣà. 15Mò ń ba yín sọ̀rọ̀ bí ọlọ́gbọ́n. Ẹ̀yin fúnra yín náà, ẹ gba ohun tí mò ń sọ rò. 16Ife ibukun tí à ń dúpẹ́ fún, ṣebí àjọpín ninu ẹ̀jẹ̀ Kristi ni. Burẹdi tí a bù, ṣebí àjọpín ninu ara Kristi ni.#Mat 26:26-28; Mak 14:22-24; Luk 22:19-20 17Nítorí burẹdi kan ni ó wà, ninu ara kan yìí ni gbogbo wa sì wà, nítorí ninu burẹdi kan ni gbogbo wa ti ń jẹ.
18Ẹ ṣe akiyesi ìṣe àwọn ọmọ Israẹli. Ṣebí àwọn tí ń jẹ ẹbọ ń jẹ ninu anfaani lílo pẹpẹ ìrúbọ fún ìsìn Ọlọrun?#Lef 7:6 19Nítorí náà, ṣé ohun tí mò ń sọ ni pé ohun tí a fi rúbọ fún oriṣa jẹ́ nǹkan? Tabi pé oriṣa jẹ́ nǹkan? 20Rárá o! Ohun tí mò ń sọ ni pé àwọn nǹkan tí àwọn abọ̀rìṣà fi ń rúbọ, ẹ̀mí burúkú ni wọ́n fi ń rúbọ sí, kì í ṣe Ọlọrun. N kò fẹ́ kí ẹ ní ìdàpọ̀ pẹlu àwọn ẹ̀mí burúkú.#Diut 32:17 21Ẹ kò lè mu ninu ife Oluwa tán kí ẹ tún lọ mu ninu ife ti ẹ̀mí burúkú. Ẹ kò lè jẹ ninu oúnjẹ orí tabili Oluwa, kí ẹ tún lọ jẹ ninu oúnjẹ orí tabili ẹ̀mí burúkú. 22Àbí a fẹ́ mú Oluwa jowú ni bí? Àbí a lágbára jù ú lọ ni?#Diut 32:21
Ẹ Ṣe Ohun Gbogbo fún Ògo Ọlọrun
23Lóòótọ́, “Ohun tí a bá fẹ́ ni a lè ṣe,” bí àwọn kan ti ń wí. Ṣugbọn kì í ṣe gbogbo nǹkan ni ó ń ṣe eniyan ní anfaani. “Ohun tí a bá fẹ́ ni a lè ṣe.” Ṣugbọn kì í ṣe gbogbo nǹkan tí a lè ṣe ni ó ń mú ìdàgbà wá.#1 Kọr 6:12 24Kí ẹnikẹ́ni má ṣe máa wá ire ti ara rẹ̀ bíkòṣe ire ẹnìkejì rẹ̀.
25Kí ẹ jẹ ohunkohun tí ẹ bá rà ní ọjà láì wádìí ohunkohun kí ẹ̀rí-ọkàn yín lè mọ́; 26“Nítorí Oluwa ni ó ni ayé ati gbogbo nǹkan tí ó wà ninu rẹ̀.”#O. Daf 24:1
27Bí ẹnìkan ninu àwọn alaigbagbọ bá pè yín wá jẹun, tí ẹ bá gbà láti lọ, ẹ jẹ ohunkohun tí ó bá gbé kalẹ̀ níwájú yín láì wádìí ohunkohun, kí ẹ̀rí-ọkàn yín lè mọ́. 28Ṣugbọn bí ẹnìkan bá sọ fun yín pé, “A ti fi oúnjẹ yìí ṣe ìrúbọ,” ẹ má jẹ ẹ́, nítorí ẹni tí ó sọ bẹ́ẹ̀ ati nítorí ẹ̀rí-ọkàn. 29Kì í ṣe ẹ̀rí-ọkàn tiyín ni mò ń sọ bíkòṣe ẹ̀rí-ọkàn ti ẹni tí ó pe akiyesi yín sí oúnjẹ náà.
Kí ló dé tí yóo fi jẹ́ pé ẹ̀rí-ọkàn ẹlòmíràn ni yóo máa sọ bí n óo ti ṣe lo òmìníra mi? 30Bí mo bá jẹ oúnjẹ pẹlu ọpẹ́ sí Ọlọrun, ẹ̀tọ́ wo ni ẹnìkan níláti bá mi wí fún ohun tí mo ti dúpẹ́ fún?
31Nítorí náà, ìbáà jẹ́ pé ẹ̀ ń jẹ ni, tabi pé ẹ̀ ń mu ni, ohunkohun tí ẹ bá ń ṣe, ẹ máa ṣe é fún ògo Ọlọrun. 32Ẹ má ṣe jẹ́ ohun ìkọsẹ̀ fún àwọn Juu tabi fún àwọn tí kì í ṣe Juu tabi fún ìjọ Ọlọrun. 33Ní tèmi, mò ń gbìyànjú láti ṣe ohun tí ó wu gbogbo eniyan ní gbogbo ọ̀nà. Kì í ṣe ohun tí ó jẹ́ anfaani tèmi ni mò ń wá, bíkòṣe ohun tí ó jẹ́ anfaani ọpọlọpọ eniyan, kí á lè gbà wọ́n là.
Currently Selected:
KỌRINTI KINNI 10: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010