1
AISAYA 54:17
Yoruba Bible
Kò sí ohun ìjà tí a ṣe láti fi bá ọ jà tí yóo lágbára lórí rẹ. Gbogbo ẹni tí ó bá bá ọ rojọ́ nílé ẹjọ́, ni o óo jàre wọn. Èyí ni ìpín àwọn iranṣẹ OLUWA, ati ìdáláre wọn lọ́dọ̀ mi. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
Compare
Explore AISAYA 54:17
2
AISAYA 54:10
Bí àwọn òkè ńlá tilẹ̀ ṣí kúrò, tí a sì ṣí àwọn òkè kéékèèké nídìí, ṣugbọn ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀, kò ní yẹ̀ lára rẹ, majẹmu alaafia mi tí mo bá ọ dá kò ní yẹ̀. Èmi OLUWA tí mo ṣàánú fún ọ ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
Explore AISAYA 54:10
3
AISAYA 54:4
Má bẹ̀rù nítorí ojú kò ní tì ọ́, má sì dààmú, nítorí a kì yóo dójú tì ọ́, nítorí o óo gbàgbé ìtìjú ìgbà èwe rẹ, o kò sì ní ranti ẹ̀sín ìgbà tí o jẹ́ opó mọ́.
Explore AISAYA 54:4
4
AISAYA 54:5
Nítorí Ẹlẹ́dàá rẹ ni ọkọ rẹ, OLUWA àwọn ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀. Ẹni Mímọ́ Israẹli ni Olùràpadà rẹ, Ọlọrun gbogbo ayé ni à ń pè é.
Explore AISAYA 54:5
5
AISAYA 54:2
Fẹ ààyè àgọ́ rẹ sẹ́yìn, sì jẹ́ kí aṣọ tí ó ta sórí ibùgbé rẹ gbòòrò sí i, má ṣẹ́wọ́ kù. Na okùn àgọ́ rẹ kí ó gùn, kí o sì kan èèkàn rẹ̀ mọ́lẹ̀ kí ó lágbára.
Explore AISAYA 54:2
6
AISAYA 54:13
“Gbogbo àwọn ọmọ rẹ ọkunrin, ni OLUWA yóo kọ́ wọn yóo sì ṣe ọpọlọpọ àṣeyọrí.
Explore AISAYA 54:13
7
AISAYA 54:8
Mo fojú mi pamọ́ fún ọ, fún ìgbà díẹ̀ nítorí inú mi ń ru sí ọ, ṣugbọn nítorí ìfẹ́ àìlópin mi, n óo ṣàánú fún ọ. Èmi OLUWA, Olùràpadà rẹ ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
Explore AISAYA 54:8
8
AISAYA 54:7
Mo kọ̀ ọ́ sílẹ̀ fún ìgbà díẹ̀, ṣugbọn n óo kó ọ jọ pẹlu ọpọlọpọ àánú.
Explore AISAYA 54:7
9
AISAYA 54:9
Bí ìgbà ayé Noa ni Ọ̀rọ̀ yìí rí sí mi: mo búra nígbà náà, pé omi Noa kò ní bo ayé mọ́lẹ̀ mọ́. Bẹ́ẹ̀ náà ni mo búra nisinsinyii, pé n kò ní bínú sí ọ mọ́, pé n kò ní bá ọ wí mọ́.
Explore AISAYA 54:9
10
AISAYA 54:12
Òkúta Agate ni n óo fi ṣe ṣóńṣó ilé rẹ, òkúta dídán ni n óo fi ṣe ẹnu ọ̀nà ibodè rẹ, àwọn òkúta olówó iyebíye ni n óo fi mọ odi rẹ.
Explore AISAYA 54:12
Home
Bible
Plans
Videos