“Bí òjò ati yìnyín, tí ń rọ̀ láti ojú ọ̀run,
tí wọn kì í pada sibẹ mọ́,
ṣugbọn tí wọn ń bomi rin ilẹ̀,
tí ń mú kí nǹkan hù jáde;
kí àgbẹ̀ lè rí èso gbìn,
kí eniyan sì rí oúnjẹ jẹ.
Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ tó ń jáde lẹ́nu mi yóo rí,
kò ní pada sí ọ̀dọ̀ mi lọ́wọ́ òfo,
ṣugbọn yóo ṣe ohun tí mo fẹ́ kí ó ṣe,
yóo sì ṣe é ní àṣeyọrí.