1
MATIU 27:46
Yoruba Bible
Nígbà tí ó tó nǹkan bí agogo mẹta ọ̀sán, Jesu kígbe ní ohùn rara pé, “Eli, Eli, lema sabakitani?” Ìtumọ̀ èyí ni, “Ọlọrun mi! Ọlọrun mi! Kí ló dé tí o fi kọ̀ mí sílẹ̀?”
Compare
Explore MATIU 27:46
2
MATIU 27:51-52
Aṣọ ìkélé tí ó wà ninu Tẹmpili ya sí meji láti òkè dé ilẹ̀. Ilẹ̀ mì tìtì. Àwọn òkè sán. Òkúta ẹnu ibojì ṣí, a sì jí ọ̀pọ̀ òkú àwọn olódodo dìde.
Explore MATIU 27:51-52
3
MATIU 27:50
Jesu bá tún kígbe tòò, ó mí kanlẹ̀, ó bá dákẹ́.
Explore MATIU 27:50
4
MATIU 27:54
Nígbà tí ọ̀gágun ati àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀ tí wọn ń ṣọ́ Jesu rí ilẹ̀ tí ó mì ati gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ẹ̀rù bà wọ́n pupọ. Wọ́n ní, “Nítòótọ́ Ọmọ Ọlọrun ni ọkunrin yìí.”
Explore MATIU 27:54
5
MATIU 27:45
Láti agogo mejila ọ̀sán ni òkùnkùn ti bo gbogbo ilẹ̀ títí di agogo mẹta ọ̀sán.
Explore MATIU 27:45
6
MATIU 27:22-23
Pilatu wá bi wọ́n pé, “Kí ni ẹ fẹ́ kí n ṣe sí Jesu tí ó ń jẹ́ Mesaya?” Gbogbo wọn dáhùn pé, “Kàn án mọ́ agbelebu.” Pilatu bi wọ́n pé, “Ohun burúkú wo ni ó ṣe?” Ṣugbọn wọ́n túbọ̀ kígbe pé, “Kàn án mọ́ agbelebu.”
Explore MATIU 27:22-23
Home
Bible
Plans
Videos