1
ORIN DAFIDI 84:11
Yoruba Bible
Nítorí OLUWA Ọlọrun ni oòrùn ati ààbò wa, òun níí ṣeni lóore, tíí dáni lọ́lá, nítorí OLUWA kò ní rowọ́ láti fún ẹni tí ọkàn rẹ̀ mọ́ ní ohun tí ó dára.
Compare
Explore ORIN DAFIDI 84:11
2
ORIN DAFIDI 84:10
Nítorí pé ọjọ́ kan péré ninu àgbàlá rẹ, ṣe anfaani ju ẹgbẹrun ọjọ́ níbòmíràn lọ. Ó wù mí kí n jẹ́ aṣọ́nà ninu ilé Ọlọrun mi ju pé kí n máa gbé inú àgọ́ àwọn eniyan burúkú.
Explore ORIN DAFIDI 84:10
3
ORIN DAFIDI 84:5
Ayọ̀ ń bẹ fún gbogbo àwọn tí ó fi ọ́ ṣe agbára wọn, tí ìrìn àjò sí Sioni jẹ wọ́n lógún.
Explore ORIN DAFIDI 84:5
4
ORIN DAFIDI 84:2
ọkàn àgbàlá tẹmpili OLUWA ń fà mí, àárò rẹ̀ ń sọ mí; tọkàn-tara ni mo fi ń kọrin ayọ̀ sí Ọlọrun alààyè.
Explore ORIN DAFIDI 84:2
Home
Bible
Plans
Videos