ORIN DAFIDI 84
84
Ṣíṣàárò Ilé Ọlọrun
1Ibùgbé rẹ lẹ́wà pupọ, OLUWA àwọn ọmọ ogun,
2ọkàn àgbàlá tẹmpili OLUWA ń fà mí,
àárò rẹ̀ ń sọ mí;
tọkàn-tara ni mo fi ń kọrin ayọ̀
sí Ọlọrun alààyè.
3Àwọn ẹyẹ ológoṣẹ́ pàápàá a máa kọ́ ilé,
àwọn alápàáǹdẹ̀dẹ̀ a sì máa tẹ́ ìtẹ́
níbi tí wọ́n ń pa ọmọ sí, lẹ́bàá pẹpẹ rẹ,
àní lẹ́bàá pẹpẹ rẹ, OLUWA àwọn ọmọ ogun,
ọba mi, ati Ọlọrun mi.
4Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ń gbé inú ilé rẹ,
wọn óo máa kọ orin ìyìn sí ọ títí lae!
5Ayọ̀ ń bẹ fún gbogbo àwọn tí ó fi ọ́ ṣe agbára wọn,
tí ìrìn àjò sí Sioni jẹ wọ́n lógún.
6Bí wọ́n ti ń la àfonífojì Baka lọ,
wọ́n ń sọ ọ́ di orísun omi;
àkọ́rọ̀ òjò sì mú kí adágún omi kún ibẹ̀.
7Wọn ó máa ní agbára kún agbára,
títí wọn ó fi farahàn níwájú Ọlọrun ní Sioni.
8OLUWA, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, gbọ́ adura mi;
tẹ́tí sílẹ̀, Ọlọrun Jakọbu!
9Bojú wo àpáta wa, Ọlọrun,
fi ojú àánú wo ẹni àmì òróró rẹ.
10Nítorí pé ọjọ́ kan péré ninu àgbàlá rẹ,
ṣe anfaani ju ẹgbẹrun ọjọ́ níbòmíràn lọ.
Ó wù mí kí n jẹ́ aṣọ́nà ninu ilé Ọlọrun mi
ju pé kí n máa gbé inú àgọ́ àwọn eniyan burúkú.
11Nítorí OLUWA Ọlọrun ni oòrùn ati ààbò wa,
òun níí ṣeni lóore, tíí dáni lọ́lá,
nítorí OLUWA kò ní rowọ́ láti fún ẹni tí ọkàn rẹ̀ mọ́
ní ohun tí ó dára.
12OLUWA àwọn ọmọ ogun,
ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé ọ.
Currently Selected:
ORIN DAFIDI 84: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010