YouVersion Logo
Search Icon

ORIN DAFIDI 83

83
Adura Ìṣẹ́gun
1Ọlọrun, má dákẹ́;
má wòran; Ọlọrun má dúró jẹ́ẹ́!
2Wò ó! Àwọn ọ̀tá rẹ ń ṣọ̀tẹ̀ sí ọ;
àwọn tí ó kórìíra rẹ sì ń yájú sí ọ.
3Wọ́n pète àrékérekè sí àwọn eniyan rẹ;
wọ́n sì gbìmọ̀ pọ̀ sí àwọn tí ó sá di ọ́.
4Wọ́n ní, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á pa orílẹ̀-èdè wọn run;
kí á má ranti orúkọ Israẹli mọ́!”
5Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n jùmọ̀ pète pèrò;
wọ́n dá majẹmu láti dojú kọ ọ́.
6Àwọn ará Edomu, ati àwọn ọmọ Iṣimaeli,
àwọn ará Moabu, ati àwọn ọmọ Hagiri,
7àwọn ará Gebali, àwọn ọmọ Amoni, ati àwọn ọmọ Amaleki,
àwọn ará Filistia ati àwọn tí ń gbé Tire.
8Àwọn ará Asiria pàápàá ti dara pọ̀ mọ́ wọn;
àwọn ni alátìlẹ́yìn àwọn ọmọ Lọti.
9Ṣe wọ́n bí o ti ṣe àwọn ará Midiani,
bí o ti ṣe Sisera ati Jabini ni odò Kiṣoni,
10àwọn tí o parun ní Endori,
tí wọ́n di ààtàn lórí ilẹ̀.
11Ṣe àwọn ọlọ́lá wọn bí o ti ṣe Orebu ati Seebu;
ṣe àwọn ìjòyè wọn bí o ti ṣe Seba ati Salumuna,
12àwọn tí ó wí pé,
“Ẹ jẹ́ kí á mú lára ilẹ̀ Ọlọrun
kí á sọ ọ́ di tiwa.”#(a) A. Ada 7:1-23 (b) A. Ada 4:6-22 #(a) A. Ada 7:25 (b) A. Ada 8:12
13Ọlọrun mi, ṣe wọ́n bí ààjà tíí ṣe ewé,
àní, bí afẹ́fẹ́ tíí ṣe fùlùfúlù.
14Bí iná tíí jó igbó,
àní, bí ọwọ́ iná sì ṣe ń jó òkè kanlẹ̀,
15bẹ́ẹ̀ ni kí o fi ìjì rẹ lé wọn,
kí o sì fi ààjà rẹ dẹ́rù bà wọ́n.
16Da ìtìjú bò wọ́n,
kí wọn lè máa wá ọ kiri, OLUWA.
17Jẹ́ kí ojú tì wọ́n, kí ìdààmú dé bá wọn títí lae,
kí wọn sì ṣègbé ninu ìtìjú.
18Jẹ́ kí wọn mọ̀ pé ìwọ nìkan,
tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ OLUWA,
ni Ọ̀gá Ògo lórí gbogbo ayé.

Currently Selected:

ORIN DAFIDI 83: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

Video for ORIN DAFIDI 83