Nitorina mo fẹ ki awọn ọkunrin mã gbadura nibi gbogbo, ki nwọn mã gbé ọwọ́ mimọ́ soke, li aibinu ati li aijiyan.
Bẹ̃ gẹgẹ ki awọn obinrin ki o fi aṣọ iwọntunwọnsin ṣe ara wọn li ọṣọ́, pẹlu itiju ati ìwa airekọja; kì iṣe pẹlu irun didì ati wura, tabi pearli, tabi aṣọ olowo iyebiye,
Bikoṣe pẹlu iṣẹ́ rere (eyi ti o yẹ fun awọn obinrin ti o jẹwọ ìwa-bi-Ọlọrun).