I. Tim 2
2
Ẹ̀kọ́ nípa Adura
1NITORINA mo gbà nyin niyanju ṣaju ohun gbogbo, pe ki a mã bẹ̀bẹ, ki a mã gbadura, ki a mã ṣìpẹ, ati ki a mã dupẹ nitori gbogbo enia;
2Fun awọn ọba, ati gbogbo awọn ti o wà ni ipo giga; ki a le mã lo aiye wa ni idakẹjẹ ati pẹlẹ ninu gbogbo ìwa-bi-Ọlọrun ati ìwa agbà.
3Nitori eyi dara o si ṣe itẹwọgbà niwaju Ọlọrun Olugbala wa;
4Ẹniti o nfẹ ki gbogbo enia ni igbala ki nwọn si wá sinu ìmọ otitọ.
5Nitori Ọlọrun kan ni mbẹ, Onilaja kan pẹlu larin Ọlọrun ati enia, on papa enia, ani Kristi Jesu;
6Ẹniti o fi ara rẹ̀ ṣe irapada fun gbogbo enia, ẹrí li akokò rẹ̀;
7Nitori eyiti a yàn mi ṣe oniwasu, ati aposteli, (otitọ li emi nsọ, emi kò ṣeke;) olukọ awọn Keferi ni igbagbọ́ ati otitọ.
8Nitorina mo fẹ ki awọn ọkunrin mã gbadura nibi gbogbo, ki nwọn mã gbé ọwọ́ mimọ́ soke, li aibinu ati li aijiyan.
9Bẹ̃ gẹgẹ ki awọn obinrin ki o fi aṣọ iwọntunwọnsin ṣe ara wọn li ọṣọ́, pẹlu itiju ati ìwa airekọja; kì iṣe pẹlu irun didì ati wura, tabi pearli, tabi aṣọ olowo iyebiye,
10Bikoṣe pẹlu iṣẹ́ rere (eyi ti o yẹ fun awọn obinrin ti o jẹwọ ìwa-bi-Ọlọrun).
11Jẹ ki obinrin ki o mã fi idakẹjẹ ati itẹriba gbogbo kọ́ ẹkọ́.
12Ṣugbọn emi kò fi aṣẹ fun obinrin lati mã kọ́ni, tabi lati paṣẹ lori ọkunrin, bikoṣepe ki o dakẹjẹ.
13Nitori Adamu li a kọ́ dá, lẹhin na, Efa.
14A kò si tàn Adamu jẹ, ṣugbọn obinrin na, nigbati a tàn a, o ṣubu sinu ẹ̀ṣẹ.
15Ṣugbọn a o gbà a là nipa ìbimọ rẹ̀, bi nwọn ba duro ninu igbagbọ́ ati ifẹ, ati ìwa mimọ́ pẹlu ìwa airekọja.
Currently Selected:
I. Tim 2: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.