1
Isa 30:21
Bibeli Mimọ
Eti rẹ o si gbọ́ ọ̀rọ kan lẹhin rẹ, wipe, Eyiyi li ọ̀na, ẹ ma rin ninu rẹ̀, nigbati ẹnyin bá yi si apa ọtún, tabi nigbati ẹnyin bá yi si apa òsi.
Compare
Explore Isa 30:21
2
Isa 30:18
Nitorina ni Oluwa yio duro, ki o le ṣe ore fun nyin, ati nitori eyi li o ṣe ga, ki o le ṣe iyọ́nu si nyin: nitori Oluwa li Ọlọrun idajọ: ibukun ni fun gbogbo awọn ti o duro dè e.
Explore Isa 30:18
3
Isa 30:15
Nitori bayi ni Oluwa Jehofah, Ẹni-Mimọ Israeli wi; Ninu pipada on sisimi li a o fi gbà nyin là; ninu didakẹjẹ ati gbigbẹkẹle li agbara nyin wà; ṣugbọn ẹnyin kò fẹ.
Explore Isa 30:15
4
Isa 30:20
Oluwa yio si fi onjẹ ipọnju, ati omi inira fun nyin, awọn olukọ́ni rẹ kì yio sápamọ́ mọ, ṣugbọn oju rẹ yio ri olukọ́ni rẹ̀
Explore Isa 30:20
5
Isa 30:19
Nitori awọn enia Sioni yio gbe Jerusalemu, iwọ kì yio sọkun mọ: yio ṣanu fun ọ gidigidi nigbati iwọ ba nkigbe; nigbati on ba gbọ́ ọ, yio dá ọ lohùn.
Explore Isa 30:19
6
Isa 30:1
OLUWA wipe, egbé ni fun awọn ọlọ̀tẹ ọmọ, ti nwọn gbà ìmọ, ṣugbọn kì iṣe ati ọdọ mi; ti nwọn si mulẹ, ṣugbọn kì iṣe nipa ẹmi mi, ki nwọn ba le fi ẹ̀ṣẹ kún ẹ̀ṣẹ
Explore Isa 30:1
Home
Bible
Plans
Videos