Isa 30
30
Àdéhùn tí kò Wúlò pẹlu Egipti
1OLUWA wipe, egbé ni fun awọn ọlọ̀tẹ ọmọ, ti nwọn gbà ìmọ, ṣugbọn kì iṣe ati ọdọ mi; ti nwọn si mulẹ, ṣugbọn kì iṣe nipa ẹmi mi, ki nwọn ba le fi ẹ̀ṣẹ kún ẹ̀ṣẹ:
2Ti nwọn nrìn lọ si Egipti, ṣugbọn ti nwọn kò bere li ẹnu mi; lati mu ara wọn le nipa agbara Farao, ati lati gbẹkẹle ojiji Egipti!
3Nitorina ni agbara Farao yio ṣe jẹ itiju nyin, ati igbẹkẹle ojiji Egipti yio jẹ idãmu nyin.
4Nitori awọn olori rẹ̀ wá ni Soani, awọn ikọ̀ rẹ̀ de Hanesi.
5Oju awọn enia kan ti kò li ère fun wọn tilẹ tì wọn, ti kò le ṣe iranwọ, tabi anfani, bikoṣe itiju ati ẹ̀gan pẹlu.
Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Àwọn ẹranko Ilẹ̀ Nẹgẹbu
6Ọ̀rọ-ìmọ niti awọn ẹranko gusu: sinu ilẹ wahala on àrodun, nibiti akọ ati abo kiniun ti wá, pamọlẹ ati ejò-ina ti nfò, nwọn o rù ọrọ̀ wọn li ejika awọn ọmọ kẹtẹkẹtẹ, ati iṣura wọn lori iké awọn ràkumi, sọdọ awọn enia kan ti kò li ère.
7Egipti yio ṣe iranwọ lasan, kò si ni lari: nitorina ni mo ṣe kigbe pè e ni, Rahabu ti o joko jẹ.
Àwọn Aláìgbọràn
8Nisisiyi lọ, kọ ọ niwaju wọn si walã kan, si kọ ọ sinu iwe kan, ki o le jẹ fun igbà ti mbọ lai ati lailai:
9Pe, ọlọ̀tẹ enia ni awọn wọnyi, awọn ọmọ eké, awọn ọmọ ti kò fẹ igbọ́ ofin Oluwa:
10Ti nwọn wi fun awọn ariran pe, Máṣe riran; ati fun awọn wolĩ pe, Má sọtẹlẹ ohun ti o tọ́ fun wa, sọ nkan didùn fun wa, sọ asọtẹlẹ̀ itanjẹ.
11Kuro li ọna na, yẹ̀ kuro ni ipa na, mu ki Ẹni-Mimọ Israeli ki o dẹkun kuro niwaju wa.
12Nitorina bayi li Ẹni-Mimọ Israeli wi, Nitoriti ẹnyin gàn ọ̀rọ yi, ti ẹnyin si gbẹkẹle ininilara on ìyapa, ti ẹnyin si gbe ara nyin lé e;
13Nitorina ni aiṣedede yi yio ri si nyin bi odi yiya ti o mura ati ṣubu, ti o tiri sode lara ogiri giga, eyiti wiwó rẹ̀ de lojijì, lojukanna.
14Yio si fọ́ ọ bi fifọ́ ohun-èlo amọ̀ ti a fọ́ tútu; ti a kò dasi: tobẹ̃ ti a kì yio ri apãdi kan ninu ẹfọ́ rẹ̀ lati fi fọ̀n iná li oju ãro, tabi lati fi bù omi ninu ikũdu.
15Nitori bayi ni Oluwa Jehofah, Ẹni-Mimọ Israeli wi; Ninu pipada on sisimi li a o fi gbà nyin là; ninu didakẹjẹ ati gbigbẹkẹle li agbara nyin wà; ṣugbọn ẹnyin kò fẹ.
16Ṣugbọn ẹnyin wipe, Bẹ̃kọ; nitori ẹṣin li a o fi sá; nitorina li ẹnyin o ṣe sá: ati pe, Awa o gùn eyi ti o lè sare; nitorina awọn ti yio lepa nyin yio lè sare.
17Ẹgbẹrun yio sá ni ibawi ẹnikan; ni ibawi ẹni marun li ẹnyin o sá: titi ẹnyin o fi kù bi àmi lori oke-nla, ati bi asia lori oke.
18Nitorina ni Oluwa yio duro, ki o le ṣe ore fun nyin, ati nitori eyi li o ṣe ga, ki o le ṣe iyọ́nu si nyin: nitori Oluwa li Ọlọrun idajọ: ibukun ni fun gbogbo awọn ti o duro dè e.
Ọlọrun Yóo Bukun Àwọn Eniyan Rẹ̀
19Nitori awọn enia Sioni yio gbe Jerusalemu, iwọ kì yio sọkun mọ: yio ṣanu fun ọ gidigidi nigbati iwọ ba nkigbe; nigbati on ba gbọ́ ọ, yio dá ọ lohùn.
20Oluwa yio si fi onjẹ ipọnju, ati omi inira fun nyin, awọn olukọ́ni rẹ kì yio sápamọ́ mọ, ṣugbọn oju rẹ yio ri olukọ́ni rẹ̀:
21Eti rẹ o si gbọ́ ọ̀rọ kan lẹhin rẹ, wipe, Eyiyi li ọ̀na, ẹ ma rin ninu rẹ̀, nigbati ẹnyin bá yi si apa ọtún, tabi nigbati ẹnyin bá yi si apa òsi.
22Ẹnyin o si sọ ibora ere fadaka nyin wọnni di aimọ́, ati ọṣọ́ ere wura didà nyin wọnni: iwọ o sọ wọn nù bi ohun-aimọ́, iwọ o si wi fun u pe, Kuro nihinyi.
23On o si rọ̀ òjo si irugbin rẹ ti iwọ ti fọ́n si ilẹ: ati onjẹ ibísi ilẹ, yio li ọrá yio si pọ̀: li ọjọ na ni awọn ẹran rẹ yio ma jẹ̀ ni pápa oko nla.
24Awọn akọ-malu pẹlu, ati awọn ọmọ kẹtẹkẹtẹ ti ntulẹ yio jẹ oko didùn, ti a ti fi kọ̀nkọsọ ati atẹ fẹ.
25Ati lori gbogbo oke-nla giga, ati lori gbogbo oke kékèké ti o ga, ni odò ati ipa-omi yio wà li ọjọ pipa nla, nigbati ile-iṣọ́ wọnni bá wó.
26Imọ́lẹ oṣupa yio si dabi imọ́lẹ õrun, imọ́lẹ õrun yio si ràn ni iwọ̀n igbà meje, bi imọ́lẹ ọjọ meje, li ọjọ ti Oluwa dí yiya awọn enia rẹ̀, ti o si ṣe àwotán ọgbẹ ti a ṣá wọn.
Ọlọrun Yóo Jẹ Asiria níyà
27Kiyesi i, orukọ Ọluwa mbọ̀ lati ọ̀na jijin wá, ibinu rẹ̀ si njo, ẹrù rẹ̀ si wuwo: ète rẹ̀ si kún fun ikannu, ati ahọn rẹ̀ bi ajonirun iná:
28Ẽmi rẹ̀ bi kikun omi, yio si de ãrin-meji ọrùn, lati fi kọ̀nkọsọ kù awọn orilẹ-ède: ijanu yio si wà li ẹ̀rẹkẹ́ awọn enia, lati mu wọn ṣina.
29Ẹnyin o li orin kan, gẹgẹ bi igbati a nṣe ajọ li oru; ati didùn inu, bi igbati ẹnikan fun fère lọ, lati wá si òke-nla Oluwa, sọdọ Apata Israeli.
30Oluwa yio si mu ki a gbọ́ ohùn ogo rẹ̀, yio si fi isọkalẹ apá rẹ̀ hàn pẹlu ikannu ibinu rẹ̀, ati pẹlu ọwọ́ ajonirun iná, pẹlu ifúnka, ati ijì, ati yinyín.
31Nitori nipa ohùn Oluwa li a o fi lù awọn ara Assiria bo ilẹ, ti o fi kùmọ lù.
32Ati nibi gbogbo ti paṣán ti a yàn ba kọja si, ti Oluwa yio fi lé e, yio ṣe pẹlu tabreti ati dùru: yio si fi irọ́kẹ̀kẹ ogun bá a jà.
33Nitori a ti yàn Tofeti lati igbà atijọ; nitõtọ, ọba li a ti pèse rẹ̀ fun; o ti ṣe e ki o jìn, ki o si gbòro: okiti rẹ̀ ni iná ati igi pupọ; emi Oluwa, bi iṣàn imí-ọjọ́ ntàn iná ràn a.
Currently Selected:
Isa 30: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.