1
Joh 19:30
Bibeli Mimọ
Nitorina nigbati Jesu si ti gbà ọti kikan na, o wipe, O pari: o si tẹ ori rẹ̀ ba, o jọwọ ẹmí rẹ̀ lọwọ.
Compare
Explore Joh 19:30
2
Joh 19:28
Lẹhin eyi, bi Jesu ti mọ̀ pe, a ti pari ohun gbogbo tan, ki iwe-mimọ́ le ba ṣẹ, o wipe, Orungbẹ ngbẹ mi.
Explore Joh 19:28
3
Joh 19:26-27
Nitorina nigbati Jesu ri iya rẹ̀, ati ọmọ-ẹhin na duro, ẹniti Jesu fẹràn, o wi fun iya rẹ̀ pe, Obinrin, wò ọmọ rẹ! Lẹhin na li o si wi fun ọmọ-ẹhin na pe, Wò iya rẹ! Lati wakati na lọ li ọmọ-ẹhin na si ti mu u lọ si ile ara rẹ̀.
Explore Joh 19:26-27
4
Joh 19:33-34
Ṣugbọn nigbati nwọn de ọdọ Jesu, ti nwọn si ri pe, o ti kú na, nwọn kò si ṣẹ́ egungun itan rẹ̀: Ṣugbọn ọkan ninu awọn ọmọ-ogun na fi ọ̀kọ gún u li ẹgbẹ, lojukanna ẹ̀jẹ ati omi si tú jade.
Explore Joh 19:33-34
5
Joh 19:36-37
Nkan wọnyi ṣe, ki iwe-mimọ́ ki o le ṣẹ, ti o wipe, A kì yio fọ́ egungun rẹ̀. Iwe-mimọ́ miran ẹ̀wẹ si wipe, Nwọn o ma wò ẹniti a gún li ọ̀kọ.
Explore Joh 19:36-37
6
Joh 19:17
Nitorina nwọn mu Jesu, o si jade lọ, o rù agbelebu fun ara rẹ̀ si ibi ti a npè ni Ibi-agbari, li ede Heberu ti a npè ni Golgota
Explore Joh 19:17
7
Joh 19:2
Awọn ọmọ-ogun si hun ade ẹgún, nwọn si fi de e li ori, nwọn si fi aṣọ igunwà elesè àluko wọ̀ ọ.
Explore Joh 19:2
Home
Bible
Plans
Videos