Joh 19
19
1NITORINA ni Pilatu mu Jesu, o si nà á.
2Awọn ọmọ-ogun si hun ade ẹgún, nwọn si fi de e li ori, nwọn si fi aṣọ igunwà elesè àluko wọ̀ ọ.
3Nwọn si wipe, Kabiyesi, Ọba awọn Ju! nwọn si fi ọwọ́ wọn gbá a loju.
4Pilatu si tún jade, o si wi fun wọn pe, Wo o, mo mu u jade tọ̀ nyin wá, ki ẹnyin ki o le mọ̀ pe, emi kò ri ẹ̀ṣẹ kan lọwọ rẹ̀.
5Nitorina Jesu jade wá, ti on ti ade ẹgún ati aṣọ elesè àluko. Pilatu si wi fun wọn pe, Ẹ wò ọkunrin na!
6Nitorina nigbati awọn olori alufa, ati awọn onṣẹ ri i, nwọn kigbe wipe, Kàn a mọ agbelebu, kàn a mọ agbelebu. Pilatu wi fun wọn pe, Ẹ mu u fun ara nyin, ki ẹ si kàn a mọ agbelebu: nitoriti emi ko ri ẹ̀ṣẹ lọwọ rẹ̀.
7Awọn Ju da a lohùn wipe, Awa li ofin kan, ati gẹgẹ bi ofin wa o yẹ lati kú, nitoriti o fi ara rẹ̀ ṣe Ọmọ Ọlọrun.
8Nitorina nigbati Pilatu gbọ́ ọ̀rọ yi ẹ̀ru tubọ ba a.
9O si tun wọ̀ inu gbọ̀ngan idajọ lọ, o si wi fun Jesu pe, Nibo ni iwọ ti wá? Ṣugbọn Jesu kò da a lohùn.
10Nitorina Pilatu wi fun u pe, Emi ni iwọ ko fọhun si? iwọ kò mọ̀ pe, emi li agbara lati dá ọ silẹ, emi si li agbara lati kàn ọ mọ agbelebu?
11Jesu da a lohun pe, Iwọ kì ba ti li agbara kan lori mi, bikoṣepe a fi i fun ọ lati oke wá: nitorina ẹniti o fi mi le ọ lọwọ li o ni ẹ̀ṣẹ pọ̀ju.
12Nitori eyi Pilatu nwá ọ̀na lati dá a silẹ: ṣugbọn awọn Ju kigbe, wipe, Bi iwọ ba dá ọkunrin yi silẹ, iwọ kì iṣe ọrẹ́ Kesari: ẹnikẹni ti o ba ṣe ara rẹ̀ li ọba, o sọ̀rọ òdi si Kesari.
13Nitorina nigbati Pilatu gbọ́ ọ̀rọ wọnyi, o mu Jesu jade wá, o si joko lori itẹ́ idajọ ti a npè ni Okuta-titẹ, ṣugbọn li ede Heberu, Gabbata.
14O jẹ Ipalẹmọ́ ajọ irekọja, o jẹ iwọn wakati ẹkẹfa: o si wi fun awọn Ju pe, Ẹ wò Ọba nyin!
15Nitorina nwọn kigbe wipe, Mu u kuro, mu u kuro, kàn a mọ agbelebu. Pilatu wi fun wọn pe, Emi o ha kàn Ọba nyin mọ agbelebu bi? Awọn olori alufa dahùn wipe,
16Awa kò li ọba bikoṣe Kesari. Nigbana li o fà a le wọn lọwọ lati kàn a mọ agbelebu.
Wọ́n Kan Jesu Mọ́ Agbelebu
(Mat 27:32-44; Mak 15:21-32; Luk 23:26-43)
Wọ́n bá gba Jesu lọ́wọ́ Pilatu.
17Nitorina nwọn mu Jesu, o si jade lọ, o rù agbelebu fun ara rẹ̀ si ibi ti a npè ni Ibi-agbari, li ede Heberu ti a npè ni Golgota:
18Nibiti nwọn gbé kàn a mọ agbelebu, ati awọn meji miran pẹlu rẹ̀, niha ikini ati nìha keji, Jesu si wà larin.
19Pilatu si kọ iwe akọle kan pẹlu, o si fi i le ori agbelebu na. Ohun ti a si kọ ni, JESU TI NASARETI ỌBA AWỌN JU.
20Nitorina ọpọ awọn Ju li o kà iwe akọle yi: nitori ibi ti a gbé kàn Jesu mọ agbelebu sunmọ eti ilu: a si kọ ọ li ède Heberu, ati ti Latini, ati ti Helene.
21Nitorina awọn olori alufa awọn Ju wi fun Pilatu pe, Máṣe kọ ọ pe, Ọba awọn Ju; ṣugbọn pe on wipe, Emi li Ọba awọn Ju.
22Pilatu dahùn pe, Ohun ti mo ti kọ tan, mo ti kọ na.
23Nigbana li awọn ọmọ-ogun, nigbati nwọn kàn Jesu mọ agbelebu tan, nwọn mu aṣọ rẹ̀, nwọn si pín wọn si ipa mẹrin, apakan fun ọmọ-ogun kọkan, ati àwọtẹlẹ rẹ̀: ṣugbọn àwọ̀tẹlẹ na kò li ojuran, nwọn hun u lati oke titi jalẹ.
24Nitorina nwọn wi fun ara wọn pe, Ẹ má jẹ ki a fà a ya, ṣugbọn ki a ṣẹ kèké nitori rẹ̀, ti ẹniti yio jẹ: ki iwe-mimọ́ ki o le ṣẹ, ti o wipe, Nwọn pín aṣọ mi larin ara wọn, nwọn si ṣẹ kèké fun aṣọ ileke mi. Nkan wọnyi li awọn ọmọ-ogun ṣe.
25Iya Jesu ati arabinrin iya rẹ̀ Maria aya Klopa, ati Maria Magdalene, si duro nibi agbelebu.
26Nitorina nigbati Jesu ri iya rẹ̀, ati ọmọ-ẹhin na duro, ẹniti Jesu fẹràn, o wi fun iya rẹ̀ pe, Obinrin, wò ọmọ rẹ!
27Lẹhin na li o si wi fun ọmọ-ẹhin na pe, Wò iya rẹ! Lati wakati na lọ li ọmọ-ẹhin na si ti mu u lọ si ile ara rẹ̀.
Ikú Jesu
(Mat 27:45-56; Mak 15:33-41; Luk 23:44-49)
28Lẹhin eyi, bi Jesu ti mọ̀ pe, a ti pari ohun gbogbo tan, ki iwe-mimọ́ le ba ṣẹ, o wipe, Orungbẹ ngbẹ mi.
29A gbé ohun èlo kan kalẹ nibẹ̀ ti o kún fun ọti kikan: nwọn si fi sponge ti o kun fun ọti kikan, sori igi hissopu, nwọn si fi si i li ẹnu.
30Nitorina nigbati Jesu si ti gbà ọti kikan na, o wipe, O pari: o si tẹ ori rẹ̀ ba, o jọwọ ẹmí rẹ̀ lọwọ.
Ọmọ-ogun Kan Fi Ọ̀kọ̀ Gún Jesu Lẹ́gbẹ̀ẹ́
31Nitori o jẹ ọjọ Ipalẹmọ, ki okú wọn ma bà wà lori agbelebu li ọjọ isimi, (nitori ojọ nla ni ọjọ isimi na) nitorina awọn Ju bẹ̀ Pilatu pe ki a ṣẹ egungun itan wọn, ki a si gbe wọn kuro.
32Nitorina awọn ọmọ-ogun wá, nwọn si ṣẹ́ egungun itan ti ekini, ati ti ekeji, ti a kàn mọ agbelebu pẹlu rẹ̀.
33Ṣugbọn nigbati nwọn de ọdọ Jesu, ti nwọn si ri pe, o ti kú na, nwọn kò si ṣẹ́ egungun itan rẹ̀:
34Ṣugbọn ọkan ninu awọn ọmọ-ogun na fi ọ̀kọ gún u li ẹgbẹ, lojukanna ẹ̀jẹ ati omi si tú jade.
35Ẹniti o ri i si jẹri, otitọ si li ẹrí rẹ̀: o si mọ̀ pe õtọ li on wi, ki ẹnyin ki o le gbagbọ́.
36Nkan wọnyi ṣe, ki iwe-mimọ́ ki o le ṣẹ, ti o wipe, A kì yio fọ́ egungun rẹ̀.
37Iwe-mimọ́ miran ẹ̀wẹ si wipe, Nwọn o ma wò ẹniti a gún li ọ̀kọ.
Ìsìnkú Jesu
(Mat 27:57-61; Mak 15:42-47; Luk 23:50-56)
38Lẹhin nkan wọnyi ni Josefu ará Arimatea, ẹniti iṣe ọmọ-ẹhin Jesu, ṣugbọn ni ikọ̀kọ nitori ìbẹru awọn Ju, o bẹ̀ Pilatu ki on ki o le gbé okú Jesu kuro: Pilatu si fun u li aṣẹ. Nitorina li o wá, o si gbé okú Jesu lọ.
39Nikodemu pẹlu si wá, ẹniti o tọ̀ Jesu wá loru lakọṣe, o si mu àdapọ̀ ojia ati aloe wá, o to ìwọn ọgọrun litra.
40Bẹni nwọn gbé okú Jesu, nwọn si fi aṣọ ọ̀gbọ dì i pẹlu turari, gẹgẹ bi iṣe awọn Ju ti ri ni isinkú wọn.
41Agbala kan si wà nibiti a gbé kàn a mọ agbelebu; ibojì titun kan sí wà ninu agbala na, ninu eyiti a ko ti itẹ́ ẹnikẹni si ri.
42Njẹ nibẹ ni nwọn si tẹ́ Jesu si, nitori Ipalẹmọ́ awọn Ju; nitori ibojì na wà nitosi.
Currently Selected:
Joh 19: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.