1
Saamu 143:10
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Kọ́ mi láti ṣe ìfẹ́ rẹ, nítorí ìwọ ni Ọlọ́run mi jẹ́ kí ẹ̀mí rẹ dídára darí mi sí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú.
Compare
Explore Saamu 143:10
2
Saamu 143:8
Mú mi gbọ́ ìṣeun ìfẹ́ rẹ ní òwúrọ̀: nítorí ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé. Fi ọ̀nà tí èmi i bá rìn hàn mí, nítorí èmi gbé ọkàn mi sókè sí ọ.
Explore Saamu 143:8
3
Saamu 143:9
Gbà mí kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi, OLúWA, nítorí èmi fi ara mi pamọ́ sínú rẹ.
Explore Saamu 143:9
4
Saamu 143:11
Nítorí orúkọ rẹ, OLúWA, sọ mi di ààyè; nínú òdodo rẹ, mú ọkàn mi jáde nínú wàhálà.
Explore Saamu 143:11
5
Saamu 143:1
OLúWA gbọ́ àdúrà mi, fetísí igbe mi fún àánú; nínú òtítọ́ àti òdodo rẹ, wá fún ìrànlọ́wọ́ mi
Explore Saamu 143:1
6
Saamu 143:7
Dá mi lóhùn kánkán, OLúWA; ó rẹ ẹ̀mí mi tán. Má ṣe pa ojú rẹ mọ́ kúrò lára mi kí èmi má ba à dàbí àwọn tí ó lọ sínú ihò
Explore Saamu 143:7
7
Saamu 143:5
Èmi rántí ọjọ́ tí ó ti pẹ́; èmi ń ṣe àṣàrò lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ mo sì ṣe àkíyèsí ohun tí ọwọ́ rẹ ti ṣe.
Explore Saamu 143:5
Home
Bible
Plans
Videos