TIMOTI KINNI 6
6
1Àwọn tí wọ́n wà lábẹ́ àjàgà ẹrú níláti rí i pé wọ́n ń bu ọlá fún àwọn ọ̀gá wọn ní ọ̀nà gbogbo, kí àwọn eniyan má baà sọ̀rọ̀ ìṣáátá sí orúkọ Ọlọrun ati ẹ̀kọ́ onigbagbọ. 2Àwọn ẹrú tí wọ́n ní ọ̀gá onigbagbọ kò gbọdọ̀ sọ ara wọn di ẹgbẹ́ ọ̀gá wọn, wọn ìbáà jẹ́ ará ninu Kristi. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n níláti sìn wọ́n tara-tara, nítorí àwọn tí wọn ń ṣiṣẹ́ fún jẹ́ arakunrin ninu igbagbọ ati ìfẹ́.
Ẹ̀kọ́ Burúkú ati Ọ̀rọ̀ Tòótọ́
Àwọn nǹkan wọnyi ni kí o máa fi kọ́ àwọn eniyan, kí o sì máa fi gbà wọ́n níyànjú. 3Bí ẹnìkan bá ń kọ́ àwọn eniyan ní ẹ̀kọ́ mìíràn, tí kò mọ ẹ̀kọ́ tí ó yè, ẹ̀kọ́ ti Oluwa wa Jesu Kristi, ati ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn tí ó pé, 4ìgbéraga ti sọ irú ẹni bẹ́ẹ̀ di aṣiwèrè, kò sì mọ nǹkankan. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ óo fẹ́ràn láti máa ṣe òfintótó ọ̀ràn, ati iyàn jíjà, àwọn ohun tí ó ń mú owú-jíjẹ, ìjà, ìsọkúsọ, ìfura burúkú, 5ati àríyànjiyàn wá. Nǹkan wọnyi wọ́pọ̀ láàrin àwọn tí orí wọn ti kú, tí wọ́n ti yapa kúrò ní ọ̀nà òtítọ́. Wọ́n rò pé nítorí èrè ni eniyan fi ń ṣe ẹ̀sìn.
6Òtítọ́ ni pé èrè ńlá wà ninu jíjẹ́ olùfọkànsìn, tí eniyan bá ní ìtẹ́lọ́rùn. 7Nítorí a kò mú ohunkohun wá sinu ayé, bẹ́ẹ̀ ni a kò lè mú ohunkohun kúrò ninu rẹ̀. 8Bí a bá ti ní oúnjẹ ati aṣọ, kí á ní ìtẹ́lọ́rùn pẹlu wọn. 9Àwọn tí wọn ń fẹ́ di ọlọ́rọ̀ a máa ṣubú sinu ìdánwò, tàkúté a sì mú wọn. Wọn a máa lépa ọpọlọpọ nǹkan tí kò mú ọgbọ́n wá ati àwọn nǹkan tí ó lè pa eniyan lára, irú nǹkan tí ó ti mú kí àwọn mìíràn jìn sinu ọ̀fìn ikú ati ìparun. 10Ìfẹ́ owó ni ìpìlẹ̀ gbogbo nǹkan burúkú. Èyí ni àwọn mìíràn ń lépa tí wọ́n fi ṣìnà kúrò ninu igbagbọ, tí wọ́n sì fi ọwọ́ ara wọn fa ọpọlọpọ ìbànújẹ́ fún ara wọn.
Ìjà Rere ti Igbagbọ
11Ṣugbọn ìwọ eniyan Ọlọrun, sá fún nǹkan wọnyi. Máa lépa òdodo, ati ìfọkànsìn Ọlọrun, igbagbọ, ìfẹ́, ìfaradà, ati ìwà pẹ̀lẹ́. 12Máa ja ìjà rere ti igbagbọ. Di ìyè ainipẹkun mú. Ohun tí Ọlọrun pè ọ́ fún nìyí, òun sì ni ẹ̀rí rere tí o fi ẹnu ara rẹ jẹ́ níwájú ọpọlọpọ ẹlẹ́rìí. 13Mo pá a láṣẹ fún ọ níwájú Ọlọrun tí ó fi ẹ̀mí sinu gbogbo ohun alààyè, ati níwájú Kristi Jesu tí òun náà jẹ́rìí rere níwájú Pọntiu Pilatu,#Joh 18:37 14pé kí o mú gbogbo àṣẹ tí o ti gbà ṣẹ láìsí àléébù ati láìsí ẹ̀gàn títí Oluwa wa Jesu Kristi yóo fi farahàn. 15Ọlọrun yóo mú ìfihàn yìí wá ní àkókò tí ó bá wù ú, òun ni aláṣẹ kanṣoṣo, Ọba àwọn ọba ati Oluwa àwọn oluwa; 16òun nìkan tí kì í kú, tí ó ń gbé inú ìmọ́lẹ̀ tí eniyan kò lè súnmọ́, tí ẹnikẹ́ni kò rí rí, tí eniyan kò tilẹ̀ lè rí. Tirẹ̀ ni ọlá ati agbára tí kò lópin. Amin.
17Mo pa á láṣẹ fún àwọn ọlọ́rọ̀ ayé yìí, pé kí wọ́n má ṣe ní ọkàn gíga. Bẹ́ẹ̀ ni kí wọ́n má ṣe gbára lé ọrọ̀ tí kò lágbẹkẹ̀lé, ṣugbọn kí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun tí ó ń fún wa ní gbogbo ọrọ̀ fún ìgbádùn wa. 18Kí wọn máa ṣe rere, kí wọn jẹ́ ọlọ́rọ̀ ninu iṣẹ́ rere, kí wọn fẹ́ràn láti máa ṣe ọrẹ ati láti máa mú ninu ohun ìní wọn fún àwọn ẹlòmíràn, 19kí wọ́n lè ní ìṣúra fún ara wọn tí yóo jẹ́ ìpìlẹ̀ rere fún ẹ̀yìn ọ̀la, kí ọwọ́ wọn lè tẹ ìyè tòótọ́.
20Timoti mi ọ̀wọ́n, pa ìṣúra tí a fi fún ọ mọ́. Di etí rẹ sí àwọn ọ̀rọ̀ játijàti tí kò ṣeni ní anfaani ati àwọn ọ̀rọ̀ tí àwọn kan ń ṣì pè ní ọ̀rọ̀ ọgbọ́n. Àṣìpè ni, nítorí pé wọ́n kún fún àwọn ẹ̀kọ́ tí ó lòdì sí ara wọn. 21Àwọn mìíràn tí wọ́n tẹ̀lé irú ọ̀nà yìí ti ṣìnà kúrò ninu igbagbọ.
Kí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun wà pẹlu yín.
Currently Selected:
TIMOTI KINNI 6: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010