TẸSALONIKA KEJI 1
1
Ìkíni
1Èmi Paulu, ati Silifanu, ati Timoti, ni à ń kọ ìwé yìí sí ìjọ Tẹsalonika, tíí ṣe ìjọ Ọlọrun Baba ati ti Jesu Kristi Oluwa.#A. Apo 17:1
2Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba ati Oluwa Jesu Kristi máa wà pẹlu yín.
Ìdájọ́ Nígbà Tí Jesu Bá Dé
3Ẹ̀yin ará, ó yẹ kí á máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun nígbà gbogbo nítorí yín. Ó tọ́ bẹ́ẹ̀ nítorí pé igbagbọ yín ń tóbi sí i, ìfẹ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan yín sí ara yín sì ń pọ̀ sí i. 4Àwa fúnra wa ń fọ́nnu nípa yín láàrin àwọn ìjọ Ọlọrun. À ń ròyìn ìfaradà ati igbagbọ yín ninu gbogbo inúnibíni ati ìpọ́njú tí ẹ̀ ń faradà.
5Ìfaradà yín jẹ́ ẹ̀rí ìdájọ́ òdodo Ọlọrun láti kà yín yẹ fún ìjọba rẹ̀ tí ẹ̀ ń tìtorí rẹ̀ jìyà. 6Nítorí ó tọ́ lójú Ọlọrun láti fi ìpọ́njú san ẹ̀san fún àwọn tí wọn ń pọn yín lójú, 7ati láti fún ẹ̀yin tí wọn ń pọ́n lójú, ati àwa náà ní ìsinmi, nígbà tí Oluwa wa, Jesu, bá farahàn láti ọ̀run ninu ọwọ́ iná pẹlu àwọn angẹli tí wọ́n jẹ́ alágbára. 8Nígbà náà ni yóo gbẹ̀san lára àwọn tí kò mọ Ọlọrun ati àwọn tí kò gba ọ̀rọ̀ ìyìn rere Oluwa wa Jesu. 9Àwọn yìí ni wọn yóo gba ìdálẹ́bi sí ìparun ayérayé, wọn yóo sì kúrò níwájú Oluwa ati ògo agbára rẹ̀;#Ais 2:10 10nígbà tí Oluwa bá dé ní ọjọ́ náà láti gba ògo lọ́dọ̀ àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀, nígbà tí gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́ yóo máa yẹ́ ẹ sí, nítorí wọ́n gba ẹ̀rí tí a jẹ́ fún wọn gbọ́.
11Nítorí èyí ni a fi ń gbadura fun yín nígbà gbogbo, pé kí Ọlọrun wa lè kà yín yẹ fún ìpè tí ó pè yín, kí ó mú èrò gbogbo ṣẹ, kí ó sì fi agbára fun yín láti máa gbé ìgbé-ayé tí ó yẹ onigbagbọ; 12kí ẹ lè yin orúkọ Oluwa wa Jesu lógo, kí òun náà sì yìn yín, gẹ́gẹ́ bí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun wa ati ti Oluwa Jesu Kristi.
Currently Selected:
TẸSALONIKA KEJI 1: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010