YouVersion Logo
Search Icon

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 10

10
Ìtàn Peteru ati Kọniliu
1Ọkunrin kan wà ní Kesaria tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kọniliu. Ó jẹ́ balogun ọ̀rún ti ẹgbẹ́ tí à ń pè ní Ẹgbẹ́ Ọmọ Ogun Itali. 2Olùfọkànsìn ni. Òun ati gbogbo ìdílé rẹ̀ sì bẹ̀rù Ọlọrun. A máa ṣàánú àwọn eniyan lọpọlọpọ, a sì máa gbadura sí Ọlọrun nígbà gbogbo. 3Ní ọjọ́ kan, ní nǹkan agogo mẹta ọ̀sán, ó rí ìran kan. Angẹli Ọlọrun wọlé tọ̀ ọ́ wá, ó ní, “Kọniliu!”
4Kọniliu bá tẹjú mọ́ ọn. Ẹ̀rù bà á, ó ní, “Kí ló dé, alàgbà?”
Angẹli yìí bá sọ fún un pé, “Adura rẹ ti gbà; iṣẹ́ àánú rẹ ti gòkè lọ siwaju Ọlọrun. Ọlọrun sì ti ranti rẹ. 5Nisinsinyii wá rán àwọn kan lọ sí Jọpa, kí wọn lọ pe ẹnìkan tí ń jẹ́ Simoni, tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Peteru, kí ó wá. 6Ó dé sílé ẹnìkan tí ń jẹ́ Simoni, tí ń ṣe òwò awọ, tí ilé rẹ̀ wà létí òkun.” 7Bí angẹli tí ó ń bá a sọ̀rọ̀ ti lọ tán, ó pe meji ninu àwọn iranṣẹ rẹ̀ ati ọmọ-ogun olùfọkànsìn kan, ọ̀kan ninu àwọn tí ó máa ń dúró tì í tímọ́tímọ́. 8Ó ròyìn ohun gbogbo fún wọn, ó bá rán wọn lọ sí Jọpa.
9Ní ọjọ́ keji, bí wọ́n ti ń bá ìrìn àjò wọn lọ, tí wọ́n súnmọ́ Jọpa, Peteru gun òkè ilé lọ láti gbadura ní nǹkan agogo mejila ọ̀sán.#Judt 8:5 10Ebi dé sí i, ó wá ń wá nǹkan tí yóo jẹ. Bí wọ́n ti ń tọ́jú oúnjẹ lọ́wọ́, Peteru bá rí ìran kan. 11Ó rí ọ̀run tí ó pínyà, tí nǹkankan bí aṣọ tí ó fẹ̀, tí ó ní igun mẹrin, ń bọ̀ wálẹ̀, títí ó fi dé ilẹ̀. 12Gbogbo ẹranko ẹlẹ́sẹ̀ mẹrin ati oríṣìíríṣìí ẹranko tí ó ń fi àyà fà, ati ẹyẹ ojú ọ̀run ni ó wà ninu rẹ̀. 13Ó wá gbọ́ ohùn ẹnìkan tí ó ń bá a sọ̀rọ̀, ó ní, “Peteru dìde, pa ẹran kí o jẹ ẹ́!”
14Ṣugbọn Peteru dáhùn pé, “Èèwọ̀ Oluwa! N kò jẹ ẹrankẹ́ran tabi ẹran àìmọ́ kan rí.”
15Ohùn náà tún dún létí rẹ̀ lẹẹkeji pé, “Ohun tí Ọlọrun bá ti sọ di mímọ́, o kò gbọdọ̀ pè é ní ohun àìmọ́!” 16Èyí ṣẹlẹ̀ lẹẹmẹta. Lẹsẹkẹsẹ a tún gbé aṣọ náà lọ sókè ọ̀run.
17Ìran tí Peteru rí yìí rú u lójú. Bí ó ti ń rò ó pé kí ni ìtumọ̀ ohun tí òun rí yìí, àwọn tí Kọniliu rán sí i ti wádìí ibi tí ilé Simoni wà, wọ́n ti dé ẹnu ọ̀nà. 18Wọ́n ké “Àgò!” wọ́n sì ń bèèrè bí Simoni tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Peteru bá dé sibẹ.
19Bí Peteru ti ń ronú lórí ìran yìí, Ẹ̀mí sọ fún un pé, “Àwọn ọkunrin mẹta#10:19 Dípò mẹta, Bibeli àtijọ́ kan tí ó dára pupọ sọ pé meji. Àwọn Bibeli àtijọ́ mìíràn kò sọ iye wọn ní pàtó. ń wá ọ. 20Dìde, lọ sí ìsàlẹ̀, kí o bá wọn lọ láì kọminú nítorí èmi ni mo rán wọn.” 21Nígbà tí Peteru dé ìsàlẹ̀, ó wí fún àwọn ọkunrin náà pé, “Èmi tí ẹ̀ ń wá nìyí, kí ni ẹ̀ ń fẹ́ o?”
22Wọ́n bá dáhùn pé, “Kọniliu ọ̀gágun ni ó rán wa wá; eniyan rere ni, ó sì bẹ̀rù Ọlọrun tóbẹ́ẹ̀ tí gbogbo àwọn ọmọ Juu fi lè jẹ́rìí sí i. Angẹli Oluwa ni ó sọ fún un pé kí ó ranṣẹ pè ọ́ wá sí ilé rẹ̀, kí ó lè gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ.” 23Ni Peteru bá pè wọ́n wọlé, ó gbà wọ́n lálejò.
Nígbà tí ó di ọjọ́ keji, ó dìde, ó bá wọn lọ. Àwọn kan ninu àwọn ọmọ ìjọ ní Jọpa sì tẹ̀lé wọn. 24Ní ọjọ́ keji tí wọ́n gbéra ní Jọpa ni wọ́n dé Kesaria. Kọniliu ti ń retí wọn. Ó ti pe àwọn ẹbí ati àwọn tí ó jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ jọ. 25Bí Peteru ti fẹ́ wọlé, Kọniliu lọ pàdé rẹ̀. Ó kúnlẹ̀, ó sì foríbalẹ̀. 26Ṣugbọn Peteru fà á dìde, ó ní, “Dìde! Eniyan ni èmi náà.” 27Bí ó ti ń bá a sọ̀rọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó bá a wọlé. Ó rí ọ̀pọ̀ eniyan tí ó ti péjọ. 28Ó sọ fún wọn pé, “Ó ye yín pé ó lòdì sí òfin wa pé kí ẹni tíí ṣe Juu kí ó ní nǹkan í ṣe pẹlu ẹni tí ó jẹ́ ẹ̀yà mìíràn, tabi kí ó lọ bẹ̀ ẹ́ wò ninu ilé rẹ̀. Ṣugbọn Ọlọrun ti fihàn mí pé n kò gbọdọ̀ pe ẹnikẹ́ni ni eniyan lásán tabi aláìmọ́. 29Ìdí tí mo ṣe wá láì kọminú nìyí nígbà tí o ranṣẹ sí mi. Mo wá fẹ́ mọ ìdí rẹ̀ tí o fi ranṣẹ sí mi.”
30Kọniliu dáhùn pé, “Ní ijẹrin, ní déédé àkókò yìí, mo ń gbadura ninu ilé mi ní agogo mẹta ọ̀sán. Ọkunrin kan bá yọ sí mi, ó wọ aṣọ dídán. 31Ó ní, ‘Kọniliu, Ọlọrun ti gbọ́ adura rẹ, ó sì ti ranti iṣẹ́ àánú rẹ. 32Nítorí náà, ranṣẹ lọ sí Jọpa, kí o lọ pe Simoni tí àdàpè rẹ̀ ń jẹ́ Peteru wá. Ó dé sílé Simoni tí ń ṣe òwò awọ, létí òkun.’ 33Lẹsẹkẹsẹ ni mo bá ranṣẹ sí ọ. O ṣeun tí o wá. Nisinsinyii gbogbo wa wà níwájú Ọlọrun láti gbọ́ ohun gbogbo tí Oluwa ti pa láṣẹ fún ọ láti sọ.”
Ọ̀rọ̀ Tí Peteru Sọ nílé Kọniliu
34Peteru bá tẹnu bọ̀rọ̀. Ó ní, “Ó wá yé mi gan-an pé Ọlọrun kì í ṣe ojuṣaaju.#Diut 10:17 35Ẹnikẹ́ni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣe rere ni yóo fà mọ́ra láì bèèrè orílẹ̀-èdè tí ó jẹ́. 36Ẹ mọ iṣẹ́ tí ó rán sí àwọn ọmọ Israẹli, ọ̀rọ̀ ìyìn rere alaafia nípasẹ̀ Jesu Kristi, ẹni tíí ṣe Oluwa gbogbo eniyan. 37Ẹ mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní gbogbo Judia. Ó bẹ̀rẹ̀ láti Galili lẹ́yìn ìrìbọmi tí Johanu ń sọ pé kí àwọn eniyan ṣe. 38Ẹ mọ̀ nípa Jesu ará Nasarẹti, bí Ọlọrun ti ṣe yàn án, tí ó fún un ní Ẹ̀mí Mímọ́ ati agbára; bí ó ti ṣe ń lọ káàkiri tí ó ń ṣe rere, tí ó ń wo gbogbo àwọn tí Satani ti ń dá lóró sàn, nítorí Ọlọrun wà pẹlu rẹ̀. 39Àwa yìí ni ẹlẹ́rìí gbogbo ohun tí ó ṣe ní ilẹ̀ àwọn Juu ati ní Jerusalẹmu. Wọ́n kan ọkunrin yìí mọ́ agbelebu. 40Ṣugbọn Ọlọrun jí i dìde ní ọjọ́ kẹta, ó sì jẹ́ kí eniyan rí i. 41Kì í ṣe gbogbo eniyan ni ó rí i bíkòṣe àwọn ẹlẹ́rìí tí Ọlọrun ti yàn tẹ́lẹ̀, àwa tí a bá a jẹ, tí a bá a mu lẹ́yìn tí ó jinde kúrò ninu òkú. 42Ó wá pàṣẹ fún wa láti waasu fún àwọn eniyan, kí á fi yé wọn pé Jesu yìí ni ẹni tí Ọlọrun ti yàn láti jẹ́ onídàájọ́ àwọn tí ó ti kú ati àwọn tí ó wà láàyè. 43Òun ni gbogbo àwọn wolii ń jẹ́rìí sí, tí wọ́n sọ pé gbogbo ẹni tí ó bá gbà á gbọ́ yóo ní ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ ní orúkọ rẹ̀.”
Àwọn Tí Kì Í ṣe Juu Gba Ẹ̀mí Mímọ́
44Bí Peteru ti ń sọ̀rọ̀ báyìí lọ́wọ́, kò tíì dákẹ́ ọ̀rọ̀ tí ń sọ, bẹ́ẹ̀ ni Ẹ̀mí Mímọ́ bá bà lé gbogbo àwọn tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ náà. 45Ẹnu ya àwọn onigbagbọ tí wọ́n jẹ́ Juu tí wọ́n bá Peteru wá nítorí àwọn tí kì í ṣe Juu rí ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ gbà lọ́fẹ̀ẹ́ ati lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. 46Wọ́n gbọ́ tí wọn ń fi oríṣìíríṣìí èdè sọ̀rọ̀, tí wọn ń yin Ọlọrun fún iṣẹ́ ńlá rẹ̀. Peteru bá bèèrè pé, 47“Ta ló rí ohun ìdíwọ́ kan, ninu pé kí á ṣe ìrìbọmi fún àwọn wọnyi, tí wọ́n gba Ẹ̀mí Mímọ́ bí àwa náà ti gbà á?” 48Lẹ́yìn náà, ó pàṣẹ pé kí wọ́n ṣe ìrìbọmi ní orúkọ Jesu Kristi. Wọ́n bá bẹ̀ ẹ́ kí ó dúró lọ́dọ̀ wọn fún ọjọ́ díẹ̀.

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

Video for ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 10