EFESU 6:10-18
EFESU 6:10-18 YCE
Ní ìparí, ẹ jẹ́ alágbára ninu Oluwa, kí ẹ fi agbára rẹ̀ ṣe okun yín. Ẹ gbé gbogbo ihamọra Ọlọrun wọ̀, kí ẹ lè dúró láti dojú kọ èṣù pẹlu ọgbọ́n àrékérekè rẹ̀. Nítorí kì í ṣe eniyan ni à ń bá jagun, bíkòṣe àwọn ẹ̀mí burúkú ojú ọ̀run, àwọn aláṣẹ ati àwọn alágbára òkùnkùn ayé yìí. Nítorí èyí, ẹ gbé gbogbo ihamọra Ọlọrun wọ̀, kí ẹ lè dìde dúró láti jà nígbà tí ọjọ́ ibi bá dé. Nígbà tí ìjà bá sì dópin, kí ẹ lè wà ní ìdúró. Nítorí náà, ẹ dúró gbọningbọnin. Ẹ fi òtítọ́ ṣe ọ̀já ìgbànú yín. Ẹ fi òdodo bo àyà yín bí apata. Ẹ jẹ́ kí ìmúrasílẹ̀ láti waasu ìyìn rere alaafia jẹ́ bàtà ẹsẹ̀ yín. Lẹ́yìn gbogbo nǹkan wọnyi, ẹ fi igbagbọ ṣe ààbò yín. Nípa rẹ̀ ni ẹ óo lè fi pa iná gbogbo ọfà amúbíiná tí èṣù ń ta. Ẹ fi ìgbàlà ṣe fìlà onírin tí ẹ óo máa dé, kí ẹ sì mú idà Ẹ̀mí Mímọ́, tíí ṣe ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Ẹ máa gbadura nígbà gbogbo, kí ẹ máa fi gbogbo ẹ̀bẹ̀ yín siwaju Ọlọrun nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́. Nítorí náà, ẹ máa gbadura láì sùn, láì wo, fún gbogbo àwọn eniyan Ọlọrun.