ẸSITA 7
7
1Ọba ati Hamani lọ bá Ayaba Ẹsita jẹ àsè. 2Ní ọjọ́ keji, bí wọ́n ti ń mu ọtí, ọba tún bi Ẹsita pé, “Ẹsita, Ayaba, kí ni ẹ̀bẹ̀ rẹ, a óo ṣe é fún ọ. Kí ni ìbéèrè rẹ, gbogbo rẹ̀ ni yóo sì tẹ̀ ọ́ lọ́wọ́, àní títí kan ìdajì ìjọba mi.”
3Ẹsita ayaba dáhùn, ó ní, “Kabiyesi, bí mo bá rí ojurere rẹ, bí ó bá sì wù ọ́, dá ẹ̀mí mi ati ti àwọn eniyan mi sí. 4Wọ́n ti ta èmi ati àwọn eniyan mi fún pípa, wọn ó sì pa wá run. Bí ó bá jẹ́ pé wọ́n ta tọkunrin tobinrin wa bí ẹrú lásán ni, n kì bá tí yọ ìwọ kabiyesi lẹ́nu rárá, nítorí a kò lè fi ìnira wa wé àdánù tí yóo jẹ́ ti ìwọ ọba.”
5Ahasu-erusi ọba bi Ẹsita Ayaba pé, “Ta ni olúwarẹ̀, níbo ni ẹni náà wà, tí ń gbèrò láti dán irú nǹkan bẹ́ẹ̀ wò?”
6Ẹsita bá dá a lóhùn pé, “Ọlọ̀tẹ̀ ati ọ̀tá náà ni Hamani eniyan burúkú yìí.” Ẹ̀rù ba Hamani gidigidi níwájú ọba ati ayaba. 7Ọba dìde kúrò ní ibi àsè náà pẹlu ibinu, ó jáde lọ sinu àgbàlá ààfin. Nígbà tí Hamani rí i pé ọba ti pinnu ibi fún òun, ó dúró lẹ́yìn láti bẹ Ẹsita Ayaba fún ẹ̀mí rẹ̀. 8Bí ọba ti pada wá láti inú àgbàlá sí ibi tí wọ́n ti ń mu ọtí, ó rí Hamani tí ó ṣubú sí ibi àga tí Ẹsita rọ̀gbọ̀kú sí. Ọba ní, “Ṣé yóo tún máa fi ọwọ́ pa Ayaba lára lójú mi ni, ninu ilé mi?” Ní kété tí ọba sọ̀rọ̀ yìí tán, wọ́n faṣọ bo Hamani lójú. 9Habona, ọ̀kan ninu àwọn ìwẹ̀fà ọba, bá sọ fún ọba pé, “Igi kan, tí ó ga ní aadọta igbọnwọ (mita 22) wà ní ilé rẹ̀, tí ó ti rì mọ́lẹ̀ láti gbé Modekai kọ́ sí, Modekai tí ó gba ẹ̀mí rẹ là.”
10Ọba bá ní kí wọ́n lọ gbé Hamani kọ́ sí orí rẹ̀. Wọ́n bá gbé Hamani kọ́ sí orí igi tí ó ti rì mọ́lẹ̀ fún Modekai, nígbà náà ni inú ọba tó rọ̀.
Currently Selected:
ẸSITA 7: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010