YouVersion Logo
Search Icon

ẸKISODU 6

6
1Ṣugbọn OLUWA sọ fún Mose pé, “O óo rí ohun tí n óo ṣe sí ọba Farao; ó fẹ́, ó kọ̀, yóo jẹ́ kí àwọn eniyan mi lọ, fúnra rẹ̀ ni yóo sì fi ipá tì wọ́n jáde.”
Ọlọrun Pe Mose
2Ọlọrun tún sọ fún Mose pé, “Èmi ni OLUWA. 3Mo fara han Abrahamu, Isaaki, ati Jakọbu gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun Olodumare, ṣugbọn n kò farahàn wọ́n gẹ́gẹ́ bí OLUWA#6:3 OLUWA tí a kọ pẹlu lẹta ńlá ni a lò láti túmọ̀ YAHWEH tí í ṣe orúkọ Ọlọrun ní èdè Heberu . tíí ṣe orúkọ mi gan-an.#Jẹn 17:1; 28:3; 35:11; Eks 3:13-15. 4Mo tún bá wọn dá majẹmu pé n óo fi ilẹ̀ Kenaani fún wọn, ilẹ̀ tí wọ́n ti jẹ́ àlejò. 5Mo gbọ́ ìkérora àwọn ọmọ Israẹli tí àwọn ará Ijipti dì ní ìgbèkùn, mo sì ranti majẹmu mi. 6Nítorí náà, sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Èmi ni OLUWA, n óo yọ yín jáde kúrò lábẹ́ ẹrù wúwo tí àwọn ará Ijipti dì rù yín, n óo yọ yín kúrò ninu ìgbèkùn wọn, ipá ni n óo sì fi rà yín pada pẹlu ìdájọ́ ńlá. 7N óo mu yín gẹ́gẹ́ bí eniyan mi, n óo jẹ́ Ọlọrun yín; ẹ óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA Ọlọrun yín, tí ó fà yín yọ kúrò lábẹ́ ẹrù wúwo tí àwọn ará Ijipti dì rù yín. 8N óo sì ko yín wá sí ilẹ̀ tí mo búra láti fún Abrahamu, ati Isaaki ati Jakọbu; n óo fún yín gẹ́gẹ́ bí ìní, Èmi ni OLUWA.’ ” 9Mose sọ ọ̀rọ̀ wọnyi fún àwọn eniyan Israẹli, ṣugbọn wọn kò fetí sí ohun tí ó ń sọ, nítorí pé ìyà burúkú tí wọn ń jẹ ní oko ẹrú ti jẹ́ kí ọkàn wọn rẹ̀wẹ̀sì.
10OLUWA bá sọ fún Mose pé, 11“Wọlé lọ sí ọ̀dọ̀ Farao, ọba ilẹ̀ Ijipti, kí o wí fún un pé kí ó jẹ́ kí àwọn eniyan Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀.”
12Ṣugbọn Mose dá OLUWA lóhùn pé, “Àwọn eniyan Israẹli gan-an kò gbọ́ tèmi, báwo ni Farao yóo ṣe gbọ́, èmi akólòlò lásánlàsàn.”
13Ṣugbọn Ọlọrun bá Mose ati Aaroni sọ̀rọ̀, ó wá pàṣẹ ohun tí wọn yóo sọ fún àwọn eniyan Israẹli ati fún Farao, ọba Ijipti, pé kí ó kó àwọn eniyan Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti.
Àkọsílẹ̀ Ìran Mose ati Ti Aaroni
14Èyí ni àkọsílẹ̀ àwọn olórí olórí ninu ìdílé wọn: Reubẹni, àkọ́bí Jakọbu bí ọmọkunrin mẹrin: Hanoku, Palu, Hesironi ati Karimi; àwọn ni olórí àwọn ìdílé ẹ̀yà Reubẹni. 15Simeoni bí ọmọkunrin mẹfa: Jemueli, Jamini, Ohadi, Jakini, Sohari ati Ṣaulu, tí obinrin ará Kenaani kan bí fún un; àwọn ni olórí àwọn ìdílé ẹ̀yà Simeoni. 16Lefi bí ọmọ mẹta: Geriṣoni, Kohati ati Merari; àwọn ni olórí àwọn ìdílé ẹ̀yà Lefi. Ọdún mẹtadinlogoje (137) ni Lefi gbé láyé. 17Geriṣoni bí ọmọ meji: Libini ati Ṣimei, wọ́n jẹ́ olórí àwọn ìdílé wọn. 18Kohati bí ọmọ mẹrin: Amramu, Iṣari, Heburoni ati Usieli. Ọdún mẹtalelaadoje (133) ni Kohati gbé láyé. 19Merari bí ọmọkunrin meji: Mahili ati Muṣi. Àwọn ìdílé ẹ̀yà Lefi nìwọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí arọmọdọmọ wọn.#Nọm 3:17-20; 26:57-58; 1 Krọ 6:16-19.
20Amramu fẹ́ Jokebedi, arabinrin baba rẹ̀. Jokebedi sì bí Aaroni ati Mose fún un. Ọdún mẹtadinlogoje (137) ni Amramu gbé láyé. 21Iṣari bí ọmọkunrin mẹta: Kora, Nefegi ati Sikiri. 22Usieli bí ọmọkunrin mẹta: Miṣaeli, Elisafani ati Sitiri.
23Aaroni fẹ́ Eliṣeba ọmọbinrin Aminadabu tíí ṣe arabinrin Naṣoni. Àwọn ọmọ tí ó bí fún un nìwọ̀nyí: Nadabu, Abihu, Eleasari, ati Itamari. 24Kora bí ọmọkunrin mẹta: Asiri, Elikana ati Abiasafu; àwọn ni ìdílé Kora. 25Eleasari ọmọ Aaroni fẹ́ ọ̀kan ninu àwọn ọmọbinrin Putieli; ó sì bí Finehasi fún un; àwọn ni olórí àwọn ìdílé ẹ̀yà Lefi.
26Aaroni ati Mose ni OLUWA pè, tí ó sì wí fún pé kí wọ́n kó àwọn eniyan Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti. 27Àwọn ni wọ́n sọ fún ọba Ijipti pé kí ó dá àwọn eniyan Israẹli sílẹ̀.
Àṣẹ Tí OLUWA Pa fún Mose ati Aaroni
28Ní ọjọ́ tí OLUWA bá Mose sọ̀rọ̀ ní ilẹ̀ Ijipti, 29OLUWA sọ fún un pé, “Èmi ni OLUWA, sọ gbogbo ohun tí mo rán ọ fún Farao, ọba Ijipti.”
30Ṣugbọn Mose dáhùn pé, “OLUWA, akólòlò ni mí; báwo ni ọba Farao yóo ṣe fetí sí ọ̀rọ̀ mi?”

Currently Selected:

ẸKISODU 6: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in