ẸSIRA 2
2
Àwọn tí Wọ́n Pada ti Oko Ẹrú Dé
(Neh 7:4-73)
1Àwọn ọmọ Juda wọnyi ni wọ́n pada dé láti oko ẹrú ní Babiloni, níbi tí Nebukadinesari, ọba Babiloni, kó wọn lẹ́rú lọ. Wọ́n pada sí Jerusalẹmu ati ilẹ̀ Juda, olukuluku pada sí ìlú rẹ̀. 2Àwọn olórí wọn ni: Serubabeli, Jeṣua, Nehemaya, Seraaya, Reelaya, Modekai, Biliṣani, Misipa, Bigifai, Rehumu ati Baana.
Iye àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n pada láti oko ẹrú ní ìdílé ìdílé nìyí:
3Àwọn ọmọ Paroṣi jẹ́ ẹgbaa lé mejilelaadọsan-an (2,172)
4Àwọn ọmọ Ṣefataya jẹ́ ọọdunrun ó lé mejilelaadọrin (372)
5Àwọn ọmọ Ara jẹ́ ẹẹdẹgbẹrin lé marundinlọgọrin (775)
6Àwọn ọmọ Pahati Moabu láti inú ìran Jeṣua ati Joabu jẹ́ ẹgbẹrinla lé mejila (2,812)
7Àwọn ọmọ Elamu jẹ́ ẹgbẹfa ó lé mẹrinlelaadọta (1,254)
8Àwọn ọmọ Satu jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ó lé marundinlaadọta (945)
9Àwọn ọmọ Sakai jẹ́ ẹẹdẹgbẹrin ó lé ọgọta (760)
10Àwọn ọmọ Bani jẹ́ ẹgbẹta ó lé mejilelogoji (642)
11Àwọn ọmọ Bebai jẹ́ ẹgbaata ó lé mẹtalelogun (623)
12Àwọn ọmọ Asigadi jẹ́ ẹgbẹfa ó lé mejilelogun (1,222)
13Àwọn ọmọ Adonikamu jẹ́ ẹgbẹta ó lé mẹrindinlaadọrin (666)
14Àwọn ọmọ Bigifai jẹ́ ẹgbaa ó lé mẹrindinlọgọta (2,056)
15Àwọn ọmọ Adini jẹ́ irinwo ó lé mẹrinlelaadọta (454)
16Àwọn ọmọ Ateri láti inú ìran Hesekaya jẹ́ mejidinlọgọrun-un
17Àwọn ọmọ Besai jẹ́ ọọdunrun ó lé mẹtalelogun (323)
18Àwọn ọmọ Jora jẹ́ aadọfa ó lé meji (112)
19Àwọn ọmọ Haṣumu jẹ́ igba ó lé mẹtalelogun (223)
20Àwọn ọmọ Gibari jẹ́ marundinlọgọrun-un
21Àwọn ọmọ Bẹtilẹhẹmu jẹ́ mẹtalelọgọfa (123)
22Àwọn eniyan Netofa jẹ́ mẹrindinlọgọta
23Àwọn eniyan Anatoti jẹ́ mejidinlaadoje (128)
24Àwọn ọmọ Asimafeti jẹ́ mejilelogoji
25Àwọn ọmọ Kiriati Jearimu; Kefira ati Beeroti jẹ́ ẹẹdẹgbẹrin ó lé mẹtalelogoji (743)
26Àwọn ọmọ Rama ati Geba jẹ́ ẹgbẹta ó lé mọkanlelogun (621)
27Àwọn ọmọ Mikimaṣi jẹ́ mejilelọgọfa (122)
28Àwọn eniyan Bẹtẹli ati Ai jẹ́ igba ó lé mẹtalelogun (223)
29Àwọn ọmọ Nebo jẹ́ mejilelaadọta
30Àwọn ọmọ Magibiṣi jẹ́ mẹrindinlọgọjọ (156)
31Àwọn ọmọ Elamu keji jẹ́ ẹgbẹfa ó lé mẹrinlelaadọta (1,254)
32Àwọn ọmọ Harimu jẹ́ ọọdunrun ó lé ogún (320)
33Àwọn ọmọ Lodi, Hadidi ati Ono jẹ́ ẹẹdẹgbẹrin ó lé mẹẹdọgbọn (725)
34Àwọn ọmọ Jẹriko jẹ́ ojilelọọdunrun ó lé marun-un (345)
35Àwọn ọmọ Senaa jẹ́ egbejidinlogun ó lé ọgbọ̀n (3,630)
36Iye àwọn alufaa tí wọ́n pada dé láti, oko ẹrú wọn nìwọ̀nyí:
Àwọn ọmọ Jedaaya láti inú ìdílé Jeṣua jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ó lé mẹtalelaadọrin (973)
37Àwọn ọmọ Imeri jẹ́ ẹgbẹrun ó lé mejilelaadọta (1,052)
38Àwọn ọmọ Paṣuri jẹ́ ẹgbẹfa ó lé mẹtadinlaadọta (1,247)
39Àwọn ọmọ Harimu jẹ́ ẹgbẹrun ó lé mẹtadinlogun (1,017)
40Iye àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n pada dé láti oko ẹrú nìwọ̀nyí:
Àwọn ọmọ Jeṣua ati Kadimieli láti inú ìran Hodafaya jẹ́ mẹrinlelaadọrin
41Àwọn ọmọ Asafu tí wọ́n jẹ́ akọrin ní tẹmpili jẹ́ mejidinlaadoje (128)
42Iye àwọn ọmọ àwọn aṣọ́nà:
àwọn ọmọ Ṣalumu ati àwọn ọmọ Ateri, àwọn ọmọ Talimoni ati àwọn ọmọ Akubu; àwọn ọmọ Hatita ati àwọn ọmọ Ṣobai jẹ́ mọkandínlogoje (139)
43Àwọn òṣìṣẹ́ tẹmpili nìwọ̀nyí:
àwọn ọmọ Siha, àwọn ọmọ Hasufa ati àwọn ọmọ Tabaoti;
44àwọn ọmọ Kerosi, àwọn ọmọ Siaha ati àwọn ọmọ Padoni;
45àwọn ọmọ Lebana, àwọn ọmọ Hagaba ati àwọn ọmọ Akubu;
46àwọn ọmọ Hagabu, àwọn ọmọ Ṣamlai ati àwọn ọmọ Hanani;
47àwọn ọmọ Gideli, àwọn ọmọ Gahari ati àwọn ọmọ Reaaya;
48àwọn ọmọ Resini, àwọn ọmọ Nekoda ati àwọn ọmọ Gasamu;
49àwọn ọmọ Usa, àwọn ọmọ Pasea, ati àwọn ọmọ Besai;
50àwọn ọmọ Asina, àwọn ọmọ Meuni, ati àwọn ọmọ Nefisimu;
51àwọn ọmọ Bakibuki, àwọn ọmọ Akufa, àwọn ọmọ Hahuri,
52àwọn ọmọ Basiluti, àwọn ọmọ Mehida, ati àwọn ọmọ Haṣa,
53àwọn ọmọ Bakosi, àwọn ọmọ Sisera, ati àwọn ọmọ Tema,
54àwọn ọmọ Nesaya ati àwọn ọmọ Hatifa.
55Àwọn ọmọ àwọn iranṣẹ Solomoni nìyí:
àwọn ọmọ Sotai, àwọn ọmọ Hasofereti, ati àwọn ọmọ Peruda;
56àwọn ọmọ Jaala, àwọn ọmọ Dakoni, ati àwọn ọmọ Gideli;
57àwọn ọmọ Ṣefataya ati àwọn ọmọ Hatili, àwọn ọmọ Pokereti Hasebaimu ati àwọn ọmọ Ami.
58Àwọn òṣìṣẹ́ tẹmpili ati àwọn ọmọ àwọn iranṣẹ Solomoni jẹ́ irinwo ó dín mẹjọ (392).
59Àwọn kan wá láti Teli Mela, Teli Hariṣa, Kerubu, Adani ati Imeri tí wọn kò mọ ìdílé baba wọn tabi ìran wọn, yálà wọ́n jẹ́ ọmọ Israẹli tabi wọn kì í ṣe ọmọ Israẹli àwọn nìwọ̀nyí:
60Àwọn ọmọ Delaaya, àwọn ọmọ Tobaya, ati àwọn ọmọ Nekoda. Gbogbo wọn jẹ́ ọtalelẹgbẹta ó dín mẹjọ (652).
61Àwọn tí wọ́n jẹ́ ọmọ alufaa ninu wọn nìwọ̀nyí: àwọn ọmọ Habaya, àwọn ọmọ Hakosi, ati àwọn ọmọ Basilai (tí ó fẹ́ aya ninu ìdílé Basilai ará Gileadi, tí wọ́n sì ń fi orúkọ àna rẹ̀ pe àwọn ọmọ rẹ̀).
62Wọ́n wá orúkọ wọn ninu ìwé àkọsílẹ̀ tí a kọ ní ìdílé ìdílé, ṣugbọn wọn kò rí i. Nítorí náà a kà wọ́n kún aláìmọ́, a sì yọ wọ́n kúrò ninu iṣẹ́ alufaa.
63Gomina sọ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ jẹ ninu àwọn oúnjẹ mímọ́ jùlọ, títí tí wọn yóo fi rí alufaa kan tí ó lè lo Urimu ati Tumimu láti wádìí lọ́wọ́ OLUWA.#Nọm 27:21
64Àpapọ̀ gbogbo àwọn tí wọ́n ti oko ẹrú dé jẹ́ ọ̀kẹ́ meji ó lé ẹgbaa, ó lé ọtalelọọdunrun (42,360).
65Láìka àwọn iranṣẹkunrin ati àwọn iranṣẹbinrin wọn tí wọ́n jẹ́ ẹẹdẹgbaarin ó lé ojilelọọdunrun ó dín mẹta (7,337). Wọ́n sì tún ní igba (200) akọrin lọkunrin, ati lobinrin.
66Àwọn ohun ọ̀sìn tí wọ́n kó bọ̀ nìwọ̀nyí: ẹṣin wọn jẹ́ ẹẹdẹgbẹrin ó lé mẹrindinlogoji (736) akọ mààlúù wọn jẹ́ igba ó lé marundinlaadọta (245)
67Ràkúnmí wọn jẹ́ irinwo ó lé marundinlogoji (435), kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn jẹ́ ẹgbaata ó lé okoolelẹẹdẹgbẹrin (6,720).
68Nígbà tí wọ́n dé ilé OLUWA ní Jerusalẹmu, díẹ̀ ninu àwọn olórí ìdílé náà fi ọrẹ àtinúwá sílẹ̀ láti tún ilé Ọlọrun kọ́ sí ààyè rẹ̀.
69Wọ́n ṣe gẹ́gẹ́ bí agbára wọn ti tó. Wọ́n fi ọọdunrun ó lé mejila (312) kilogiramu wúrà ẹgbẹsan (1,800) kilogiramu fadaka ati ọgọrun-un (100) ẹ̀wù alufaa, ṣe ẹ̀bùn fún ilé OLUWA.
70Àwọn alufaa, àwọn ọmọ Lefi ati àwọn kan ninu àwọn eniyan náà ń gbé Jerusalẹmu ati agbègbè rẹ̀. Àwọn akọrin, àwọn aṣọ́nà ati àwọn òṣìṣẹ́ tẹmpili ń gbé àwọn ìlú tí ó wà nítòsí wọn, àwọn ọmọ Israẹli yòókù sì ń gbé àwọn ìlú wọn.#1Kron 9:2; Neh 11:3
Currently Selected:
ẸSIRA 2: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010