YouVersion Logo
Search Icon

ẸSIRA 8

8
Àwọn tí Wọ́n Pada láti Oko Ẹrú
1Àkọsílẹ̀ àwọn eniyan ati àwọn baálé baálé tí wọ́n bá mi pada wá láti Babiloni ní àkókò Atasasesi, ọba, nìyí:
2Ninu àwọn ọmọ Finehasi, Geriṣomu ni olórí.
Ninu àwọn ọmọ Itamari, Daniẹli ni olórí.
Ninu àwọn ọmọ Dafidi,
3Hatuṣi, ọmọ Ṣekanaya, ni olórí.
Ninu àwọn ọmọ Paroṣi, Sakaraya ni olórí;
orúkọ aadọjọ (150) eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀.
4Ninu àwọn ọmọ Pahati Moabu, Eliehoenai, ọmọ Serahaya, ni olórí;
orúkọ igba (200) eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀.
5Ninu àwọn ọmọ Satu, Ṣekanaya, ọmọ Jahasieli, ni olórí;
orúkọ ọọdunrun (300) eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀.
6Ninu àwọn ọmọ Adini, Ebedi, ọmọ Jonatani, ni olórí;
orúkọ aadọta eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀.
7Ninu àwọn ọmọ Elamu, Jeṣaya, ọmọ Atalaya, ni olórí;
orúkọ aadọrin eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀.
8Ninu àwọn ọmọ Ṣefataya, Sebadaya, ọmọ Mikaeli, ni olórí;
orúkọ ọgọrin eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀.
9Ninu àwọn ọmọ Joabu, Ọbadaya, ọmọ Jehieli, ni olórí;
orúkọ igba eniyan ó lé mejidinlogun (218) ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀.
10Ninu àwọn ọmọ Bani, Ṣelomiti, ọmọ Josifaya, ni olórí;
orúkọ ọgọjọ (160) eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀.
11Ninu àwọn ọmọ Bebai, Sakaraya, ọmọ Bebai, ni olórí;
orúkọ eniyan mejidinlọgbọn ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀.
12Ninu àwọn ọmọ Asigadi, Johanani, ọmọ Hakatani, ni olórí;
orúkọ aadọfa (110) eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀.
13Ninu àwọn ọmọ Adonikamu,
orúkọ àwọn tí wọ́n dé lẹ́yìn àwọn tí wọ́n kọ́ dé ni:
Elifeleti, Jeueli ati Ṣemaaya; orúkọ ọgọta eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu wọn.
14Ninu àwọn ọmọ Bigifai, Utai ati Sakuri ni olórí,
orúkọ aadọrin eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu wọn.
Ẹsira Wá Àwọn Ọmọ Lefi Kan fún Iṣẹ́ Tẹmpili
15Mo pe gbogbo wọn jọ síbi odò tí ń ṣàn lọ sí Ahafa, a sì pàgọ́ sibẹ fún ọjọ́ mẹta. Nígbà tí mo wo ààrin àwọn eniyan ati àwọn alufaa, n kò rí ọmọ Lefi kankan níbẹ̀. 16Mo bá ranṣẹ pe àwọn olórí wọn wọnyi: Elieseri, Arieli ati Ṣemaaya, Elinatani, Jaribu, Elinatani Natani, Sakaraya, ati Meṣulamu. Mo sì tún ranṣẹ pe Joiaribu ati Elinatani, tí wọ́n jẹ́ amòye. 17Mo rán wọn lọ sọ́dọ̀ Ido, olórí àwọn eniyan ní Kasifia; mo ní kí wọ́n sọ fún Ido ati àwọn arakunrin rẹ̀ tí ń ṣiṣẹ́ ninu tẹmpili pé kí wọ́n fi àwọn eniyan tí yóo máa ṣe iṣẹ́ ìsìn ninu ilé Ọlọrun wa ranṣẹ. 18Pẹlu ìrànlọ́wọ́ Ọlọrun, wọ́n fi Ṣerebaya, ọlọ́gbọ́n eniyan kan ranṣẹ sí wa. Ọmọ Israẹli ni, láti inú àwọn ọmọ Mahili, ninu ẹ̀yà Lefi: wọ́n fi ranṣẹ pẹlu àwọn ọmọ ati àwọn arakunrin rẹ̀. Gbogbo wọn jẹ́ mejidinlogun. 19Wọ́n tún rán Haṣabaya, òun ati Jeṣaya ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Merari; pẹlu àwọn arakunrin rẹ̀, ati àwọn ọmọ wọn. Gbogbo wọn jẹ́ ogún, 20láì tíì ka igba ó lé ogún (220) àwọn òṣìṣẹ́ tẹmpili, tí Dafidi ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ ti yà sọ́tọ̀ láti máa ran àwọn ọmọ Lefi lọ́wọ́. Gbogbo wọn ni a kọ orúkọ wọn sinu ìwé.
Ẹsira Darí Àwọn Eniyan náà ninu Ààwẹ̀ ati Adura
21Lẹ́yìn náà, mo pàṣẹ létí odò Ahafa pé kí á gbààwẹ̀, kí á lè rẹ ara wa sílẹ̀ níwájú Ọlọrun wa, kí á sì bèèrè ìtọ́sọ́nà fún ara wa ati àwọn ọmọ wa, ati gbogbo ohun ìní wa. 22Ìtìjú ni ó jẹ́ fún mi láti bèèrè fún ọ̀wọ́ ọmọ ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin tí yóo dáàbò bò wá ninu ìrìn àjò wa, nítorí mo ti sọ fún ọba pé Ọlọrun wa a máa ṣe rere fún àwọn tí wọ́n bá ń gbọ́ tirẹ̀; Ṣugbọn a máa fi ìyà jẹ gbogbo àwọn tí wọn kò bá tẹ̀lé e. 23Nítorí náà, a gba ààwẹ̀, a sì gbadura sí Ọlọ́run, ó sì gbọ́ tiwa.
Àwọn Ẹ̀bùn fún Tẹmpili náà
24Lẹ́yìn náà mo ya àwọn àgbààgbà alufaa mejila sọ́tọ̀: Ṣerebaya, Haṣabaya ati mẹ́wàá ninu àwọn arakunrin wọn. 25Mo wọn fadaka, wúrà ati àwọn ohun èlò tí ọba, ati àwọn ìgbìmọ̀ rẹ̀, ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ mú wá, ati èyí tí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wà níbẹ̀ náà mú wá fún ìlò ilé Ọlọrun. 26Mo wọn ẹgbẹta lé aadọta (650) ìwọ̀n talẹnti fadaka, ohun èlò fadaka tí a wọ̀n tó ọgọrun-un (100) ìwọ̀n talẹnti fadaka, ọgọrun-un (100) ìwọ̀n talẹnti wúrà, 27ogún àwo wúrà tí wọ́n tó ẹgbẹrun (1000) ìwọ̀n diramu ati ohun èlò idẹ meji tí ó ń dán, tí ó sì níye lórí bíi wúrà.
28Mo sọ fún wọn pé, “A yà yín ati gbogbo nǹkan wọnyi sí mímọ́ fún OLUWA. Fadaka ati wúrà jẹ́ ọrẹ àtinúwá fún OLUWA Ọlọrun àwọn baba yín. 29Ẹ máa tọ́jú wọn kí ẹ sì máa pa wọ́n mọ́ títí tí ẹ óo fi wọ̀n wọ́n níwájú àwọn olórí alufaa, àwọn ọmọ Lefi ati àwọn baálé baálé Israẹli ní Jerusalẹmu ninu yàrá ilé OLUWA.” 30Àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi gba fadaka, wúrà ati àwọn ohun èlò náà, wọ́n kó wọn wá sinu ilé Ọlọrun wa ní Jerusalẹmu.
Pípadà sí Jerusalẹmu
31Ní ọjọ́ kejila oṣù kinni ni a kúrò ní odò Ahafa à ń bọ̀ wá sí Jerusalẹmu. Ọlọrun wà pẹlu wa, ó dáàbò bò wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá ati àwọn dánàdánà. 32Nígbà tí a dé Jerusalẹmu a wà níbẹ̀ fún ọjọ́ mẹta. 33Ní ọjọ́ kẹrin, a gbéra, a lọ sí ilé Ọlọrun, a wọn fadaka, wúrà ati àwọn ohun èlò, a sì kó wọn lé Meremoti, alufaa, ọmọ Uraya lọ́wọ́. Àwọn tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ níbẹ̀ ni Eleasari, ọmọ Finehasi, pẹlu àwọn ọmọ Lefi, Josabadi, ọmọ Jeṣua, ati Noadaya, ọmọ Binui. 34A ka gbogbo wọn, a sì ṣe àkọsílẹ̀ ohun tí ìwọ̀n ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́.
35Àwọn tí wọ́n ti oko ẹrú dé fi akọ mààlúù mejila rú ọrẹ ẹbọ sísun sí Ọlọrun Israẹli fún ẹ̀yà Israẹli mejila, pẹlu àgbò mẹrindinlọgọrun-un, ọ̀dọ́ aguntan mẹtadinlọgọrun-un, ati òbúkọ mejila fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Gbogbo àwọn ẹran wọnyi jẹ́ ẹbọ sísun fún Ọlọrun. 36Wọ́n fún àwọn aláṣẹ ati àwọn gomina tí ọba yàn fún àwọn ìgbèríko tí wọ́n wà ní òdìkejì odò ní ìwé àṣẹ tí ọba pa; àwọn aláṣẹ náà sì ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wọn ati fún iṣẹ́ ilé Ọlọrun.

Currently Selected:

ẸSIRA 8: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

Videos for ẸSIRA 8