JẸNẸSISI 43
43
Àwọn Arakunrin Josẹfu Pada Lọ sí Ijipti pẹlu Bẹnjamini
1Ìyàn tí ó mú ní ilẹ̀ Kenaani ṣá túbọ̀ ń pọ̀ sí i ni. 2Nígbà tí wọ́n jẹ ọkà tí wọ́n rà ní Ijipti tán, baba wọn pè wọ́n, ó ní, “Ẹ tún wá lọ ra oúnjẹ díẹ̀ sí i.”
3Ṣugbọn Juda dá a lóhùn, ó ní, “Ọkunrin náà kìlọ̀ fún wa gidigidi pé a kò ní fi ojú kan òun láìjẹ́ pé a mú arakunrin wa lọ́wọ́. 4Bí o bá jẹ́ kí arakunrin wa bá wa lọ, a óo lọ ra oúnjẹ wá fún ọ, 5ṣugbọn bí o kò bá jẹ́ kí ó bá wa lọ, a kò ní lọ, nítorí pé ọkunrin náà tẹnumọ́ ọn fún wa pé a kò ní fi ojú kan òun láìjẹ́ pé arakunrin wa bá wa wá.”
6Israẹli ní, “Irú ọ̀ràn ńlá wo ni ẹ tún dá sí mi lọ́rùn yìí, tí ẹ lọ sọ fún ọkunrin náà pé ẹ ní arakunrin mìíràn?”
7Wọ́n dá a lóhùn pé, “Kò sí ohun tí ọkunrin náà kò bi wá tán nípa ará ati ẹbí wa, ó ní, ‘Ǹjẹ́ baba yín wà láàyè? Ǹjẹ́ ẹ tún ní arakunrin mìíràn?’ Àwọn ìbéèrè tí ó ń bèèrè ni ó mú kí á sọ ohun tí a sọ fún un. Báwo ni a ṣe lè mọ̀ pé yóo sọ pé kí á mú àbúrò wa wá?”
8Juda bá sọ fún Israẹli, ó ní, “Fa ọmọ náà lé mi lọ́wọ́, a óo sì lọ kí á lè wà láàyè, kí ebi má baà pa ẹnikẹ́ni kú ninu wa, ati àwọn ọmọ wa kéékèèké. 9N óo dúró fún ọmọ náà, ọwọ́ mi ni kí o ti bèèrè rẹ̀. Bí n kò bá mú un pada, kí n sì fà á lé ọ lọ́wọ́, da ẹ̀bi rẹ̀ lé mi lórí títí lae, 10nítorí pé bí a kò bá fi ìrìn àjò yìí falẹ̀ ni, à bá ti lọ, à bá sì ti dé, bí ẹẹmeji.”
11Israẹli, baba wọn bá sọ fún wọn pé, “Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ó dára, báyìí ni kí ẹ ṣe, ẹ dì ninu àwọn èso tí ó dára jùlọ ní ilẹ̀ yìí sinu àpò yín, kí ẹ gbé e lọ fún ọkunrin náà. Ẹ mú ìpara díẹ̀, oyin díẹ̀, turari díẹ̀ ati òjíá díẹ̀, ẹ mú èso pistakio ati èso alimọndi pẹlu. 12Ìlọ́po meji owó ọjà tí ẹ óo rà ni kí ẹ mú lọ́wọ́, ẹ mú owó tí ó wà lẹ́nu àpò yín níjelòó lọ́wọ́ pẹlu, bóyá wọ́n gbàgbé ni. 13Ẹ mú arakunrin yín náà lọ́wọ́, kí ẹ sì tọ ọkunrin náà lọ. 14Kí Ọlọrun Olodumare jẹ́ kí ọkunrin náà ṣàánú yín, kí ó sì dá arakunrin yín kan yòókù ati Bẹnjamini pada. Bí mo bá tilẹ̀ wá ṣòfò àwọn ọmọ mi nígbà náà, n óo gbà pé mo ṣòfò wọn.”
15Àwọn ọkunrin náà bá gbé ẹ̀bùn náà, wọ́n sì mú ìlọ́po meji owó tí wọ́n nílò, ati Bẹnjamini, wọ́n lọ siwaju Josẹfu ní Ijipti. 16Nígbà tí Josẹfu rí Bẹnjamini pẹlu wọn, ó sọ fún alabojuto ilé rẹ̀, ó ní, “Mú àwọn ọkunrin wọnyi wọlé, pa ẹran kan kí o sì sè é, nítorí wọn yóo bá mi jẹun lọ́sàn-án yìí.” 17Ọkunrin náà ṣe bí Josẹfu ti pàṣẹ fún un, ó sì mú àwọn ọkunrin náà wọ ilé Josẹfu lọ.
18Ẹ̀rù bẹ̀rẹ̀ sí bà wọ́n nígbà tí Josẹfu mú wọn wọ ilé rẹ̀, wọ́n ń wí fún ara wọn pé, “Nítorí owó tí wọ́n fi sí ẹnu àpò wa níjelòó ni wọ́n fi kó wa wọlé, kí ó lè rí ẹ̀sùn kà sí wa lẹ́sẹ̀, kí ó lè fi wá ṣe ẹrú, kí ó sì kó àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wa.” 19Wọ́n bá tọ alabojuto ilé Josẹfu lọ lẹ́nu ọ̀nà, 20wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀bẹ̀, wọ́n ní, “Jọ̀wọ́ oluwa mi, a ti kọ́kọ́ wá ra oúnjẹ níhìn-ín nígbà kan. 21Nígbà tí à ń pada lọ tí a dé ibi tí a fẹ́ sùn, a tú àpò wa, olukuluku wa bá owó tirẹ̀ lẹ́nu àpò rẹ̀, kò sí ti ẹni tí ó dín rárá, a mú owó náà lọ́wọ́ báyìí. 22A sì tún mú owó mìíràn lọ́wọ́ pẹlu láti ra oúnjẹ. A kò mọ ẹni tí ó dá owó wa pada sinu àpò wa.”
23Ó dá wọn lóhùn, ó ní, “Ẹ fọkàn yín balẹ̀, ẹ má bẹ̀rù, ó níláti jẹ́ pé Ọlọrun yín ati ti baba yín ni ó fi owó náà sinu àpò yín fun yín, mo gba owó lọ́wọ́ yín.” Ó bá mú Simeoni jáde sí wọn.
24Ọkunrin náà mú wọn wọ inú ilé Josẹfu, ó fún wọn ní omi, wọ́n fọ ẹsẹ̀ wọn, wọ́n sì fún àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn ní oúnjẹ. 25Lẹ́yìn náà wọ́n tọ́jú ẹ̀bùn Josẹfu sílẹ̀ di ìgbà tí yóo dé lọ́sàn-án, nítorí wọ́n gbọ́ pé ibẹ̀ ni wọn yóo ti jẹun. 26Nígbà tí Josẹfu wọlé, wọ́n mú ẹ̀bùn tí wọ́n mú bọ̀ fún un wọlé tọ̀ ọ́ lọ, wọ́n sì wólẹ̀ fún un, wọ́n dojúbolẹ̀. 27Ó bèèrè alaafia wọn, ó ní, “Ṣé alaafia ni baba yín wà, arúgbó tí ẹ sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún mi? Ṣé ó ṣì wà láàyè?”
28Wọ́n dá a lóhùn, wọ́n ní, “Baba wa, iranṣẹ rẹ ń bẹ láàyè, ó sì wà ní alaafia.” Wọ́n tẹríba, wọ́n bu ọlá fún un. 29Ojú tí ó gbé sókè, ó rí Bẹnjamini ọmọ ìyá rẹ̀, ó bá bèèrè pé, “Ṣé arakunrin yín tí í ṣe àbíkẹ́yìn tí ẹ wí nìyí? Kí Ọlọrun fi ojurere wò ọ́, ọmọ mi.” 30Josẹfu bá yára jáde kúrò lọ́dọ̀ wọn nítorí pé ọkàn rẹ̀ fà sí àbúrò rẹ̀, orí rẹ̀ sì wú, ó wá ibìkan láti lọ sọkún. Ó bá wọ yàrá rẹ̀, ó lọ sọkún níbẹ̀. 31Lẹ́yìn náà ó bọ́ ojú rẹ̀, ó jáde, ó gbìyànjú, ó dárayá, ó ní, “Ẹ gbé oúnjẹ wá.” 32Wọ́n gbé oúnjẹ tirẹ̀ kalẹ̀ lọ́tọ̀, ti àwọn arakunrin rẹ̀ lọ́tọ̀, ati ti àwọn ará Ijipti tí wọn ń bá a jẹun lọ́tọ̀, nítorí pé ìríra ni ó jẹ́ fún àwọn ará Ijipti láti bá àwọn Heberu jẹun pọ̀. 33Àwọn arakunrin Josẹfu jókòó níwájú rẹ̀, wọ́n tò wọ́n gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ orí wọn, láti orí ẹ̀gbọ́n patapata dé orí àbúrò patapata. Nígbà tí àwọn arakunrin Josẹfu rí i bí wọ́n ti tò wọ́n, wọ́n ń wo ara wọn lójú tìyanu-tìyanu. 34Láti orí tabili Josẹfu ni wọ́n ti bu oúnjẹ fún olukuluku, ṣugbọn oúnjẹ ti Bẹnjamini tó ìlọ́po marun-un ti ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn. Wọ́n bá a jẹ, wọ́n mu, wọ́n sì bá a ṣe àríyá.
Currently Selected:
JẸNẸSISI 43: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010