JẸNẸSISI 45
45
Josẹfu Farahan Àwọn Arakunrin Rẹ̀
1Josẹfu kò lè mú ọ̀rọ̀ yìí mọ́ra mọ́ lójú gbogbo àwọn tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀, ó bá kígbe, ó ní, “Gbogbo yín patapata, ẹ jáde kúrò lọ́dọ̀ mi.” Nítorí náà, kò sí ẹnikẹ́ni lọ́dọ̀ Josẹfu nígbà tí ó fi ara rẹ̀ han àwọn arakunrin rẹ̀ pé òun ni Josẹfu.#A. Apo 7:13. 2Ó bú sẹ́kún, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí pohùnréré ẹkún tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn ará Ijipti ati gbogbo ilé Farao gbọ́ ẹkún rẹ̀. 3Josẹfu sọ fún àwọn arakunrin rẹ̀ pé òun ni Josẹfu. Ó bi wọ́n léèrè pé ǹjẹ́ baba òun ṣì wà láàyè. Ṣugbọn jìnnìjìnnì dà bo àwọn arakunrin rẹ̀ níwájú rẹ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí wọn kò lè dáhùn. 4Josẹfu bá bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀ wọ́n, ó ní kí wọ́n jọ̀wọ́, kí wọ́n súnmọ́ òun. Ó tún wí fún wọn pé òun ni Josẹfu arakunrin wọn, tí wọ́n tà sí Ijipti. 5Ó ní, “Ẹ má wulẹ̀ dààmú ẹ̀mí ara yín, ẹ má sì bínú sí ara yín pé ẹ tà mí síhìn-ín. Ọlọrun fúnrarẹ̀ ni ó rán mi ṣáájú yín láti gba ẹ̀mí là. 6Nítorí ó ti di ọdún keji tí ìyàn yìí ti bẹ̀rẹ̀ ní ilẹ̀ yìí, ó sì ku ọdún marun-un gbáko tí kò fi ní sí ìfúrúgbìn tabi ìkórè. 7Ọlọrun ni ó rán mi ṣáájú yín láti dá yín sí, ati láti gba ọpọlọpọ ẹ̀mí là ninu ìran yín. 8Nítorí náà, kì í ṣe ẹ̀yin ni ẹ gbé mi dé ìhín, Ọlọrun ni, ó sì ti fi mí ṣe baba fún Farao, ati oluwa ninu gbogbo ilé rẹ̀ ati alákòóso gbogbo ilẹ̀ Ijipti.
9“Ẹ ṣe kíá, ẹ wá lọ sọ́dọ̀ baba mi kí ẹ wí fún un pé, Josẹfu ọmọ rẹ̀ wí pé, Ọlọrun ti fi òun ṣe olórí ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti, ẹ ní mo ní kí ó máa bọ̀ lọ́dọ̀ mi kíákíá. 10Ẹ sọ fún un pé mo sọ pé kí ó wá máa gbé ní ilẹ̀ Goṣeni nítòsí mi, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀, ati àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀, ati agbo mààlúù rẹ̀, ati ohun gbogbo tí ó ní. 11N óo máa tọ́jú rẹ̀ níbẹ̀, nítorí pé ó tún ku ọdún marun-un gbáko kí ìyàn yìí tó kásẹ̀ nílẹ̀, kí òun ati ìdílé rẹ̀ ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ má baà di aláìní.#A. Apo 7:14.
12“Ẹ̀yin pàápàá fi ojú rí i, Bẹnjamini arakunrin mi náà sì rí i pẹlu pé èmi gan-an ni mò ń ba yín sọ̀rọ̀. 13Ẹ níláti sọ fún baba mi nípa gbogbo ògo mi ní Ijipti, ati gbogbo ohun tí ẹ ti rí. Ẹ tètè yára mú baba mi wá bá mi níhìn-ín.”
14Ó bá rọ̀ mọ́ Bẹnjamini arakunrin rẹ̀ lọ́rùn, ó sì bú sẹ́kún, bí Bẹnjamini náà ti rọ̀ mọ́ ọn, ni òun náà bú sẹ́kún. 15Josẹfu bá fi ẹnu ko àwọn arakunrin rẹ̀ lẹ́nu lọ́kọ̀ọ̀kan, ó sì sọkún, lẹ́yìn náà ni àwọn arakunrin rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí bá a sọ̀rọ̀.
16Nígbà tí gbogbo ìdílé Farao gbọ́ pé àwọn arakunrin Josẹfu dé, inú Farao ati àwọn iranṣẹ rẹ̀ dùn pupọ. 17Farao sọ fún Josẹfu pé kí ó sọ fún àwọn arakunrin rẹ̀ kí wọ́n múra, kí wọ́n di ẹrù ru àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn, kí wọ́n tètè pada lọ sí Kenaani, 18kí wọ́n sì lọ mú baba rẹ̀ ati gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀ wá sọ́dọ̀ òun. Ó ní òun óo fún un ní ibi tí ó dára jùlọ ní ilẹ̀ Ijipti, wọn yóo sì jẹ àjẹyó ninu ilẹ̀ náà. 19Ó ní kí Josẹfu pàṣẹ fún wọn pẹlu kí wọ́n kó kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́ṣin láti ilẹ̀ Ijipti, láti fi kó àwọn ọmọde ati àwọn obinrin, kí baba wọn náà sì máa bá wọn bọ̀. 20Ó ní kí wọ́n má ronú àwọn dúkìá wọn nítorí àwọn ni wọn yóo ni ilẹ̀ tí ó dára jù ní Ijipti.
21Àwọn ọmọ Israẹli ṣe bí ọba ti wí, Josẹfu fún wọn ní kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́ṣin gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Farao, ó sì fún wọn ní oúnjẹ tí wọn yóo máa jẹ lọ́nà. 22Ó fún olukuluku wọn ní ìpààrọ̀ aṣọ kọ̀ọ̀kan, ṣugbọn ó fún Bẹnjamini ní ọọdunrun (300) ṣekeli fadaka ati ìpààrọ̀ aṣọ marun-un. 23Ó di àwọn nǹkan dáradára ilẹ̀ Ijipti ru kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mẹ́wàá, ó di ọkà ati oúnjẹ ru abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mẹ́wàá, ó kó wọn ranṣẹ sí baba rẹ̀ pé kí ó rí ohun máa jẹ bọ̀ lọ́nà. 24Ó bá ní kí àwọn arakunrin òun máa lọ, bí wọ́n sì ti fẹ́ máa lọ, ó kìlọ̀ fún wọn pé kí wọ́n má bá ara wọn jà lọ́nà.
25Wọ́n bá kúrò ní Ijipti, wọ́n pada sọ́dọ̀ Jakọbu baba wọn ní ilẹ̀ Kenaani. 26Wọ́n sọ fún un pé, “Josẹfu kò kú, ó wà láàyè, ati pé òun ni alákòóso gbogbo ilẹ̀ Ijipti.” Nígbà tí ó gbọ́ bẹ́ẹ̀, orí rẹ̀ fò lọ fee, kò kọ́ gbà wọ́n gbọ́.
27Ṣugbọn nígbà tí ó gbọ́ gbogbo ohun tí Josẹfu wí fún wọn, tí ó tún rí kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́ṣin tí Josẹfu fi ranṣẹ pé kí wọ́n fi gbé òun wá, ara rẹ̀ wálẹ̀. 28Israẹli bá dáhùn, ó ní, “Josẹfu, ọmọ mi wà láàyè! Ó ti parí, n óo lọ fi ojú kàn án kí n tó kú.”
Currently Selected:
JẸNẸSISI 45: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010