HEBERU 4
4
1Nítorí náà níwọ̀n ìgbà tì ìlérí àtiwọ inú ìsinmi rẹ̀ tún wà, ẹ jẹ́ kí á ṣọ́ra gidigidi kí ẹnikẹ́ni ninu yín má baà kùnà láti wọ̀ ọ́. 2Nítorí àwa náà ti gbọ́ ìyìn rere bí àwọn tọ̀hún ti gbọ́. Ṣugbọn ọ̀rọ̀ tí àwọn gbọ́ kò ṣe wọ́n ní anfaani, nítorí wọn kò ní igbagbọ ninu ohun tí wọ́n gbọ́. 3Àwa tí a gbàgbọ́ ni a wọ inú ìsinmi náà. Nígbà tí Ọlọrun sọ pé,
“Mo búra pẹlu ibinu pé,
wọn kò ní wọ inú ìsinmi mi.”
Ó sọ bẹ́ẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti parí iṣẹ́ rẹ̀ láti ìpìlẹ̀ ayé.#O. Daf 95:11 4Nítorí Ìwé Mímọ́ sọ níbìkan nípa ọjọ́ keje pé, “Ọlọrun sinmi ninu gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ ní ọjọ́ keje.”#Jẹn 2:2 5Lẹ́ẹ̀kan sí i, ohun tí ó sọ ní ibí yìí ni pé, “Wọn kò ní wọ inú ìsinmi mi.”#O. Daf 95:11 6Nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn ará àtijọ́ tí wọ́n gbọ́ ìyìn rere kò wọ inú ìsinmi náà nítorí àìgbọràn, nítorí náà ó ku àwọn kan tí wọn yóo wọ inú rẹ̀. 7Ọlọrun wá tún yan ọjọ́ mìíràn. Ninu ìwé Dafidi, tí ó kọ lẹ́yìn ọdún pupọ, ó sọ pé, “Lónìí”, níbi tí atọ́ka sí, tí ó kà báyìí pé,
“Lónìí, bí ẹ bá gbọ́ ohùn rẹ̀,
Ẹ má ṣe agídí.”#O. Daf 95:7-8
8Bí ó bá jẹ́ pé Joṣua fún wọn ní ìsinmi ni, Ọlọrun kò ní tún sọ nípa ọjọ́ mìíràn mọ́ lẹ́yìn ọjọ́ pupọ.#Diut 31:7; Joṣ 22:4 9Nítorí náà, ìsinmi ọjọ́ ìsinmi wà nílẹ̀ fún àwọn eniyan Ọlọrun. 10Nítorí ẹni tí ó bá wọ inú ìsinmi rẹ̀ ti sinmi ninu iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti sinmi ninu tirẹ̀.#Jẹn 2:2 11Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á sa gbogbo ipá wa láti wọ inú ìsinmi náà, kí ẹnikẹ́ni má tẹ̀lé àpẹẹrẹ burúkú ati àìgbọràn bíi ti àwọn tí à ń sọ̀rọ̀ wọn.
12Nítorí pé ọ̀rọ̀ Ọlọrun wà láàyè, ó sì lágbára. Ó mú ju idà olójú meji lọ. Ó mú tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi lè gé ẹ̀mí kúrò lára ọkàn, ó sì lè rẹ́ mùdùnmúdùn kúrò lára àwọn oríkèé ara. Ó yára láti mọ ète ati èrò ọkàn eniyan. 13Kò sí ẹ̀dá kan tí ó lè fara pamọ́ níwájú rẹ̀. Gbogbo nǹkan ṣípayá kedere níwájú Ọlọrun, ẹni tí a óo jíyìn iṣẹ́ wa fún.#Ọgb 1:6
Jesu Olórí Alufaa Ńlá
14Nítorí náà, níwọ̀n ìgbà tí a ní Olórí Alufaa ńlá tí ó ti kọjá lọ sí ọ̀run tíí ṣe Jesu Ọmọ Ọlọrun, ẹ jẹ́ kí á di ohun ti a fi igbagbọ jẹ́wọ́ mú ṣinṣin. 15Nítorí Olórí Alufaa tí a ní kì í ṣe ẹni tí kò lè bá wa kẹ́dùn ninu àwọn àìlera wa. Ṣugbọn ó jẹ́ ẹni tí a ti dán wò ní gbogbo ọ̀nà bíi wa, ṣugbọn òun kò dẹ́ṣẹ̀. 16Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á fi ìgboyà súnmọ́ ìtẹ́ oore-ọ̀fẹ́, kí á lè rí àánú gbà, ati nípa oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, kí á lè rí ìrànlọ́wọ́ ní àkókò tí ó wọ̀.
Currently Selected:
HEBERU 4: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

: