YouVersion Logo
Search Icon

HEBERU 5

5
1Nítorí ẹnikẹ́ni tí a bá yàn láàrin àwọn eniyan láti jẹ́ olórí alufaa, a yàn án bí aṣojú àwọn eniyan níwájú Ọlọrun, kí ó lè máa mú àwọn ọrẹ ati ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn wá siwaju Ọlọrun. 2Ó lè fi sùúrù bá àwọn tí wọ́n ṣìnà nítorí wọn kò gbọ́ lò, nítorí pé eniyan aláìlera ni òun náà. 3Nítorí èyí, bí ó ti ń rúbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan, bẹ́ẹ̀ ni yóo máa rúbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ ti òun alára.#Lef 9:7 4Kò sí ẹni tíí yan ara rẹ̀ sí ipò yìí. Ṣugbọn àwọn tí Ọlọrun bá pè ni à ń yàn, bíi Aaroni.#Eks 28:1
5Bẹ́ẹ̀ gan-an ni, Kristi náà kò yan ògo yìí fúnrarẹ̀, láti jẹ́ olórí alufaa. Ọlọrun ni ó yàn án. Ọlọrun ni ó sọ fún un pé,
“Ìwọ ni Ọmọ mi,
lónìí ni mo bí ọ.”#O. Daf 2:7
6Bẹ́ẹ̀ náà ni ó sọ ní ibòmíràn pé,
“Alufaa ni ọ́ títí laelae
gẹ́gẹ́ bíi ti Mẹlikisẹdẹki.”#O. Daf 110:4
7Ní ìgbà ayé Jesu, pẹlu igbe ńlá ati ẹkún, ó fi adura ati ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ siwaju ẹni tí ó lè gbà á lọ́wọ́ ikú. Nítorí pé ó bọ̀wọ̀ fún Ọlọrun, adura rẹ̀ gbà.#Mat 26:36-46; Mak 14:32-42; Luk 22:39-46 8Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọmọ ni, ó kọ́ láti gbọ́ràn nípa ìyà tí ó jẹ. 9Nígbà tí a ti ṣe é ní àṣepé, ó wá di orísun ìgbàlà tí kò lópin fún gbogbo àwọn tí wọ́n bá gbà á gbọ́. 10Òun ni Ọlọrun pè ní olórí alufaa gẹ́gẹ́ bíi ti Mẹlikisẹdẹki.
Ìkìlọ̀ nípa Àwọn tí Ó Kúrò ninu Ẹ̀sìn Igbagbọ
11A ní ọ̀rọ̀ pupọ láti sọ fun yín nípa Mẹlikisẹdẹki yìí. Ọ̀rọ̀ náà ṣòro láti túmọ̀ nígbà tí ọkàn yín ti le báyìí. 12Nítorí ó ti yẹ kí ẹ di olùkọ́ni ní ọjọ́ tí ó ti pẹ́. Sibẹ ẹ tún wà ninu àwọn tí a óo máa kọ́ ní “A, B, D,” nípa nǹkan tí ó jẹ mọ́ ti Ọlọrun. Ẹ wà ninu àwọn tí a óo máa fi wàrà bọ́, ẹ kò ì tíì lè jẹ oúnjẹ gidi.#1 Kọr 3:2 13Nítorí gbogbo àwọn tí wọ́n bá sì ń mu wàrà, kò tíì mọ ẹ̀kọ́ nípa òdodo, nítorí ọmọ-ọwọ́ ni irú wọn. 14Ṣugbọn oúnjẹ gidi ni àgbàlagbà máa ń jẹ, àwọn tí ìrírí wọn fún ọjọ́ pípẹ́ ti fún ní òye láti mọ ìyàtọ̀ láàrin nǹkan rere ati nǹkan burúkú.

Currently Selected:

HEBERU 5: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in