YouVersion Logo
Search Icon

AISAYA 50

50
1OLUWA ní:#Bar 4:6
OLUWA ní:
“Ìwé ìkọ̀sílẹ̀ tí mo fi kọ àwọn eniyan mi sílẹ̀ dà?
Ta ni mo tà yín fún,
tí mo jẹ lówó?
Ẹ wò ó! Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín ni a ṣe tà yín,
nítorí àìdára yín ni mo ṣe kọ̀ yín sílẹ̀.
2“Kí ló dé tí mo wá àwọn eniyan mi tí n kò rí ẹnìkan;
mo pè, ẹnikẹ́ni kò dá mi lóhùn?
Ṣé n kò lágbára tó láti rà wọ́n pada ni;
àbí n kò lágbára láti gba ni là?
Wò ó! Ìbáwí lásán ni mo fi gbẹ́ omi òkun,
tí mo sì fi sọ odò tí ń ṣàn di aṣálẹ̀,
omi wọn gbẹ,
òùngbẹ gbẹ àwọn ẹja inú wọn pa,
wọ́n kú, wọ́n sì ń rùn.
3Mo da òkùnkùn bo ojú ọ̀run bí aṣọ,
mo ṣe aṣọ ọ̀fọ̀ ní ìbora fún wọn.”
Ìgbọràn Iranṣẹ OLUWA
4OLUWA Ọlọrun ti fi ọ̀rọ̀ ìmọ̀ sí mi lẹ́nu.
Kí n lè mọ bí a tií gba àwọn tí ọkàn wọn rẹ̀wẹ̀sì níyànjú.
Ojoojumọ ni ó ń ṣí mi létí láràárọ̀,
kí n lè máa gbọ́rọ̀ bí àwọn akẹ́kọ̀ọ́.
5OLUWA Ọlọrun ti ṣí mi létí,
n kò sì ṣe oríkunkun,
tabi kí n pada sẹ́yìn.
6Mo tẹ́ ẹ̀yìn sílẹ̀ fún àwọn tí ń nani lẹ́gba;#Mat 26:67; Mak 14:65
mo sì kọ ẹ̀rẹ̀kẹ́ sí àwọn tí ń fa eniyan ní irùngbọ̀n tu.
N kò fojú pamọ́ nítorí ẹ̀gàn,
bẹ́ẹ̀ ni n kò gbójú sá fún itọ́ títu síni lójú.
7OLUWA Ọlọrun ń ràn mí lọ́wọ́,
nítorí náà ojú kò tì mí;
nítorí náà mo múra gírí,
mo jẹ́ kí ojú mi le koko,
mo sì mọ̀ pé ojú kò ní tì mí.
8Ẹni tí yóo dá mi láre wà nítòsí,
ta ló fẹ́ bá mi jà?
Ta ló fẹ́ fi ẹ̀sùn kàn mí?
Kí olúwarẹ̀ súnmọ́ tòsí mi,
kí á jọ kojú ara wa?
9Wò ó! OLUWA Ọlọrun ń ràn mí lọ́wọ́,#Rom 8:33-34
ta ni yóo dá mi lẹ́bi?
Gbogbo wọn ni yóo gbọ̀n dànù bí aṣọ,
kòkòrò yóo sì jẹ wọ́n.
10Ta ló bẹ̀rù OLUWA ninu yín,
tí ń gbọ́ràn sí iranṣẹ rẹ̀ lẹ́nu,
tí ń rìn ninu òkùnkùn,
tí kò ní ìmọ́lẹ̀,
ṣugbọn sibẹ, tí ó gbẹ́kẹ̀lé OLUWA,
tí ó fẹ̀yìn ti Ọlọrun rẹ̀.
11Gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń dáná,
tí ẹ tan iná yí ara yín ká,
ẹ máa rìn lọ ninu iná tí ẹ dá;
ẹ máa la iná tí ẹ fi yí ara yín ká kọjá.
Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe fun yín.
Ẹ óo wà ninu ìrora.

Currently Selected:

AISAYA 50: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in