ÀWỌN ADÁJỌ́ 13
13
Ìbí Samsoni
1Àwọn ọmọ Israẹli tún ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA, OLUWA sì fi wọ́n lé àwọn ará Filistia lọ́wọ́. Wọ́n sin àwọn ará Filistia fún ogoji ọdún.
2Ọkunrin kan wà, ará Sora, láti inú ẹ̀yà Dani, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Manoa; àgàn ni iyawo rẹ̀, kò bímọ. 3Nígbà tí ó di ọjọ́ kan, angẹli OLUWA fi ara han iyawo Manoa yìí, ó wí fún un pé, “Lóòótọ́, àgàn ni ọ́, ṣugbọn o óo lóyún, o óo sì bí ọmọkunrin kan. 4Nítorí náà, ṣọ́ra, o kò gbọdọ̀ mu ọtí waini tabi ọtí líle, bẹ́ẹ̀ ni o kò gbọdọ̀ jẹ ohunkohun tí ó jẹ́ aláìmọ́. 5Nítorí pé, o óo lóyún, o óo sì bí ọmọkunrin kan. Abẹ kò gbọdọ̀ kan orí rẹ̀, nítorí pé, Nasiri Ọlọrun ni yóo jẹ́ láti ọjọ́ ìbí rẹ̀; òun ni yóo sì gba Israẹli sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Filistia.”#Nọm 6:1-5.
6Obinrin náà bá lọ sọ fún ọkọ rẹ̀, ó ní, “Eniyan Ọlọrun kan tọ̀ mí wá, ìrísí rẹ̀ jọ ìrísí angẹli Ọlọrun. Ó bani lẹ́rù gidigidi. N kò bèèrè ibi tí ó ti wá, kò sì sọ orúkọ ara rẹ̀ fún mi. 7Ṣugbọn ó wí fún mi pé, n óo lóyún, n óo sì bí ọmọkunrin kan. Ó ní n kò gbọdọ̀ mu ọtí waini, tabi ọtí líle. N kò sì gbọdọ̀ jẹ ohunkohun tí ó jẹ́ aláìmọ́; nítorí pé, Nasiri Ọlọrun ni ọmọ náà yóo jẹ́ láti ọjọ́ ìbí rẹ̀ títí yóo fi jáde láyé.”
8Manoa bá gbadura sí OLUWA, ó ní, “OLUWA, jọ̀wọ́ jẹ́ kí iranṣẹ rẹ tí o rán sí wa tún pada wá, kí ó wá kọ́ wa bí a óo ṣe máa tọ́jú ọmọkunrin tí a óo bí.”
9Ọlọrun gbọ́ adura Manoa, angẹli Ọlọrun náà tún pada tọ obinrin yìí wá níbi tí ó jókòó sí ninu oko; ṣugbọn Manoa, ọkọ rẹ̀, kò sí lọ́dọ̀ rẹ̀. 10Obinrin náà bá sáré lọ sọ fún ọkọ rẹ̀, ó ní, “Ẹni tí ó wá sọ́dọ̀ mi níjọ́sí tún ti fara hàn mí.”
11Manoa bá gbéra, ó bá tẹ̀lé iyawo rẹ̀ lọ sọ́dọ̀ ọkunrin náà, ó bi í pé, “Ṣé ìwọ ni o bá obinrin yìí sọ̀rọ̀?”
Ọkunrin náà dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni.”
12Manoa tún bèèrè pé, “Nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ bá ṣẹ, báwo ni ìgbé ayé ọmọ náà yóo rí? Irú kí ni yóo sì máa ṣe?”
13Angẹli OLUWA náà dá Manoa lóhùn, ó ní, “Gbogbo ohun tí mo sọ fún obinrin yìí ni kí o kíyèsí. 14Kò gbọdọ̀ fẹnu kan ohunkohun tí ó bá jáde láti inú èso àjàrà, kò gbọdọ̀ mu waini tabi ọtí líle tabi kí ó jẹ ohunkohun tí ó jẹ́ aláìmọ́. Gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún un ni kí ó ṣe.”
15Manoa dá angẹli OLUWA náà lóhùn, ó ní, “Jọ̀wọ́, dúró díẹ̀ kí á se ọmọ ewúrẹ́ kan fún ọ.”
16Angẹli OLUWA náà dá Manoa lóhùn, ó ní, “Bí o bá dá mi dúró, n kò ní jẹ ninu oúnjẹ rẹ, ṣugbọn tí o bá fẹ́ tọ́jú ohun tí o fẹ́ fi rú ẹbọ sísun, OLUWA ni kí o rú u sí.” Manoa kò mọ̀ pé angẹli OLUWA ni.
17Manoa bá bèèrè lọ́wọ́ angẹli OLUWA náà, ó ní, “Kí ni orúkọ rẹ kí á lè dá ọ lọ́lá nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ bá ṣẹ.”
18Angẹli OLUWA náà dáhùn pé, “Kí ló dé tí o fi ń bèèrè orúkọ mi nígbà tí ó jẹ́ pé ìyanu ni?”
19Manoa bá mú ọmọ ewúrẹ́ náà, pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ, ó fi wọ́n rúbọ lórí òkúta kan sí OLUWA tí ń ṣe iṣẹ́ ìyanu. 20Nígbà tí ọwọ́ iná ẹbọ náà bẹ̀rẹ̀ sí yọ sókè láti orí pẹpẹ, angẹli OLUWA náà bẹ̀rẹ̀ sí gòkè lọ ninu ọwọ́ iná orí pẹpẹ náà, bí Manoa ati iyawo rẹ̀ ti ń wò ó. Wọ́n bá dojú wọn bolẹ̀. 21Angẹli OLUWA náà kò tún fara han Manoa ati iyawo rẹ̀ mọ́. Manoa wá mọ̀ nígbà náà pé, angẹli OLUWA ni.
22Manoa bá sọ fún iyawo rẹ̀ pé, “Dájúdájú, a óo kú, nítorí pé a ti rí Ọlọrun.”
23Ṣugbọn iyawo rẹ̀ dá a lóhùn pé, “Bí ó bá ṣe pé OLUWA fẹ́ pa wá ni, kò ní gba ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ tí a rú sí i lọ́wọ́ wa, bẹ́ẹ̀ ni kò ní fi nǹkan wọnyi hàn wá, tabi kí ó sọ wọ́n fún wa.”
24Nígbà tí ó yá, obinrin náà bí ọmọkunrin kan, ó sì sọ ọ́ ní Samsoni. Ọmọ náà bẹ̀rẹ̀ sí dàgbà, OLUWA sì bukun un. 25Ẹ̀mí OLUWA sì bẹ̀rẹ̀ sí lò ó ní Mahanedani, tí ó wà láàrin Sora ati Eṣitaolu.
Currently Selected:
ÀWỌN ADÁJỌ́ 13: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010