ÀWỌN ADÁJỌ́ 7
7
Gideoni Ṣẹgun Àwọn Ará Midiani
1Nígbà tí ó yá, Gideoni, tí àdàpè rẹ̀ ń jẹ́ Jerubaali, ati àwọn eniyan tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ gbéra ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ kan, wọ́n lọ pàgọ́ sí ẹ̀gbẹ́ odò Harodu. Àgọ́ ti àwọn ará Midiani wà ní apá ìhà àríwá wọn ní àfonífojì lẹ́bàá òkè More.
2OLUWA wí fún Gideoni pé, “Àwọn tí wọ́n wà pẹlu rẹ ti pọ̀jù fún mi, láti fi àwọn ará ilẹ̀ Midiani lé lọ́wọ́, kí àwọn ọmọ Israẹli má baà gbéraga pé agbára wọn ni wọ́n fi ṣẹgun, wọn kò sì ní fi ògo fún mi. 3Nítorí náà, kéde fún gbogbo wọn pé, kí ẹnikẹ́ni tí ẹ̀rù bá ń bà pada sí ilé.” Gideoni bá dán wọn wò lóòótọ́, ọ̀kẹ́ kan ati ẹgbaa (22,000) ọkunrin ninu wọn sì pada sí ilé. Àwọn tí wọ́n kù jẹ́ ẹgbaarun (10,000).#Diut 20:8.
4OLUWA tún wí fún Gideoni pé, “Àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù yìí pọ̀jù sibẹsibẹ. Kó wọn lọ sí etí odò, n óo sì bá ọ dán wọn wò níbẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí mo bá wí fún ọ pé yóo lọ, òun ni yóo lọ, ẹnikẹ́ni tí mo bá sì wí fún ọ pé kò ní lọ, kò gbọdọ̀ lọ.” 5Gideoni bá kó àwọn eniyan náà lọ sí etí odò, OLUWA bá wí fún Gideoni pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ahọ́n lá omi gẹ́gẹ́ bí ajá, yọ ọ́ sọ́tọ̀ sí ẹ̀gbẹ́ kan, bákan náà ni kí o ṣe ẹnikẹ́ni tí ó bá kúnlẹ̀ kí ó tó mu omi. 6Àwọn tí wọ́n fi ọwọ́ bomi, tí wọ́n sì fi ahọ́n lá a bí ajá jẹ́ ọọdunrun (300), gbogbo àwọn yòókù ni wọ́n kúnlẹ̀ kí wọ́n tó mu omi. 7OLUWA bá wí fún Gideoni pé, “Àwọn ọọdunrun (300) tí wọ́n fi ahọ́n lá omi ni n óo lò láti gbà yín là, n óo sì fi àwọn ará Midiani lé ọ lọ́wọ́. Jẹ́ kí àwọn yòókù pada sí ilé wọn.” 8Gideoni bá gba oúnjẹ àwọn eniyan náà ati fèrè ogun wọn lọ́wọ́ wọn, ó sì sọ fún wọn pé kí wọ́n pada sí ilé, ṣugbọn ó dá àwọn ọọdunrun (300) náà dúró. Àgọ́ àwọn ọmọ ogun Midiani wà ní àfonífojì lápá ìsàlẹ̀ ibi tí wọ́n wà.
9OLUWA sọ fún un ní òru ọjọ́ kan náà pé, “Gbéra, lọ gbógun ti àgọ́ náà, nítorí pé mo ti fi lé ọ lọ́wọ́. 10Ṣugbọn bí ẹ̀rù bá ń bà ọ láti lọ, mú Pura iranṣẹ rẹ, kí ẹ jọ lọ sí ibi àgọ́ náà. 11O óo gbọ́ ohun tí wọ́n ń sọ, lẹ́yìn náà, o óo ní agbára láti lè gbógun ti àgọ́ náà.” Gideoni bà mú Pura, iranṣẹ rẹ̀, wọ́n jọ lọ sí ìpẹ̀kun ibi tí àwọn tí wọ́n di ihamọra ogun ninu àgọ́ wọn wà. 12Àwọn ará ilẹ̀ Midiani ati ti Amaleki ati àwọn ará ilẹ̀ tí ó wà ní ìlà oòrùn pọ̀ nílẹ̀ lọ bí eṣú àwọn ràkúnmí wọn kò níye, wọ́n pọ̀ bí iyanrìn etí òkun.
13Nígbà tí Gideoni dé ibẹ̀, ó gbọ́ tí ẹnìkan ń rọ́ àlá tí ó lá fún ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kan pé, “Mo lá àlá kan, mo rí i tí àkàrà ọkà baali kan ré bọ́ sinu ibùdó àwọn ará Midiani. Bí ó ti bọ́ lu àgọ́ náà, ó wó o lulẹ̀, ó sì dojú rẹ̀ délẹ̀, àgọ́ náà sì tẹ́ sílẹ̀ pẹrẹsẹ.”
14Ẹnìkejì rẹ̀ dá a lóhùn, ó ní, “Èyí kì í ṣe ohun mìíràn, bíkòṣe idà Gideoni, ọmọ Joaṣi, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Israẹli. Ọlọrun ti fi Midiani ati gbogbo ọmọ ogun rẹ̀ lé e lọ́wọ́.”
15Nígbà tí Gideoni gbọ́ bí ó ti rọ́ àlá yìí, ati ìtumọ̀ rẹ̀, ó yin OLUWA. Ó pada sí ibùdó Israẹli, ó ní, “Ẹ dìde, nítorí OLUWA ti fi àwọn ọmọ ogun Midiani le yín lọ́wọ́.” 16Ó pín àwọn ọọdunrun (300) náà sí ọ̀nà mẹta, ó fi fèrè ogun ati ìkòkò òfìfo tí wọn fi ògùṣọ̀ sí ninu lé ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn lọ́wọ́. 17Ó wí fún wọn pé, “Ẹ máa wò mí, kí ẹ sì máa ṣe bí mo bá ti ń ṣe. Nígbà tí mo bá dé ìkangun àgọ́ náà, ẹ ṣe bí mo bá ti ṣe. 18Nígbà tí èmi ati àwọn tí wọ́n wà lọ́dọ̀ mi bá fọn fèrè, ẹ̀yin náà ẹ fọn fèrè tiyín ní gbogbo àyíká àgọ́ náà, ẹ óo sì pariwo pé, ‘Fún OLUWA, ati fún Gideoni.’ ”
19Gideoni ati ọgọrun-un eniyan tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ bá lọ sí ìkangun àgọ́ náà ní òru, nígbà tí àwọn olùṣọ́ mìíràn ṣẹ̀ṣẹ̀ gba ipò àwọn tí wọ́n wà níbẹ̀ tẹ́lẹ̀. Wọ́n fọn fèrè, wọ́n sì fọ́ àwọn ìkòkò tí ó wà lọ́wọ́ wọn mọ́lẹ̀. 20Àwọn ẹgbẹ́ mẹtẹẹta fọn fèrè wọn, wọ́n sì fọ́ ìkòkò tì ó wà lọ́wọ́ wọn. Wọ́n fi iná ògùṣọ̀ wọn sí ọwọ́ òsì, wọ́n sì fi fèrè tí wọn ń fọn sí ọwọ́ ọ̀tún, wọ́n bá pariwo pé, “Idà kan fún OLUWA ati fún Gideoni.” 21Olukuluku wọn dúró sí ààyè wọn yípo àgọ́ náà, gbogbo àwọn ọmọ ogun Midiani bá bẹ̀rẹ̀ sí sá káàkiri, wọ́n ń kígbe, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ. 22Nígbà tí àwọn ọmọ ogun Gideoni fọn ọọdunrun (300) fèrè wọn, Ọlọrun mú kí àwọn ọmọ ogun ọ̀tá wọn dojú ìjà kọ ara wọn, gbogbo wọn bá bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ sí apá Serera. Wọ́n sá títí dé Beti Ṣita, ati títí dé ààlà Abeli Mehola, lẹ́bàá Tabati.
23Àwọn ọmọ ogun Israẹli pe àwọn ọkunrin Israẹli jáde láti inú ẹ̀yà Nafutali, ati ti Aṣeri ati ti Manase, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí lé àwọn ará Midiani lọ. 24Gideoni rán àwọn oníṣẹ́ jákèjádò agbègbè olókè Efuraimu, ó ní, “Ẹ máa bọ̀ wá bá àwọn ará Midiani jagun, kí ẹ sì gba ojú odò lọ́wọ́ wọn títí dé Bẹtibara ati odò Jọdani.” Wọ́n pe gbogbo àwọn ọkunrin Efuraimu jáde, wọ́n sì gba gbogbo odò títí dé Bẹtibara ati odò Jọdani pẹlu. 25Wọ́n mú Orebu ati Seebu, àwọn ọmọ ọba Midiani mejeeji, wọ́n pa Orebu sí ibi òkúta Orebu, wọ́n sì pa Seebu níbi ìfúntí Seebu, bí wọ́n ti ń lé àwọn ará Midiani lọ. Wọ́n gé orí Orebu ati ti Seebu, wọ́n sì gbé wọn wá sí ọ̀dọ̀ Gideoni ní òdìkejì odò Jọdani.
Currently Selected:
ÀWỌN ADÁJỌ́ 7: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010