JOBU 15
15
Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ Keji
(15:1–21:34)
1Elifasi ará Temani bá dáhùn pé,
2“Ṣé ọlọ́gbọ́n a máa fọ èsì tí kò mọ́gbọ́n lọ́wọ́?
Kí ó dàbí àgbá òfìfo?
3Kí ó máa jiyàn lórí ọ̀rọ̀ tí kò wúlò,
tabi ọ̀rọ̀ tí kò níláárí?
4Ṣugbọn ò ń kọ ìbẹ̀rù Ọlọrun sílẹ̀,
o sì ń dènà adura níwájú rẹ̀.
5Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ni ó ń fa irú ọ̀rọ̀ tí ń ti ẹnu rẹ jáde,
ètè rẹ sì kún fún àrékérekè.
6Ẹnu rẹ ni ó dá ọ lẹ́bi, kì í ṣe èmi;
ẹ̀rí tí ò ń jẹ́ nípa rẹ ní ń ta kò ọ́.
7“Ṣé ìwọ ni ẹni kinni tí wọ́n kọ́ bí láyé?
Tabi o ṣàgbà àwọn òkè?
8Ṣé o wà ninu ìgbìmọ̀ Ọlọrun?
Tabi ìwọ nìkan ni o rò pé o gbọ́n?
9Kí ni o mọ̀, tí àwa náà kò mọ̀?
Òye kí ni o ní, tí ó jẹ́ ohun ìpamọ́ fún àwa?
10Àwọn tí wọ́n hu ewú lórí wà láàrin wa, ati àwọn àgbàlagbà,
àwọn tí wọ́n dàgbà ju baba rẹ lọ.
11Ṣé ìtùnú Ọlọrun kò tó fún ọ ni,
àní ọ̀rọ̀ jẹ́ẹ́jẹ́ tí ó ń sọ fún ọ?
12Àgbéré kí lò ń ṣe,
tí o sì ń fi ojú burúkú wò wá.
13Tí ọkàn rẹ yipada kúrò lọ́dọ̀ Ọlọrun,
tí ò ń jẹ́ kí irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ ti ẹnu rẹ jáde?
14Kí ni eniyan jẹ́, tí ó fi lè mọ́ níwájú Ọlọrun?
Kí ni ẹnikẹ́ni tí obinrin bí já mọ́, tí ó fi lè jẹ́ olódodo?
15Wò ó, Ọlọrun kò fọkàn tán àwọn angẹli,
àwọn ọ̀run kò sì mọ́ níwájú rẹ̀.
16Kí á má tilẹ̀ wá sọ ti eniyan
tí ó jẹ́ aláìmọ́ ati ẹlẹ́gbin,
tí ń mu ẹ̀ṣẹ̀ bí ẹni mu omi!#Job 25:4-6
17“Fetí sílẹ̀, n óo sọ fún ọ,
n óo sọ ohun tí ojú mi rí,
18(ohun tí àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n sọ,
tí àwọn baba wọn kò sì fi pamọ́,
19àwọn nìkan ni a fún ní ilẹ̀ náà,
àlejò kankan kò sì sí láàrin wọn).
20Ẹni ibi ń yí ninu ìrora ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀,
àní, ní gbogbo ọdún tí a là sílẹ̀ fún ìkà.
21Etí rẹ̀ kún fún igbe tí ó bani lẹ́rù,
ninu ìdẹ̀ra rẹ̀ àwọn apanirun yóo dìde sí i.
22Kò gbàgbọ́ pé òun lè jáde kúrò ninu òkùnkùn;
ati pé dájú, ikú idà ni yóo pa òun.
23Ó ń wá oúnjẹ káàkiri, ó ń bèèrè pé,
‘Níbo ló wà?’
Òun gan-an sì nìyí, oúnjẹ àwọn igún!
Ó mọ̀ pé ọjọ́ òkùnkùn ti súnmọ́ tòsí.
24Ìdààmú ati ìrora dẹ́rùbà á,
wọ́n ṣẹgun rẹ̀, bí ọba tí ó múra ogun.
25Nítorí pé ó ṣíwọ́ sókè sí Ọlọrun,
o sì ṣe oríkunkun sí Olodumare,
26ó ń ṣe oríkunkun sí i,
ó sì gbé apata tí ó nípọn lọ́wọ́ láti bá a jà;
27nítorí pé ó sanra tóbẹ́ẹ̀ tí ojú rẹ̀ yíbò,
ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ sì jẹ́ kìkì ọ̀rá.
28Ó ń gbé ìlú tí ó ti di ahoro,
ninu àwọn ilé tí eniyan kò gbọdọ̀ gbé,
àwọn ilé tí yóo pada di òkítì àlàpà.
29Kò ní ní ọrọ̀,
ohun tí ó bá ní, kò ní pẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀,
òun alára kò sì ní fìdí múlẹ̀.
30Kò ní bọ́ kúrò ninu òkùnkùn,
iná yóo jó àwọn ẹ̀ka rẹ̀,
afẹ́fẹ́ yóo sì fẹ́ àwọn ìtànná rẹ̀ dànù.
31Kí ó má gbẹ́kẹ̀lé òfo,
kí ó má máa tan ara rẹ̀ jẹ,
nítorí òfo ni yóo jẹ́ èrè rẹ̀.
32A ó san án fún un lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ lọ́jọ́ àìpé,
gbogbo ẹ̀ka rẹ̀ ni yóo sì gbẹ.
33Yóo gbọn àwọn èso rẹ̀ tí kò tíì pọ́n dànù, bí àjàrà,
yóo sì gbọn àwọn ìtànná rẹ̀ dànù, bí igi olifi.
34Nítorí asán ni àwùjọ àwọn tí wọn kò mọ Ọlọ́run,
iná yóo sì jó ilé àwọn tí ń gba owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀.
35Wọ́n ń ro èrò ìkà,
wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ibi,
wọ́n sì ń pète ẹ̀tàn lọ́kàn.”
Currently Selected:
JOBU 15: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010